Jump to content

Akinloye Akinyemi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Major
Akinloyè Akínyẹmí
NicknameSergeant Carter
BornIléṣà, Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, Nigeria
Allegiance Nigeria
Service/branch Adigun Nàìjíríà
RankMajor

Akinloyè Akínyẹmí, (1954–2012), tí wọ́n tún mọ̀ sí Sergeant Carter, jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó dé ipò àṣẹ Major nínú iṣẹ́ ológun orí-ilẹ̀ ṣáájú kí ó tó fẹ̀yìn tì. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn afẹ̀sùnkan nípa ìdìtẹ̀ gbàjọba,tí wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n láàrin ọdún 1987 àti 1995.[1][2] Lásìkò tí wà níbi iṣẹ́ ológun, ó ṣiṣẹ́ lábẹ́ ilé iṣẹ́ ti (Nigerian Army Signal Corps).[3] Òun ni àbúrò fún ọ̀gbẹ́ni Bọ́lájí Akínyẹmí.[4]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Akínyẹmí jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Iléṣà, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[5] Ólọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Government College tí ó wà ní ìlú Ìbàdàn kí ó tó tẹ̀ síwájú ní ilé-ẹ̀kọ́ ti ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ìpàgọ́ àwọn ọmọ ológun igbó ní ìlú Igbó ỌràÌpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní àsìkò ọdún 1960. Ó tún lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ ọmọ ológun ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó wà ní ìlú Kàdúná níbi tí ó ti jẹ́ ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ tó peregedé jùlọ láàrin àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ ń jáde lọ́dún náà. Ó tún lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ ti Royal military Academy Sandhurst níbi tí ó tún ti gba Ọ̀pá Iyì gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ ológun tó wá láti ilẹ̀ òkèrè. Lẹ̀yìn èyí, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Royal Military College of Science, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ́ iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná (electrical engineering) pẹ̀lú ipò àkọ́kọ́ (first classs).[6][3]

  1. "Major Triumphant". The Nation Newspapers. 30 September 2012. Retrieved 10 February 2020. 
  2. Max Siollun (2019). Nigeria's Soldiers of Fortune: The Abacha and Obasanjo Years. Oxford University Press. ISBN 9781787382022. https://books.google.com/books?id=DB6sDwAAQBAJ. Retrieved 10 February 2020. 
  3. 3.0 3.1 "Lest We Forget: Major Akinloye Akinyemi’s Self Sacrifice (1954-2012)". Sahara Reporters. 25 September 2012. Retrieved 10 February 2020. 
  4. Oyo, Remi (2 October 1995). "NIGERIA-POLITICS: For The Doubting Thomases". Inter Press Service. Retrieved 10 February 2020. 
  5. "I also knew Major Akinyemi:a tribute". Vanguard Newspapers. 6 October 2012. Retrieved 10 February 2020. 
  6. "‘At ease Major, at ease’". The Nation Newspapers. 12 October 2012. Retrieved 10 February 2020.