D'Prince
D'Prince | |
---|---|
Orúkọ àbísọ | Charles Enebeli |
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | Omoba |
Ọjọ́ìbí | 23 Oṣù Kẹ̀wá 1986[1] Lagos State, Nigeria[2] |
Ìbẹ̀rẹ̀ | Umuahia, Abia State, Nigeria[2] |
Irú orin | Afropop |
Occupation(s) | Singer, songwriter, entrepreneur |
Years active | 2005–present |
Labels | Mavin Records, Jonzing World |
Associated acts | Don jazzy M.I Abaga |
Charles Enebeli (tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kẹwàá, ọdún 1986), tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ D'Prince, jẹ́ ọ̀kọrin Afropop tí ilé Naijiria. Ó jé Olùdásílẹ̀ àti adarí Ilé iṣé JONZING WORLD, ilé iṣẹ́ ìdárayá ti ó dásílẹ̀ ni ọdún 2019.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìpínlẹ̀ Èkó ni wọ́n bí Charles Enebeli sí ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kẹwàá, ọdún 1986. Ìdíle Collins Enebeli, tó jẹ́ oniṣòwò àti aṣàgbéjáde orin àti olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ agbórinjáde ti Sagitarious Productions, àti Patience Enebeli, tó jẹ́ oniṣòwò ni wọ́ bí D'Prince sí. D'Prince jé àbúrò Don jazzy, tó jẹ́ ọ̀gá ilé-iṣẹ́ Mavin Records.[3] Orin kíkọ ò ṣàjèjì sí wọn ní ìdílé yìí, ilé ni Don Jazzy àti D'Prince bá a. Wọ́n tún máa ń pè é ní ọmọọba.
Ilé-ìwé King's College[4] ní Ìpínlẹ̀ Èkó ni ó ti parí ilé-ẹ̀kọ́ girama, kí ó tó tẹ̀síwájú nínú ohun tó yàn láàyò.
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Látàrí oríyìn tó gbé fún àwọn aláwòkọ́ṣe rẹ̀ tí ń ṣe Fẹlá Kútì àti Bob Marley, ó pinnu láti máa lo àlòpọ̀ afrobeat àti Afropop láti máa fi gbé orin rẹ́ jáde. Àwọn orin rẹ́ máa ń dá lórí ayé àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì máa ń ní ìtumọ̀ ìjìnlẹ̀.
2005–2012:Mo' Hits records, & breakthrough single "Omoba"
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n pe D'Prince láti dara pọ̀ mọ̀ Mo' Hits Records ní ọdún 2005, lẹ́yìn tí ẹ̀gbọ́n rẹ́ Don Jazzy dé láti UK.[5] D'Prince ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin jáde látipa sẹ̀ Mo' Hits Records. Díẹ̀ lára àwọn orin náà ni "Booty Call", "Cloae to You", "Masquerade", "Stop the Violence", "Igbe Mi", "Hey Girl", "What You Want To Do To Me", "Oh No", àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[6] [7]
Jonzing World
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní oṣù kẹta, ọdún 2019, ó ṣe ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ agbórinjáde tirẹ̀ kalẹ̀, tí ó pè ní Jonzing World.[8] [9]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "D'Prince". Street Request. 28 April 2015. Archived from the original on 15 August 2015. Retrieved 26 April 2022.
- ↑ 2.0 2.1 Admin (28 April 2014). "D'Prince Bio". PulseNg. Archived from the original on 19 September 2015. Retrieved 16 May 2014.
- ↑ "Meet Don Jazzy, D'Prince and the entire family". Naija Gists. Retrieved 27 July 2012.
- ↑ "D'Prince Bio". Pluse. 9 April 2014. Archived from the original on 25 August 2017. Retrieved 26 April 2022.
- ↑ "D'Prince joining Mo' Hits". 5 October 2012. Archived from the original on 24 September 2015. Retrieved 26 April 2022.
- ↑ "World Premiere: D'Prince Drops 3 New Singles". Notjustok. 25 November 2009. Archived from the original on 4 March 2016. Retrieved 26 April 2022.
- ↑ "D'Prince Omoba Official Video". MoHitsRecordsTV. Retrieved 13 April 2010.
- ↑ "Don Jazzy signs record deal with D'Prince's Jonzing World". Vanguard News. 23 March 2019. Retrieved 12 July 2021.
- ↑ "Jonzing World presents the music video for 'One Shirt' feat. Ruger, Rema & D'Prince | WATCH VIDEO!". NotjustOk. 21 January 2021. Retrieved 12 July 2021.