Jump to content

Chioma Okoye

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Chioma Okoye
Ọjọ́ìbí3 Oṣù Keje 1983 (1983-07-03) (ọmọ ọdún 43)
Kaduna, Naijiria
Orílẹ̀-èdèNaijiria
Ọmọ orílẹ̀-èdèNaijiria(1983–iwoyi)
Iléẹ̀kọ́ gígaYunifásítì ìlú Èkó
Iṣẹ́Osere
Ìgbà iṣẹ́2002-iwoyi
Websitepurpleribbonentertainment.com

Chioma Okoye jẹ́ òṣèré, ònkọ̀wé àti agbéréjáde tí ó wá láti ìlú Aguleri-Otu, èyí tí ó n bẹ ní ìjọba agbègbè ti Ìwọ-òòrùn Anámbra, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó ti kópa nínu fíìmù Nollywood tó lé ní 100 láti ìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2002.[1] Lẹ́hìn gbígba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àmì-ẹ̀yẹ, [2] Chioma ti di àwòkọ́ṣe nínu ìdi-iṣẹ́ fíìmù Nollywood. Ó jẹ́ aláàkóso Purple Ribbon Entertainment. [3]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Chioma ní ìlú Kàdúná níbi tí ó dàgbà sí pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀.[4] Orúkọ ìyá rẹ̀ n jẹ́ Òkóyè Nàómì, bẹ́ẹ̀ ṣì ni orúkọ bàbá rẹ̀ (olóògbé) jẹ́ Alàgbà Joseph Òkóyè, eni tí ó kú ní Oṣù Kẹẹ̀rin Ọjọ́ Ọgbọ̀n, Ọdún 2013. Chioma lọ sí ilé-ìwé Faith Nursery and Primary school ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná àti Christ the King Seminary Nnobi ni Ìpínlẹ̀ Anámbra. Lẹ́hìn náà, ó lọ sí Yunifásítì ìlú Èkó níbití ó ti kẹ́ẹ̀kọ́ Ìtàn-àkọọ́lẹ̀.[5]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Chioma bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe nípasẹ̀ Pete Edochie tí ó jẹ́ àbúrò bàbá/ìyá rẹ̀. Ó rí ànfàní yìí ní ìgbà kan tí ó tẹ̀lé Pete Edochie lọ sí ibi tí wọ́n gbé ṣe ìpèsè eré. Ipa àkọ́kọ́ rẹ̀ wáyé nínu fíìmù No Shaking, èyítí ó ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré bíi Victor Osuagwu àti Sam Loco Efe. Lẹ́hìn náà ló tún kópa nínu eré Nothing Spoil pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Chinedu Ikedieze, Osita Iheme, àti Uche Ogbuagu. Ó gbé àkọ́kọ́ fíìmù rẹ̀ jáde tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Aso-Ebi Girls.[6] Lẹ́hìn tí ó ti hàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù tó lórúkọ, ṣíṣe ìfihàn nínu fíìmù Abuja Connection (2003) mú ìrànlọ́wọ́ bá òkìkí rẹ̀ nídi iṣẹ́ fíìmù.[7][8]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Àkọ́lé Ipa Àwọn àkọsílẹ̀
2003 Slow Poison (Agala)
Drummer Boy
2004 Abuja Connection
True Romance
2005 Too Late
2013 Aso-ebi girl
Prof and Den Gun
The World Richest Family

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Ẹ̀yẹ Ẹ̀ka Èsì
2007 African Youth Awards Òṣèré tí ó dára jùlọ lédè Gẹ̀ẹ́sì Gbàá
2004 City People awards for Excellence Òṣèré tí ó dára jùlọ Gbàá

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. ↑ "Chioma Okoye". mcomet. mcomet. Archived from the original on 7 March 2014. Retrieved 8 February 2014. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. ↑ "Chioma Okoye". nigeriadailynews. nigeriadailynews. Archived from the original on 27 March 2011. Retrieved 17 February 2011.
  3. ↑ "Chioma Okoye’s got Selling Points". Nollywoodwatch. WatchMan. Archived from the original on 10 June 2008. Retrieved 8 June 2008. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. ↑ "Chioma Okoye’s typical DAY". Punchng. Nonye Ben-Nwankwo and Ademola Olonilua. Archived from the original on 11 January 2014. Retrieved 11 January 2014. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. ↑ "Chioma Okoye’s note to Jonathan". Indepthnigeria. Bimbo. Archived from the original on 2 March 2014. Retrieved 22 April 2011.
  6. ↑ "Chioma Okoye comes calling with "Aso-Ebi Girls"". Vanguardngr. Ayo Onikoyi. Retrieved 11 May 2013.
  7. ↑ "The World’s Richest Family From Purple Ribbon Entertainment". Ogus Baba Blog. ChicBenita. Retrieved 13 August 2013.
  8. ↑ "Chioma Okoye’s note to Jonathan". Vanguardngr. Vangurdngr. Retrieved 22 April 2011.