Abibatu Mogaji
Àbíbátù Mọ́gàjí | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà | 16 Oṣù Kẹ̀wá 1916
Aláìsí | 15 June 2013 | (ọmọ ọdún 96)
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Ọmọ Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Pàràkòyí oníṣòwò |
Àwọn olùbátan | Bọ́lá Tinúbú (ọmọ rẹ̀) |
Olóyè Abibatu Mogaji, MFR, OON tí wọ́n bí ní ọdún 1917, tí ó sì kú ni oṣù kẹfà ọdún 2013 (October 1917–June 2013) jẹ́ =Pàràkòyí oníṣòwò ọmọ Nàìjíríà àti Ìyálọ̀jà yányán gbogbo Nàìjíríà. [1][2]
Ìgbà èwe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Àbíbátù Mọ́gàjí lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹwàá ọdún 1916 ní Ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà
Ẹbí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Olóyè Àbíbátù Mọ́gàjí ni ìyá olórí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress tí ó tún jẹ́ Gómìnà àná Ìpínlẹ̀ Èkó, Olóyè Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed Tinúbú.[3][4] Ọmọ Tinubu, Fọláṣadé Tinúbú-Òjó, ló joyè ìyálọ́jà lẹ́yìn ikú Mọ́gàjí.
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kí ó tó jẹ ìyálọ́jà àwọn ẹgbẹ́ àwọn oǹtajà àwọn obìnrin àti ọkùnrin, Àbíbátù jẹ́ olórí onígboyà àwọn ọlọ́jà ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[5]Ní ipò rẹ̀, ó joyè alágbára Alimotu Pelewura.
Nípa akitiyan rẹ̀ láàárín àwọn ọlọ́jà, Ìjọba Àpapọ̀ Nàìjíríà fi oyè orílẹ̀ èdè dá a lọ́lá. .[6] Bẹ́ẹ̀ náà, wọ́n fi òye Ọ̀mọ̀wé dá a lólá ní Ahmadu Bello University and the University of Lagos.[7]
Ikú rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìyálọ́jà Mọ́gàjí kú lọ́mọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ní Sátidé, lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹfà ọdún 2013 nílé rẹ̀ tó wà ní Ìkẹjà, olú-ìlú Ipinle Eko. Wọ́n sin in sí ìtẹ́ òkú ti Ikoyi Vaults and Gardens ní Èkó [8][9]
Àwọn àmìn ẹ̀yẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Order of the Federal Republic
- Order of the Niger
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Tinubu’s mother, Abibatu Mogaji, dies at 96". punchng.com. Archived from the original on 2015-02-22. Retrieved 2015-02-20. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "We’ll miss Mogaji’s motherly role – Traders". punchng.com. Archived from the original on 2015-02-22. Retrieved 2015-02-20. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "ACN leader, Tinubu’s mum, Abibatu Mogaji, dies at 94 | Newswatch Times". mynewswatchtimesng.com. Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2015-02-20. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Mother of Former Gov. Bola Tinubu Is Dead: Alhaja Abibatu Mogaji Was 96 Years Old | Sahara Reporters". saharareporters.com. Retrieved 2015-02-20.
- ↑ "Late Abibatu Mogaji: Mixed feelings over closure of markets - Vanguard News". vanguardngr.com. Retrieved 2015-02-20.
- ↑ "Lawmaker’s Wife Becomes Iyaloja General | P.M. NEWS Nigeria". pmnewsnigeria.com. Retrieved 2015-02-20.
- ↑ "Mogaji: A tale of politics and commerce | The Nation". thenationonlineng.net. Retrieved 2015-02-20.
- ↑ Powered by DMflex WebGen --- www.dmflex.com. "Tinubu’s Mother, Abibatu Mogaji, Dies at 96, Articles | THISDAY LIVE". thisdaylive.com. Archived from the original on 2015-02-20. Retrieved 2015-02-20. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Lagos stands still as Tinubu’s mother, Abibatu Mogaji is buried - Vanguard News". vanguardngr.com. Retrieved 2015-02-20.