Jump to content

A tribe called Judah

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
A tribe called Judah
AdaríFunke Akindele Adeoluwa Owu
Olùgbékalẹ̀Funke Akindele
Àwọn òṣèréFunke Akindele Timini Egbuson Olumide Oworu Uzor Arukwe Uzee Usman
OlùpínFilm One Entertainment
Déètì àgbéjáde15th, December 2023
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèEnglish Language

A Tribe Called Judah jẹ́ fíìmù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jáde ní ọdún 2023, láti ọwọ́ Funke Akindele. Lára àwọn ọ̀ṣèré tó kópa nínú fíìmù náà ni Funke Akindele, Timini Egbuson, Tobi Makinde, Faithia Balogun, Olumide Oworu, Jide Kene Achufusi, Nse Ikpe-Etim, Juliana Olayode, Uzor Arukwe, Yvonne Jegede, Genoveva Umeh àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[1] Wọ́n ṣàgbéjáde fíìmù náà ní sinimá ní ọjọ́ 15 December 2023. Akindele tó jẹ́ aṣagbátẹrù fíìmù náà sọ ọ́ di mímọ̀ pé òun fi fíìmù náà sọrí ìyá òun.[2]

Wọ́n ṣàgbéjáde fíìmù A Tribe Called Judah sí àwọn sinimá ní 15 December 2023. Lẹ́yìn ìṣàgbéjáde yìí, fíìmù náà gòkè láti jẹ́ fíìmù Nollywood àkọ́kọ́ tó máa ní ju ₦113 million ní ọ̀sẹ̀ tí wọ́n gbe jáde.[3][4]

Àṣàyàn àwọn akópa

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

[5]

A Tribe Called Judah sọ̀rọ̀ nípa ìtàn arábìnrin kan Jedidah Judah (èyí tí Funke Akindele ṣe), tó ń dá tọ́ àwọn ọmọ márùn-ún. Àwọn ọmọ márààrún yìí ní bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì wá láti ẹ̀yà márùn-ún Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn ọmọkùnrin méjì àkọ́kọ́ sọmọ gidi, tí wọ́n sì ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣiṣẹ́ kí wọ́n ba lè ran ìyá wọn lọ́wọ́. Àmọ́, ìkan-ò-gbékan ni àwọn mẹ́ta yòókù, àwọn náà ni; Pere (èyí tí Timini Egbuson ṣe) jẹ́ ògbóǹtarìgì olè, Shina (èyí tí Tobi Makinde ṣe) jẹ́ oníjàgídíjàgan ní àdúgbò, àti àbígbẹ̀yìn, tí ń ṣe Ejiro (èyí tí Olumide Oworu ṣe), jẹ́ oníbàjẹ́ ọmọ tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, ìyẹn Testimony (èyí tí Genoveva Umeh ṣe) nìkan ló jẹ ẹ́ lógún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ọwọ́ wọn burú jáì, Jedidah ò ṣààárẹ̀ nípa ṣíṣe ìtọjú fún wọn àti ṣíṣe ìgbìnyànjú láti yọ wọ́n nínú wàhálà.

Gbogbo nǹkan sorí kodò nígbà tí Jedidah dùbúlẹ̀ àìsàn, tó ní ààrùn kídìnrìn, tí ó sì nílò ₦18 million fún iṣẹ́ abẹ rẹ̀ àti ₦400,000 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún dialysis. Ọmọ àkọ́bí rẹ̀ pàdánù iṣẹ́ rẹ̀, èyí sì já àwọn ọmọ márààrún sí kòròfo. Èyí ló mú wọ́n pinnu láti lọ ja ọ̀gá Emeka lólè láti rí owó fún ìtọ́jú ìyá wọn. Gbogbo ènìyàn ló mọ̀ pé ọ̀nà ẹ̀bùrú ni ọ̀gá Emeka ń gbà rí owó rẹ̀. Àmọ́, lásìkò yẹn, ohun tó jẹ wọ́n lógún ni ṣíṣàkójọ owó fún ìwòsàn ìyá wọn.[6]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Erezi, Dennis (2023-12-11). "Glitz, glamour as Funke Akindele premieres ‘A Tribe Called Judah’". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2023-12-26. Retrieved 2023-12-26. 
  2. Ileyemi, Mariam (2023-12-12). "Funke Akindele dedicates ‘A Tribe Called Judah’ to late mother, as movie hits cinemas weekend". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-26. 
  3. Toromade, Samson (2023-12-18). "Funke Akindele's 'A Tribe Called Judah' off to record-breaking ₦122.7m box office start". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-26. 
  4. Udugba, Anthony (2023-12-19). "A Tribe Called Judah: Akindele taps street marketing to box office success". Businessday NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-26. 
  5. Oloruntoyin, Faith (2023-11-10). "Funke Akindele's 'A Tribe Called Judah's trailer promises heist-like drama". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-26. 
  6. Stephen, Onu (2023-12-25). "MOVIE REVIEW: 'A Tribe Called Judah': Funke Akindele's masterpiece of drama with comedy". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-26.