Àrokò
Aroko Lori igbeyin loju
Àrokò pípa ní ayé àtijọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àrokò pípa jẹ́ ọ̀nà tí Yorùbá máa n gbà se ìkìlọ̀ tàbí ránsẹ́ sí ẹlòmíràn láyé àtíjọ́. Àrokò má n jẹmọ́ isẹ́, ẹ̀sìn tàbí ẹgbẹ́ tí àwọn ènìyàn nse. Òtítọ́ tàbí ìgbọràn se pàtàkì nínú àrokò pípa. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ wípé ẹnikẹ́ni tí a bá fi àrokò rán gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó fetí sí òfin àti olótítọ́ ènìyàn.
Àwọn àrokò kan wà tí ó máa n wà lójú kan, àwọn àrokò wònyìí ni à n pè ní àte, irú àwọn àrokò báyìí wà láti ṣe ìkìlọ̀ ewu.
Láyé àtíjọ́, orísirísi àwọn ènìyàn ló má n pàrokò ránsẹ́. Díẹ̀ lára wọn ni:- Ọdẹ ,Babaláwo, awo, ògbóni, jagunjagun, àgbẹ̀, àti bẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ
Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì tí a bá pa àrokò]
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ẹni tí o pa àrokò
- Ẹni tí a fi àrokò ran
- Ẹni tí a fi àrokò ránsẹ́ si
Ẹni tí ó pa àrokò: Ẹni tí o pa àrokò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí o mò irú èrònjà tí ó tọ́ fún irú àrokò tí ó fẹ́ pa. Ẹni náà gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tó tó gbangba sùn lọ́yẹ́.
Ẹni Tí a fi Àrokò rán: Ẹni tí a fi àrokò náà rán gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó se fi ọkàn tán, tí kìí se màdàrù ènìyàn rárá.
Ẹni tí a fi Àrokò ránsẹ́ sí : Ẹni náà gbọdọ̀ mọ ìtumọ̀ àrokò tí a pa fún, sùgbón tí ẹni náà kò bá mọ irú àrokò tí a pa fún, ó gbọdọ̀ lọ bá àwọn àgbà láti sọ ìtumọ̀ àrokò náà fún.
Oríṣìíríṣìí Àrokò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Àrokò ìkìlọ̀
- Àrokò ẹ̀bẹ̀
- Àrokò ogun
- Àrokò ìranṣé
- Àrokò ìfẹ́
- Àrokò ìtọ́nisọ́nà[2]
- Àrokò àlè pípa
- Àrokò àṣẹ́wélé
- Àrokò agà yíya [3]
- Àrokò ajẹmówe
- Àrokò afohùn gbéwà jáde
- Àrokò ajemáṣìírí
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "AROKO - The Yoruba Hieroglyphics - Politics". Nigeria. 2019-12-31. Retrieved 2019-12-31.
- ↑ https://www.timeanddate.com/calendar/months/
- ↑ https://informationparlour.com/article-culture-tradition-communication-system-ancient-yoruba-culture
Ọlátúnjí,O (1986);Àrokò.Ìbàdàn,Vintage Publishers.