Adegoke Adelabu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Adegoke Adelabu
Opposition Leader Western House of Assembly
In office
1956–1958
Chairman of Ibadan District Council
In office
1954–1956
Federal Minister of Natural Resources and Social Services
In office
January 1955 - January 1956
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí3rd september 1915
Ibadan
AláìsíMarch 25, 1958(Age 42)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúNCNC

Gbàdàmọ́sí Adégòkè Adélabú tí a bí ní ọjọ́ Kẹta osù Kẹsàn an ọdún 1915 ní ìlú Ìbàdàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ olóṣèlú àti Mínísítà tẹ́lẹ̀ ohun àlùmọ́nì ati ìgbáyé-gbádùn fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láàrín osù Kínní ọdún 1955 sí oṣù Kínní ọdún 1956, tí ó sì padà di olórí alátakò ní ilé ìgbìmọ̀ọ̀ aṣòfin ní ẹkún ìjọba Ìwọ̀ Oòrùn nígbà ayé rẹ̀. Ó di ìlú-mòọ́ká látàrí akitiyan ati ipa malegbagbe tí ó kò nínú ìṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Adélabú lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Government College, Ibadan ó sì di oníṣòwò lẹ́yìn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìjàmbá ọkọ̀ lẹ́yìn ìgbà diẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba àmúnisìn Brítènì. [1]


Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adélabú tí a bí sínú ẹbí ọ̀gbẹ́ni Sanusi Aṣiyanbí ati abilékọ Awujola Adélabú.[2] ní ọdún 1915. Ìyá Adélabú ni ó jẹ́ ìyàwó kejì nílé ọmọ rẹ̀ tí ó sì ṣílẹ̀ wọ̀ lẹ́yìn ìgbà diẹ̀ tí ó bí Adégòkè tan, èyí ni ó mú kí ẹ̀gbọ́n Ìyá rẹ̀ ó gbà á tọ́. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alàkalẹ̀ọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti C.M.S. ní Kúdẹtì nígboro ìlú Ìbàdàn láàrín ọdún 1925-1929, tí ó sì kàwé gba Standard IV àti V ní C.M.S. Central school, Mapo. Lóòtọ́ Musulumi ni oun àti ẹbí rẹ̀, amọ́ ọ̀dọ̀ Àbúrò bàbá rẹ̀ tí ó gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ mu lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ tí ó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹ́sì Kìrìstẹ́nì ní ìlú Ìbàdàn, tí ó sì gba ìwé-ẹ̀rí ilé-ẹ̀kó náà tí fi lè wọ ilé-ẹ̀kọ́ CMS. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Government College ti ìlú Ìbàdàn láàrín ọdún [3] 1931 sí ọdún 1936 gẹ́gẹ́ bí aṣojú akẹ́kọ̀ọ́ inú ọgbà. Ní ọdún 1936, Adélabú wọ ilé-ẹ̀kọ́ Yaba Higher College, lẹ́yìn èyí, ó rí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ gbà lọ́wọ́ ilé-iṣẹ́ UAC láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa imọ̀ okòwò.[4] Láìpẹ́, Adélabú kúrò nílé ẹ̀kọ́ lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí wọ́n fun ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́. Ọkàn nínú àwọn akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ tí ó ti mọ̀ ri ní ilé-iṣẹ́ kòkó tí ó tún jẹ́ ọ̀gá àgbà ní ilé-iṣẹ́ UAC fun ní iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ adarí àgbà ilé-iṣẹ́ wọn ní ìlú Ìbàdàn . Lẹ́yìn tí ó de ibẹ̀, Adélabú gbé ìgbésẹ̀ bí ilé-iṣẹ́ ṣe lè máa to kókó lọ́nà ará ọ̀tọ̀, ìgbésẹ̀ yí sì ni ó jẹ́ kí ó ri ìgbéga sípò igbákejì adarí lẹ́ka ìtajà. Adélabú kúrò ní ilé-iṣẹ́ UAC ní ọdún 1937 láti dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ owó kòkó títà fúnra rẹ̀, láìpẹ́, ó di lààmì-laaka nínú iṣẹ́ òwò kòkó rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó di gbajúmọ̀ níbi iṣẹ́ rẹ̀ tán ni ó bẹ̀rẹ̀ ní ń wá iṣẹ́ ìjọba. [5] Ó di olùbẹ̀wò agbà fún ohun ọ̀gbìn ní ọsún 1939. Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ UAC títí di ọdún 1945, Adélabú sì kúrò ní ilé-iṣẹ́ náà nígbà tí Richardson kúrò ní ilé-iṣẹ́ UAC. [6]. Lẹ́yìn èyí, Adélabú pa gbogbo owó tí ó ti rí kó jọ ní ó papọ̀ tí ó fi da òwò òwú sílẹ̀ pẹ̀lú Levantine ní ilẹ̀ Ìbàdàn.

