Jump to content

Akinola Deko

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Gabriel Akinola Deko
Gabriel Akinola Deko with Israeli Prime Minister David Ben-Gurion in Jerusalem, 1958
Regional Minister for Agriculture
In office
1957–1963
AsíwájúAugustus Akinloye
Arọ́pòSanya Onabamiro
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí30 October 1913
Idanre, Nigeria
Aláìsí5 November 1987
London, England
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAction Group, National Party of Nigeria
(Àwọn) olólùfẹ́Chief (Mrs) Caroline Ebun Akin-Deko
ResidenceIbadan, Nigeria
ProfessionBuilding contractor

Gabriel Akinọlá Dèkó tí wọ́n bí í ọjọ́ kaẹ́dọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá, ọdún 1913 (30-1-1913) tí ó sì kú ní ọjọ́ Kárùún oṣù Kọkànlá, ọdún 1987 (5 November 1987).[1] Ni ó jẹ́ oní kọ̀ngílá ìṣẹ́ Ẹ̀kọ́lé àti Mínísítà fún ètò ọ̀ aètò ọ̀gbìn nígbà kan rí apá Ìwọ̀ Oòrùn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́ tímọ́ fún Olóyè Awólówọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Mínísítà, ó kópa ribiribi nípa mímú ìlọsíwájú bá ètò ìgbnisíṣẹ́ àwọn àṣẹ̀sẹ̀ yọ ọ̀gọ́mọ̀ tí wọ́n kàwé jáde ní Unifásitì tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ àgbẹ̀ tí ìjọba yóò ma kọ́ wọn ní iṣẹ́ ọ̀gbìn ní àwọn ìletò tí wọ́n ti kọ́ kalẹ̀ fún iṣẹ́ àkànṣe náà tí ìjọba yóò sì ma fún wọn ní owó ọ̀yà. Àwọn akẹ́ọ̀ọ́ náà yóò ma ṣiṣẹ́ f ọ̀gbìn. Dídá àwọn ìletò wọ́nyí ni wọ́n jẹ́ ètò àyálò láti ọ̀dọ àwọn Israeli. Ètò yí wà fún láti já ọkàn àwọn Ọ̀dọ́-langba kúrò nínú èrò wíwáṣẹ́ lọ sí àwọn ìlú ńlá ńlá tí wọ́n sì yan iṣẹ́ àgbẹ̀ ní pọ̀sìn.[2] Akin Dèkó ni wọ́n bí ní ìlú igbotu, ní Ìpínlẹ̀ Òndó, tí àwọn òbí rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ìlú Ìdànrè ní Ìpínlẹ̀ Òndó kan náà. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ St Peters, ní Ìpínlẹ̀ Èkó, fún ètò ẹ̀kọ́ Alákùkọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ti ìpele ọlọ́dún mẹ́fà ẹlẹ́ẹ̀kejì, Ó tún lọ sí Government College Ìbàdàn (GCI), Ó sì parí ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀ ní ilé-ẹ̀ ẹ̀kọ́ Yaba Higher College ní Ìpínlẹ̀ Èkó níbi tí ó ti gba ìwé-ẹ̀rí nínú ẹ̀kọ́ Olùkọ́ . Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Olùkọ́ ní ilé-ẹ̀ọ́ rẹ̀ tí ó ti jáde tẹ́lẹ̀ (Government College, Ìbàdàn) tí ó sì ń kọ́ ni nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ṣíṣàmúlò Ìṣirò (mechanics and applied mathematics). Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó yan iṣẹ́ ikọ́lé láàyò tí ó sì gb ilé-ẹ̀kọ́ ìkọ́lé Brixton lọ ní ìlú London. Kò pẹ́ púpọ̀ tí ó fi bẹ̀rẹ̀ ilé-iṣẹ́ ìkọ́lé tirẹ̀ náà. Ní ọdún 1950s, ọ̀rẹ́ rẹ̀ ba sọ̀rọ̀ wípé kí ó dara pọ̀ mọ́ òṣèlú ní ọdún 1956, Ó gba imọ̀ràn ọ̀rẹ́ rẹ̀, lọ́gán tí ó sì dara pọ̀ mọ́ òṣèlú ni ó wọlé ìdìbò tí ó sọọ́ di Mínísítà fún ètò Ọ̀gbìn apá Ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. [3]Akinọlá ni ó ṣe aṣojú fún ilẹ̀ Nàìjíríà níbi àpérò fún Óńjẹ àti Nnkan irè-Oko(Food and Agriculture Organization) ní ilẹ̀ Adúláwọ̀. Wọ́n tún fi ṣe ìgba-kejì Gíwá ilé-ẹ̀kọ́ fún ilé-ẹ̀kọ́ Federal University of Technology, Àkúrẹ́. Òun náà tún ní igbákejì Gíwá ilé-ẹ̀kọ́ University of Ìbàdàn àti University of Benin.[4]

Àwọn Ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Gabriel Akinola Deko". GCI Museum. Retrieved 2019-10-07. 
  2. "OBASANJO VISITS THE AKIN-DEKO FAMILY IN IBADAN". Ibadan Insider. 2016-06-17. Archived from the original on 2019-10-07. Retrieved 2019-10-07. 
  3. "International Law Reports". Google Books. Retrieved 2019-10-07. 
  4. "Reminiscences On A Great Academician: Prof. Albert Ilemobade". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2015-07-26. Retrieved 2019-10-07.