Ambrose Olútáyọ̀ Ṣómidé
Ambrose Olútáyọ̀ Ṣómidé | |
---|---|
Birth name | Ambrose Olútáyọ̀ Ṣómidé |
Born | Abẹ́òkúta, Ìpínlẹ̀ Ògùn |
Alma mater | OAU |
Show | Mìnì-jọ̀jọ̀ |
Station(s) | Raypower 100.5 FM Fàájì FM |
Country | Nàìjíríà |
Ambrose Olútáyọ̀ Ṣómidé jẹ́ olóòtú ètò lórí ẹ̀rọ TV/Radio. Ó kàwé gboyè nínú ẹ̀kọ́ Urban and Regional Planning ní ilé-ẹ̀kọ́ Ọbáfẹ́mi Awolọ́wọ̀ University ní ìlú Ilé Ifẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni Adarí àgbà fún ilé iṣẹ́ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ ti DAAR Communications Plc (DCP), tí ó sì dá ìkànì Fàájì FM sílẹ̀ .[1]
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Olútáyọ̀ ní ìlúAbẹ́òkúta,ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Baptist tí ó wà ní ìlú Abẹ́òkúta. Ní ọdún 1976, wọ́n gbàá wọlé sí Fásitì Ilé-Ifẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ti ń ṣe ààtò ìlú (urban and regional planning). Olútáyọ̀ sè wípé òun fẹ́ràn láti ma wà láàrín àwọn obìnrin jùlọ. [2] Ó dara pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ Ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ ti Raypower 100.5 FM ní ọdún 1994.[3]
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní ọdún 1982, ní ilé iṣẹ́ Radio Nigeria (RN) ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú Abẹ́òkúta gẹ́gẹ́ bí oníṣirò ìròyìn (news accountant), lẹ́yìn tí ó jáde ìwé mẹ́wá. Ní ọdún 1984, ìjọba ológun tí ọ̀gágun Muhammadu Buhari ń ṣàkóso rẹ̀ ti ilé-iṣẹ́ Rédíò náà pa. [2] Ní ọdún 1985, Olútáyọ̀ tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú àjọ OPIC ìyẹn (Ogun State Property and Investment Corporation) ní ìlú Abẹ́òkúta kan náà ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, ṣájú kí ó tó wọ ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì. Ní ọdún 1994. Ambrose pàdé ọ̀rẹ́ rẹ̀ Bashiru Àdìsá tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Bàbá Gbọin. [4] Ní ọdún 2006, ó ṣèrìn-àjò lọ sí [United Kingdom]] láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa okòwò talk show nílé iṣẹ́ BBC. Ó bẹ̀rẹ̀ ilé-iṣẹ́ Faaji 106.5 FM ní ọdún 2012, tí ó jẹ́ ẹ̀ka ti DCP.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Veteran Presenter, Ambrose Shomide Talks To CityScoop On His 33yr Career In Broadcasting". city people. Archived from the original on 2 May 2016. Retrieved 12 May 2016.
- ↑ 2.0 2.1 adeola balogun. "I don’t have many male friends, but I enjoy the company of women". nigeriafilm.com. Retrieved 20 February 2016.
- ↑ ckn nigeria. "Ambrose Somide Loses Mum". Retrieved 20 February 2016.
- ↑ daniel adeleye. "‘I have a way of handling female fans’". the nation online. Retrieved 24 November 2015.