Èdè Swàhílì
Èdè Swàhílì Swahili Language | |
---|---|
Kiswahili | |
Sísọ ní | Burundi Congo DR
Oman[1] |
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀ | – |
Èdè ìbátan | Niger-Kóngò
|
Lílò bíi oníbiṣẹ́ | |
Èdè oníbiṣẹ́ ní | African Union Kenya Tanzania Uganda |
Àkóso lọ́wọ́ | Baraza la Kiswahili la Taifa (Tanzania) |
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè | |
ISO 639-1 | sw |
ISO 639-2 | swa |
ISO 639-3 | variously: swa – Swahili (generic) swc – Congo Swahili swh – Coastal Swahili |
Eti okun, n'ibi ti Ede Swahili ti je Ede abinibi,
gege bi Ede Ijobi,Oselu ,tabi Ede orile-ede,
gege bi Ede owo, ati ibalopo eyameya. |
Ede Swahili tabi Kiswahili(ni ede Kiswahili) je ede ni Afrika.Ede naa je ede Bantu ti o gbooro ju lo fun iwulo ni iha Ìlaòrùn Áfríkà.Pupo ninu awon eya ti o wa ni Ila Oorun Afrika, ni o n lo ede naa, gege bi ede Ibara soro.Lilo ede naa wopo julo lati Ariwa orile ede Kenya titi de Ariwa orile Ede Mozambique, ati awon Erekusu ti o wa ninu okun India,fun apere Zanzibar ati Pemba, tabi Kòmórò ati Mayotte.b'o tile je pe iye eniyan egbegberun marun{5 million} nikan ni o n lo ede naa gege bi ede abinibi,Iye apapo eniyan to gbo, ati ti o le lo ede naa fun ibanisoro laarin ara, to egbegberun Ogota[60Million} eniyan[2], ni Ila Oorun ati Aarin Orile Erekusu Afrika.
Ìmò Eréfē
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Swahili je ede Bantu. pupo ninu awon Eya ti wa ni Eba odo Okun India, ni Ila Oorun Afrika ni o si n lo Ede naa. Pupo ninu awon oro ti o jeyo ninu Ede Swahili,lo ní orisun ninu Ede Larubawa, nitori Ibalopo ti o waye laarin awon Eya Bantu, ati awon Onisowo Larubawa, ti o wa ni eti bebe Sánji (Zanj) ati pásíà (Iran) ni Ila orun Afrika, ni bi odun Ogorun mejila sehin. Awon ede miran ti jeyo ninu awon oro Swahili ni Ede Jamani(German), Ede Potoki(Portuguese),Èdè Gẹ̀ẹ́sì(English), ati Ede Faranse{French}, lati awon Ibalopo ti o waye larin awon onilo ede wonyii, ni nkan bi odun Ogorun marun (500) sehin.Ede Swahili ni oni ,ti di ede Keji, ni Ilo fun Egbegberun eniyan ni orile-ede meta ni Iha Ila Orun Afrika, Tànsáníà, Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tòṣèlúaráìlú ilẹ̀ Kóngò ati Kenya, ni ibi ti ede naa ti je ede Ijoba.Ijoba Orile ede Uganda so ede naa di kiko ni gbogbo Ile Iwe alakobere, ni odun 1992. Bi o tile je pe igbese naa o sele bi won ti se ro, Ijoba orile ede naa so ede naa da Ede Ijoba no odun 1995, fun Imura s'ile ti Ìsọkan ti agbègbè Ilà Orùn Áfríkà. Gbogbo eniyan orile-ede Komoros ninu okun India ni o le so Ede Swahili, tabi ede ti o fara pẹ Swahili, fun apẹẹrẹ Èdè Shíkọmọ(Comorian).Iye eniyan die si n lo ede na ni awon Orile Ede Bùrúndì, Rùwándà, ati Ariwa orile ede Sámbíà
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Ethnologue list of countries where Swahili is spoken
Thomas J. Honneybusch, 2010, "Swahili", International Encyclopedia of Linguistics, Oxford, pp. 99-106
David Dalby, 1999/2000, The Linguasphere Register of the World's Languages and Speech Communities, Linguasphere Press, Volume Two, pg. 733-735
Benji Wald, 1994, "Sub-Saharan Africa", Atlas of the World's Languages, Routledge, pp. 289-346, maps 80, 81, 85 - ↑ Irele 2010
- ↑ http://wikisource.org/wiki/Baba_yetu