Cidade Velha

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:CaInfoboxpe Verde settlement Cidade Velha (Portuguese city atijọ́", tabí: Santiago de Cabo Verde) jẹ́ ìlú kan [1] tí ó wà ní apá ìlà Oòrùn erékùṣù Santiago, Cape Verde. Wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1462,[2]:77 òun ni ó jẹ́ ìlú tí ó pẹ́ jùlọ ní agbégbè Cape Verde tí ojẹ́ olú ìlú ibé tẹ́lẹ̀. Wọ́n ti fìgbà kan rí pèé ní Ribeira Grande, wọ́n sì yi padà síCidade Velha ní àsìkò sẹ́ntírì kejìdínlógún (18th century).[3] Òun ni ó jẹ́ olú ìlú fún Ribeira Grande de Santiago. Ìlú yí wà ní agbègbè aríwá ilẹ̀ Áfíríkà, ó sì tún jẹ́ ibi tí awọ èèbó àmúnisìn ará Yúróòpù gúnwà sí. Púpọ̀ nínú awọn ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n ṣe sí ìlú yí ni ó ṣì wà níbẹ̀ digbí, tí ó fi mọ́ ilé-ìjọsìn ati ọjà tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 16th sẹntirì ní wọ́n ṣì wà títí dòní. Lóní, Cidade Velha ni ó jẹ́ arin gbùngbù ọjà ìkẹ́rù wọ̀ ati ojú àṣà Creole. Àjọ UNESCO sọ ìlú yí di World Heritage Site àti ìkan lára Seven Wonders of Portuguese Origin in the World ní ọdún 2009.[3]

Bí ìlú náà ṣe rí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Cidade Belha wà ní apá ìlà Oòrun erékùṣù Santiago, lẹ́nu odò Cidade Velha Ribeira Grande de Santiago.Ó tó kìlómítà mẹ́wá sí olú-ìlú , àwọn ìlú tí wọ́n jẹ́ alámúlégbè Cidade ni: Largo Pelourinho, São Sebastião, Santo António and São Pedro.

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Cidade Velha - Nossa Senhora do Rosário church.
Ruins of the old cathedral

António da Noli,ni ó ṣàwárí ìlú t tí ó di Cidade Velha lóní ní nkan bí ọdún 1460.[2]:73 Da Noli kọ́kọ́ fìdí kalẹ̀ sí agbègbè Ribeira Grande pẹ̀lú àwọ ẹbí rẹ̀ láti orílẹ̀-èdè Potogí àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ láti Algarve àti Alentejo ní ọdun 1462. .[2]:77 Ojú ọjọ́ ilẹ̀ náà bá wọn lára mu, pàá pàá jùlọ omi tí ó ń ṣàn láti dò Rebeira Grande tíjẹ́ kí ó ní ànfàní ju àwọn ìlú bíi: Alcatrazes.[2]:80 Ìletò yí wá di ojúkò fún àwọn Potogí láti ṣe òwò-ẹrú ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ati ati Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ní àsìkò ọ̀rùndún kẹrìndínlógún sí ìkẹtàdínlógún Cidade Valhe jẹ́ gbajúbajà ojúkò okòwò fún àwọn arì rìn-àjò ojú omi láàrín ilẹ̀ Áfíríkà àti Cape, Brazil àti Caribbean.Látàrí bí ilẹ̀ yí ó ti ṣe fẹ̀ tó ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni ó ṣe jẹ́ kí ó di ojúkò fún òwò ẹrú ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.[3] Cidade Velha jẹ́ ibi tí àwọn arìnrìn-àjò oníwádí bí Vasco da Gama,ní nkan bí ọrún 1497 nígbà tí ó ń lọ sí ilẹ̀ India . Bákan náà ni Christopher Columbus tí ó ń lọ sí Amẹ́ríkà fún ẹlẹ́kẹta orúfẹ́ rẹ̀ ní ọdún 1498. Bákan náà ni Ferdinand Magellan tí ó ṣiṣẹ́ lábẹ́ orílẹ̀-èdè Spain. Ilú Cidade Velha ni ó ní ilé-ìjọsìn ọmọ lẹ́yìp Jésù tí ó dagbà jùlọ lágbàáyé , orúkọ ilé ìjọsìn náà ni Nossa Senhora do Rosário church,tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1495. Cidade Velha di ilé àṣẹ fún fún àwọn Roman Catholic Diocese of Santiago de Cabo Verde,èyí tí póòpù tẹ́lẹ̀ rí Pope Clement VII. Ìdàrúdàpọ̀ tí ó wáyé láàrín Ribeira Grande ati àwọn àmúnisìn Pọ́túgà ti ilẹ̀ Faramsé ati ilẹ̀ Brítènì ni ó mú kí àwọn agbésùnmọ̀mí orí omi bíi: Francis Drake (1585) àti Jacques Cassard (1712).[2]:195 Pẹ̀lú akitiyan bí wọ́n ṣe kọ́ Forte Real de São Filipe ní ọdún 1587–93, síbẹ̀ Ribeira Grande kò fi bẹ́ẹ̀ ní ààbò tó péye. Wọ́n gbé olú-ìlú rẹ̀ lọ sí Praia ní ọdún 1770 .[4]

