Dele Belgore
Muhammad Dele Belgore (tí a bí ní ọjọ́ kàrùnlélọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 1961) jẹ́ agbejọ́rò àti olósẹ̀lú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni ó dupò fún ipò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara lábẹ ẹgbẹ́ òsèlú Action Congress of Nigeria (ACN) ní ọdún 2011. Ó fìdí rẹmi fún Abdulfatah Ahmed, ẹni tí ó dupò náà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP).[1] Belgore jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ilorin ní Ìpínlẹ̀ Kwara.
Ìpìlẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Belgore sínú ìdílé Lt. Justice Mahmud Babatunde Belgore, Adájọ́ àgbà ilé ẹjọ́ àgbà Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí[2][3][4] àti Alhaja Maryam Alarape Belgore, ẹni tí ó jẹ́ Nọ́sì àti oníṣòwò epo[5][6] Belgore kàwé ní ilé ìwé Nigerian Law School ní ọdún 1985.[7]
Ipa rẹ̀ nínú òsèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ẹgbẹ́ òṣèlú Action Congress of Nigeria yan Belgore láti du ipò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara ní ọdún 2011, ṣùgbọ́n ó fìdí remi fún Abdulfatah Ahmed, ẹni tí ó dupò náà lábé ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party. Belgore yí sí ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party ní ọdún 2013 níbi tí ó ti dupò gómìnà ṣùgbọ́n ó tún fìdí rẹmi ní ọdún 2014.[8][9]
Ó padà sí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ó sì ṣe àtìlẹyìn fún Abdulrahman Abdulrasaq.[10]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Saraki Senior Demystified – P.M. News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-12.
- ↑ "Correction: Former Chief Judge of the Federal High Court, Justice Babatunde Belgore Is Dead | Sahara Reporters". saharareporters.com. Retrieved 2023-06-17.
- ↑ Oyekola, Tunde (2022-12-25). "Kwara govt honours ex-govs, ex-CJN Belgore, Saraki, others". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-17.
- ↑ Olesin, Abdullahi (2022-12-25). "Kwara Honours Founding Fathers As Best Teachers, 5 Others Get Car Prizes" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-17.
- ↑ "Kwara Gov Commiserates with Belgore over Mum's Death – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-12.
- ↑ "You are being redirected...". kwarastate.gov.ng. Retrieved 2023-06-17.
- ↑ ACMC, Edeh Samuel Chukwuemeka (2023-02-24). "Best Lawyers In Nigeria 2023: 14 Most Prominent". Bscholarly (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-12.
- ↑ "In Kwara, Belgore, Saraki, ex-VC scramble for PDP guber ticket – Daily Trust". dailytrust.com. 16 November 2014. Retrieved 2023-06-17.
- ↑ "Belgore, ACN ex-governorship candidate joins PDP – P.M. News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-17.
- ↑ "Belgore Withdraws from Kwara APC Guber Primary, Directs Supporters to Vote for Abdulrazaq – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-17.