Jump to content

Attahiru Jega

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Attahiru Jega
Jega ń sọ̀rọ̀ ní Chatham House ní oṣù kẹta ọdun 2016
Alága kẹrin aájò elétò Independent National Electoral Commission
In office
8 June 2010 – 31 June 2015
AsíwájúMaurice Iwu
Arọ́pòAmina Zakari
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Attahiru Muhammadu Jega

11 Oṣù Kínní 1957 (1957-01-11) (ọmọ ọdún 67)
Jega, Northern Region, British Nigeria (now in Kebbi State, Nigeria)
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian

Attahiru Muhammadu Jega (tí a bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kínní ọdún 1957) jé Ọ̀mọ̀wé àti gíwá àná Yunifásítì Báyéró tí ìpínlè Kano tẹ́lẹ̀rí.[1] Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdun 2010, ààrẹ Goodluck Jonathan yan(pẹ̀lú ìfọwọsí ilé ìgbìmò asòfin) gẹ́gẹ́ bi alága Independent National Electoral Commission (INEC), ajo tí ó ń rí si ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, ààrẹ yan, àwọn ilé ìgbìmò asofin sì fi owó si yíyàn rẹ̀ láti rọ́pò Ọ̀jọ̀gbọ́n Maurice Iwu, ẹni tí ó fi ipò náà lè ní ọjọ́ kejìdínlógbọ̀n oṣù kẹrin ọdun 2010.[2] Jega nìkan ni alága ààjọ INEC tí ó se àmójútó ìdìbò Nàìjíríà méjì (ọdun 2011 àti ọdun 2015). Jega fi ipò náà kalẹ̀ ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 2015, ó fi ipò náà lé Amina Zakari gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Muhammadu Buhari se pá láṣẹ fun.[3]

Ìpìlẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Jega ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kínní ọdún 1957 ní Jega, Kebbi State. Ó lọ ilé-ìwé Sabon Gari Town Primary School, Jega láàrin 1963 sí 1969 fún ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ kí ó tó tẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní Government Secondary School tí Birnin Kebbi. Ní ọdun 1974, ó wọlé sí Bayero University College ti Yunifásítì Àmọ́dù Béllò Zaria's, ó sì kẹ́kọ́ gboyè nínú ìmò Sáyẹ́ǹsì Òṣèlú ní ọdun 1979. He wopadà dé ipò adarí Bayero University ní ọdun 2005.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Attahiru Jega: The measure of excellence and integrity, By Toyin Falola" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-12-06. Retrieved 2022-02-21. 
  2. Mohammed S. Shehu (9 June 2010). "Attahiru Jega a Radical at INEC". Daily Trust. Retrieved 10 October 2010. 
  3. Leadership Newspapers. "Jega Bows Out, Hand Over to Amina Zakari". http://leadership.ng/news/443983/pmb-appoints-amina-zakari-inec-chair-as-jega-bows-out. Retrieved 1 July 2015. 
  4. EWACHE AJEFU (8 June 2010). "The Man Attahiru Jega". The Will. Archived from the original on 12 June 2010. Retrieved 10 October 2010.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)