Ribeira Grande tí ó ti di (Cidade Velha)ni ó ti di abúlé nísìnyí látàrí wípé kò sí ilé ikọ̀ awọn ọmọ ológun àti ilé ìjọsìn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni wọ́n ti di àlòpatì . Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe ní ati ọdún 1960, restoration .[5]:70 Ó di UNESCO' World Heritage Site ní ọdún 1990.[3]

Bi ile ilu naa se ri[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Iye olugbe ilu Cidade Velha ni odun (1990–2010)
1990[citation needed] 2010[6]
2148 1214

Àwọn ilé tí wọ́n ṣe pàtàkì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Pelourinho (Pillory), òpó tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1512 tàbí 1520. ti won ko ni odun 1512 tabi 1520. Ara òpó yí ni wọ́n ti ma ń fìyà je àwọn ẹrú tí wọ́n bá ṣẹ̀ ní gbngba. Òpó yí wà ní àárín gbùgbùn ìlú náà, wọ́n tún òpó yí gbéró ní ọdún 1960.[5]:38
  • Forte Real de São Filipe, ni won ko ni aarin odun 1587–93.[5]:26 Wọ́n kọ́ àgọ́ yí láti lè pagi dínà àwọn agbésùnmọ̀mí orí omi tí wọ́n ma ń wá dà wọ́n láàmú, pàá pàá jùlọ àwọn Faransé àti àwọn Gẹ̀ẹ́sì. Àgọ́ọ́ yí g sílẹ̀ ní nkan bí ẹsẹ̀ bàtà ọgọ́fà (120 m) sílẹ̀
  • Nossa Senhora do Rosário church, Ni o je ile-ijosin awon afini sowo eru Kiristeni ti o dagba julo ni gbogbo agbaye, won ko ni odun 1495. Won si fi Manueline Gothic se oso si lara.[5]:31
  • Ruined Sé Cathedral, won bere si n ko ni nkan bi odun 1556 ti won si pari re ni odun 1712. Ile ijosin naa gun to ogota bata, won si daabo bo ile-ijosin naa ni odun 2004 ki o ma ba baje tan [5]:29–30tbuilti won ko ni odun 1657 si eba arin ilu, ni won bere atunse re ni odun 2002.[5]:33
  • Awon ile ibile orisirisi ni a tun le ri ni awon oju popo ilu naa bii: rua Banana and rua Carreira.[5]:35

Oju ojo ilu naa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Cidade Velha ni o ni awon asale bii: hot arid climate (Köppen BWh). Iye ojo ti o ma n ro nibe ni 201 millimetres or 7.91 inches, iye oorun ti o ma n mu nibe ni 25.2 °C or 77.4 °F. Bákan náà, ní inú oṣù kínní ọdún ni òtútù ma ń mú jùlọ ní déédé 23.0 °C or 73.4 °F nígbà tí oru ma ń pọ̀ jùlọ nínú oṣù kẹwá ọdún ní déédé 28.0 °C or 82.4 °F.[7]

Dátà ojúọjọ́ fún Cidade Velha, 1 metre ASL
Osù Jan Feb Mar Apr May Jun Jul Aug Sep Oct Nov Dec Ọdún
Iye àmúpín tógajùlọ °C (°F) 26.7
(80.1)
27.2
(81)
27.9
(82.2)
28.3
(82.9)
28.5
(83.3)
29.6
(85.3)
29.4
(84.9)
30
(86)
30.6
(87.1)
31
(88)
29.7
(85.5)
27.3
(81.1)
28.85
(83.95)
Iye àmúpín tókéréjùlọ °C (°F) 19.4
(66.9)
19.2
(66.6)
19.7
(67.5)
20.1
(68.2)
21
(70)
21.8
(71.2)
22.5
(72.5)
23.7
(74.7)
23.9
(75)
25
(77)
22.3
(72.1)
20.8
(69.4)
21.62
(70.93)
Iye àmúpín ìrọ̀jò mm (inches) 2
(0.08)
2
(0.08)
0
(0)
0
(0)
0
(0)
0
(0)
7
(0.28)
50
(1.97)
90
(3.54)
40
(1.57)
9
(0.35)
1
(0.04)
201
(7.91)
Source: climate-data.org[7]

Àwọn àwòrán[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn itọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]


  1. Cabo Verde, Statistical Yearbook 2015, Instituto Nacional de Estatística, p. 32-33
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 Valor simbólico do centro histórico da Praia, Lourenço Conceição Gomes, Universidade Portucalense, 2008, p. 97
  3. 3.0 3.1 3.2 3.3 "Cidade Velha, Historic Centre of Ribeira Grande - UNESCO World Heritage Centre". Retrieved 8 July 2011. 
  4. Centre historique de Praia, UNESCO
  5. 5.0 5.1 5.2 5.3 5.4 5.5 5.6 Cidade Velha, Centre historique de Ribeira Grande, Proposition d’inscription sur la Liste du patrimoine mondial
  6. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named census10
  7. 7.0 7.1 "Climate Data Cidade Velha". Climate-Data.org. Retrieved 28 August 2018. 

Àdàkọ:Subdivisions of Santiago, Cape Verde Àdàkọ:Ribeira Grande de Santiago Àdàkọ:Authority control