Afẹ́nifẹ́re
Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ni ó jẹ́ ẹgbẹ́ tó ó níṣe pẹ̀lú àṣà àti ẹ̀nìn ìbílẹ̀ t orùbá ilẹ̀ Nàìjíríà tí Olóyè Abraham Adésànyà adarí rẹ̀, nígbà tí Olóyè Bọ́lá Ìgè nígbà ayé rẹ̀ sì jẹ́ igbá kejì rẹ̀. Àwọn tí wọ́n tún jọ jẹ́ olùdásílẹ̀ ni Olóyè Ọnàsànyà, Olóyè Ruben Fáṣànràntì, Adégbọ̀nmírè Òkúróunmú Fẹ́mi Gàníyù Dáwódù, Ọláníhún Àjàyí , Olú Fálaè, Adébáyọ̀ Adéfaratì Alhaji Adéyẹmọ àti Ayọ̀ Adébanjọ.[1] Nígbà tí wọ́n dá ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance for Democracy kalẹ̀ ní ọdún 1998, wọ́n lo àfojúsùn wọn ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn ìpolongo ìbò náà. [2] Lẹ́yìn ti ẹgbẹ́ yí pàdánù ìdíje ìbò dìbò wáyé ní oṣù Kẹ́ta ọdún 2003, àwọn alátakò ọmọ ẹgbẹ́ náà lọ lọ́tọ̀, wọ́n sì dá ẹgbẹ́ AD sílẹ̀, tí wọ́n sì fi Olóyè Bísí Àkàndée ja Alága AD. Ní January 2006, àwọn jàndùkú olóṣèlú kọlu àwọn Akọ́wọ̀ọ́rìn (convoy) adarí ẹgbẹ́ òṣèlú ní ìlú Òṣogbo tí ó jẹ́ Olú-Ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun .
Ní ọdún 2008, wọ́n dá Afenifere Renewal Group (alias ARG) kalẹ̀ pẹ̀lú àwọn èrò àti ìlépa láti so ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re papọ̀ kí ìyapa ó Ma sii mọ́ láàrín wọn, tí yóò sì tún máa jẹ́ ànfàní fún àwọn àgbà ẹgbẹ́ náà láti lè ma bá iṣẹ́ takun takun wọn lọ. Ní oṣù Kọkànlá ọdún 2008, apá kan ẹgbẹ́ AAfẹ́nifẹ́re tí wọ́n fi faction of Afenifere in Ìjẹ̀bú Igbó , ní Ìpínl Ògùn , èyí tí Olóyè Ayọ̀ Bánjọ ń darí rẹ̀, fi Olóyè Reuben Fáṣọ̀nràntì jẹ gẹ́gẹ́ bí Alága ẹgbẹ́ tiwọn. Àwọn àgbà ARG ní èyí tí a ti rí Senator Ọlábíyí Dúrójayé , Olóyè Bísí Àkàndé , Wálé Ọ̀ṣun àti Yínká Òdúmákin fi léde wíé àwọn kò tẹ́wọ́ gba ìyànsípò náà wọlé ní tiwọn.
Ní oṣù Kẹwàá ọdún 2009, agbẹnusọ fún ARG sọ̀rọ̀ nípa ètò yíyọ ìkúnpá lórí epo rọ̀bì lábẹ́lé ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Bákan náà ni ẹgbẹ́ náà tún kan sárá sí Olóyè month, the ARG hailed the conviction of Chief Bọ̀dé George àti àwọn márùún mìíràn fún akitiyan wọn láti fòpin sí ìwà àjẹbánu tó ti gbilẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .
Ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá ni wọ́n rí àwọn alátakò ìjọba lórí èrò wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó tọ́ láti yí ìpinu ìjọba pada, tí ó sì ń fún àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́n wà nínú àjọ náà ní ìdánimọ̀ jákèjádò ilẹ̀ Nàìjíríà, ẹ̀wẹ̀ tí ó sì tún jẹ́ ọ̀nà kan láti tọ́jú ẹ̀yà Yorùbá lápapọ̀.
Àríwísí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn kan wà lára àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́n rí ìdásílẹ̀ àwọn ẹgbẹ́ alátakò gẹ́gẹ́ bí ohun tó léwu púpọ̀. Sheik Dr. Abu-Abdullah Adélabú tí ó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀sìn Islam ṣàpèjúwe ba ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re gẹ́gẹ́ bí àkójọ àwọn ẹlẹ́yà-ò-mẹ̀yà tí wọ́n sì ń lo inọ̀ tara ẹnìkan, oní kèéta, tí wọ́n kò mọ̀ ju ìbàjẹ́ àwọn ẹlẹ́yà tó kú lọ. Ó Se èyí nibi àpérò London Awqaf Africa College, Sheikh Adelabu, yí náà ni ẹni tí ó jẹ́ olùdásílẹ̀ the Awqaf Africa Society ní ìlú Lọ́ndọ̀nù.[3]
Àwọn Ìtọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Afenifere Archives - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2019-10-06.
- ↑ "Buhari, Akande, Afenifere, others mourn Akinfenwa - Nigeria and World NewsNigeria - The Guardian Nigeria News – Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News. Retrieved 2019-10-06.
- ↑ Nwachukwu, John Owen (2019-10-04). "2023: Afenifere leader, Adebanjo snubs South-West, reveals region to produce Buhari's successor". Daily Post Nigeria. Retrieved 2019-10-06.