Emily Nkanga
Emily Nkanga | |
---|---|
Emily Nkanga ní London ní ọdún 2017 | |
Ọjọ́ìbí | Emily Oluwatobi Nkanga 21 Oṣù Kàrún 1995 Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Ayàwòrán |
Ìgbà iṣẹ́ | 2012 títí di ìsinsìnyí |
Website | emilynkanga.com |
Emily Nkanga jẹ́ ayàwòrán ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan, ó tún ń ṣe fíìmù jáde. Nkanga gbajúmọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olórin bi Koker, Aramide, Boj, Olamide, Jidenna, Not3s,[1] Mr Eazi, Mayorkun, Adekunle Gold, Sarz, òṣèré Adesola Osakalumi, agbábọ́ọ̀lù Tammy Abraham àti Femi Kuti.[2] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àwòrán Nkanga jẹ́ nípa àwọn ènìyàn tí wón ti pàdánù ilé àti ọ̀nà wọn ní àríwá Nàìjíríà nítorí ogun Boko Haram.[3]
Ìpìlẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Nkanga ní ìpínlẹ̀ Èkó sínú ìdílé Idongesit àti Mosunsola Nkanga, Ìpínlẹ̀ Èkó náà ni wọ́n ti tọ dàgbà. Ó lọ ilé-ìwé Air Force Girls Comprehensive School, Jos, Ìpínlẹ̀ Plateau, lẹyìn náà, ó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní American University of Nigeria, Yola, Ìpínlẹ̀ Adamawa, ní Àríwá Nàìjirià.[4] Ó ni àmì ẹyẹ masters of art nínú ṣíṣe àgbéjáde láti Yunifásitì Goldsmiths ti London.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Why British artist Not3s is the hottest sound of this summer". GQ Magazine (London, England). 6 July 2018. https://gq-images.condecdn.net/image/olb7pOMAYGr/crop/810/f/notes-01-gq-27jun18_b.jpg. Retrieved 10 November 2018.
- ↑ Soni, Daniel (22 May 2016). "Like my pilot-father, I also dream to conquer the world – 21-yr-old Emily Nkanga". The Vanguard Newspaper (Lagos, Nigeria). http://www.vanguardngr.com/2016/05/like-pilot-father-also-dream-conquer-world-21-yr-old-emily-nkanga/. Retrieved 5 June 2017.
- ↑ Orubo, Daniel (26 September 2016). "Photographer Takes Powerful Images Of People Displaced By Boko Haram In Northeast Nigeria". Konbini (Lagos, Nigeria). Archived from the original on 18 September 2016. https://web.archive.org/web/20160918070756/http://www.konbini.com/ng/inspiration/this-photographer-took-powerful-images-of-people-displaced-by-boko-haram-in-northeast-nigeria/. Retrieved 5 June 2017.
- ↑ "Choosing photography as a career, very challenging — Emily Nkanga". The Vanguard Newspaper (Lagos, Nigeria). 22 June 2016. http://www.vanguardngr.com/2016/06/choosing-photography-career-challenging-emily-nkanga/. Retrieved 6 June 2017.