Ipa rẹ̀ nínú ìṣèlú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún 1949–1953[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adélabú bẹ̀rẹ̀ ìṣèlú nígbà tí ó ṣe ìkúnlápá fún akitiyan àwọn olóyè ati àwọn Mọ́gàjí ẹgbẹ́ rẹ̀ tako Salami Agbájé. Àwọn ènìyàn gbàgbọ́ wípé orí Adélabú pé púpọ̀, ó sì kàwé, òun gan ni ó yẹ nípò tí Salami Agbájé wà. Àwọn olóyè ati awọn Mọ́gají wọ̀nyí nílò ẹni tí ó lè bá wọn kọ̀wé ati àríwísí láti lè fẹsẹ̀ ẹ̀hónú wọn múlẹ̀, wọ́n tọ Adélabú lọ fún ìrànlọ́wọ́. Adélabú gbà láti ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú àdéhùn wípé wọn yóò fun ní ipò akọ̀wé wọn. Salami Agbájé ni ó jẹ́ oníṣòwò tí ó dipò Ọ̀tún Balógun Ilẹ̀ Ìbàdàn mú, òun sì ni ẹnì kẹ́ta tí ipò Ọba Olúbàdàn kàn. Ó kàwé, ó lówó, ó sì gbajúmọ̀ pẹ̀lú,àmọ́ púpọ̀ nínú àwọn olóyè wọ̀nyí ni wọn kò fẹ́ràn rẹ̀ látàrí wípé wọn kò lè wojú rẹ̀. Àwọn olóyè kékèké ati àwọn Mọ́gàjí bẹ̀rẹ̀ sí polongo takòó kí wọ́n lè yọ ọ́ nípò kí ó má ba di Olubadan. Adélabú ni ó ń ṣe agbátẹrù fún àwọn akọsílẹ̀ ati ìwé ìtakoni tí wọ́n fi ń ṣọwọ́ sí àwọn òyìnbó amúnisìn tí wọ́n ṣe ìjọba nígbà máà nípa Salami Agbájé. Lásìkò yí, wọ́n yan Adélabú sí ipò akọ̀wé Ẹgbẹ́ Ọmọ Ìbílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ tí ó tako Agbaje, tí Bello Asasi tí ó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ Alẹ́ṣinlọ́yẹ́ Olúbàdan àná .[7] Nígbà tí òrọ̀ yí d'étí ìgbọ̀ awọn òyìnbó amúnisìn, wọ́n gba Agbájé níyànjú kí ó yẹ̀bà fún kíkópa nínú ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ awọn ọ̀yínbó yí lo ànfaní yí láti ṣe atúntò sí ẹkùn Ilẹ̀ Ìbàdàn nípa yíyọ ẹkùn Ọ̀ṣun kúrò lára Ìbàdàn. Ìgbésẹ̀ awọn ìjọba àmúnisìn yí kò tẹ́ àwọn ènìyàn ati ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ilẹ̀ Ìbàdàn lọ́rùn , wọ́n sì kóra jọ nílanà ti ìṣèlú láti dáàbò bo ẹkùn Ìbàdàn.

Lásìkò ìdìbò abẹ́lé ní ọdún 1951, Adélabú ọmọ oyè Ẹgbẹ́ Ọmọ ìbílẹ̀, Augustus Akinloye, àti ẹgbẹ́ awọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ya kúrò láti ara Ibadan Progressive Union láti gbéná wojú àgbà-gbà ẹgbẹ́ náà dá ẹgbẹ́ Ibadan People's Party sílẹ̀. Adélabú gbẹ́kẹ̀lé bí ẹ̀nu ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ilẹ̀ Ìbàdàn kò ṣe kò lẹ́yìn tí awọn òyìnbó àmúnisìn ti yọ ẹkùn Ọ̀ṣun tí ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group kún lápá kúrò lára ilẹ̀ Ìbàdàn. and a youth group from Ibadan Progressive Union formed the Ibadan People's Party as a challenge to the old guards of the Ibadan Progressive Union. Adelabu capitalized on some anti-Ijebu sentiments among native Ibadan residents especially after the loss of Oshun division which was supported by Action Group leaders such as Awolowo, an Ijebu-man and Akintola. The new party won all six seats to the Western Regional Assembly. However, an informal alliance proposed by Adelabu to support NCNC fell apart and four of the elected members joined AG. Adelabu then became more active in the organization of NCNC in Ibadan and became the secretary of the party's Western Province Working Committee while earning recognition within the party as the only IPP legislator who stayed with NCNC. Soon his profile began to rise nationally that in 1952, he published a book, Africa in Ebullition about his political thoughts. To provide a formidable organization to challenge AG in the 1954 elections, Adelabu formed a new organization, the Ibadan Taxpayers Association which was an attempt to attract mass following based on tax reform. The group then formed an alliance with some a farmers group called Maiyegun to become Mabolaje Grand Alliance.Ọdún 1954–1958[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní àárín ọdún yí, Adélabú àti àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ tako ẹgbẹ́ IPU àti AG tí wọ́n pọ̀ ju ní ni inú ìgbìmọ̀ Ilé-Aṣòfin. Ó sì fi àtìlẹyìn rẹ̀ hàn sí àṣà àti ìṣe nípa wípé kí àwọn lọ́ba lọ́ba nípa pe kí wọ́n Ma ṣe san owó-orí.[8]Ní àsìkò ìdìbò abẹ́lé ní ọdún 1954, ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance ni ó wọlé jùlọ sí àwọn àga ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ Ìbàdàn, èyí ni ó sọ Adélabú di Alága gbogbo gbò fún ẹkùn náà.[9] Adélabú borí nínú ìdìbò sílé aṣojú-ṣòfin àgbà ní ọdún 1954. Lẹ́yìn èyí, ó di igbá kejì Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú NCNC akọ́kọ́ tí wọ́n sì tún yàn án sípò Mínísítà fún iṣẹ́ òde tí ó sì tún dipò yí mú gẹ́gẹ́ bí Alàgbà ẹkùn Ìbàdàn láti inú oṣù kíní ọdún 1955 sí oṣù kíní ọdún 1956.

Àwọn itọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Sklar, p. 303.
  2. Post & Jenkins 1973, p. 33.
  3. Post & Jenkins 1973, p. 36.
  4. Post & Jenkins 1973, p. 37.
  5. Post & Jenkins 1973, p. 46.
  6. Post & Jenkins 1973, p. 51.
  7. Sklar, p. 291.
  8. Onabanjo 1984, p. 357.
  9. Sklar, p. 297.