Jump to content

Emmanuel Ifeajuna

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Emmanuel Arinze Ifeajuna tí a bí ní ọjàọ́ kaẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹsàán ọdún 1935 tí ó sì papò da ní ọdún 1967. [1] Jẹ́ ọmọ ológun ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti eléré ìdárayá ní ẹ̀ka igi fífò. Òun ni ọmọ orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ tí ó gba àmì ẹ̀yẹ wúrà níbi ìdíje àgbáayé ní ibi eré ìdárayá ti Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì gbé kalẹ̀ níọdún 1954. Ìwọ̀n ìfò ti ó mu gba àmì ̀ẹyẹ ̀wura ni ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà méfà ó lé ìpín mẹ́jọ (6 ft 8) èyí ni ìwọn mítà méjì ó lé mẹta (2.03 m) eléyí sì jẹ́ ìgbà ákọ́kọ́ tí ẹnìkẹ́ni yóò fò irú ìwọn yíí.

Ó jẹ́ ọmọ bíbi ìlú Onitsha ní ẹ̀yà Igbo láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níṣe, ó sì kẹ́kọ́ gboyè nínú ìmọ̀ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì láti ilè-ẹ̀kọ́ gíga ti Yunifásitì Ìbàdàn. Ó dára pọ̀ mọ́ òṣèlú, lẹ́yìn èyí ni ó tún gba iṣẹ́ ológun. Ó kó ipa pàtàkì nínú ìfipá gba ìjọba lọ́wọ́ olóṣèlú tí ó wáyé ní orílẹ-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1966.

Ìgbé Ayé àti iṣẹ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Eré ìdárayá ìfò fífò

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọmọ bíbí ìlú Onitsha[2] ni, ó lọ sí Ilé-ìwé Girama Dennis Memorial ni ilu abinibi rẹ o si fi awọn abuda ti yoo sọ ipa ti igbesi aye rẹ tọ han nigba naa. Olùkọ́ eré ìdárayá ni ile-iwe girama rẹ ni o kọ ọ ni ere idaraya ifo fifo[3]. Bakanna ni o wa lara awon ti o fi ehonu han eleyi ti o mu ki won gbe ile-ẹkọ giga re fun saa ẹkọ kan. O jade ile-iwe girama ni ọdun 1951[4] Ile-iwe Girama ti Ilesa naa le ka a kun awon akeko ti o jade nibe, biotilejepe awon ariyanjiyan kan jeyo ninu iroyin yi, sugbon o daju wipe o ṣe ile ẹkọ fun saa akoko oorun nigba kan ri nibe.[5]

Ní idije ere idaraya ni ọdun 1954 ni Vancouver, o dije pẹlu bata ẹsẹ kan, ẹsẹ osi, sibẹsibẹ, o bori nipa fifo ifo iwon ẹsẹ bata mẹfa o le mẹjo (mita 2.03), eleyi ti o ta yọ ohun ti ẹnikẹni ti fo ri boya ni ti ere idije ni tabi ni ti orilẹ-ede Gẹẹsi. Ami ẹyẹ wura ti o gba nidi eyi jẹ igba akọkọ ti alawọ dudu yoo gba nibi idije to laami laaka lagbaye. Idije ifo fifo yii gbajugbaja ni odun naa fun awon alawọ dudu nitoripe Patrick Etolu ti o jẹ ọmọ orilẹ-ede Uganda naa se ipo keji tẹle Ifeajuna tí Osagie, ti o je ọmọ orilẹ-ede Naijiria si ṣe ipo kẹta. T'iIu t'ifọn ni wọn fi ki Ifeajuna kaabọ nigba ti o pada de ilu Eko, ijo ati ayọ ni wọn fi gbe yipo ilu Eko kí o to dari si ibi a wẹjẹ-wẹmu kan nibi ti o ti sọ̀rọ̀. Aworan rẹ̀ si di ohun ti a ya si ẹyin iwe ajakọ ti awọn ọmọ ile-iwe alakọbẹrẹ ati girama n lo ni orilẹ-ede Naijiria[3].

Ipa rẹ̀ nínú ìṣèlú nílé Ẹ̀kọ́ gíga

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Léyìn ígbà tí Ifeajuna gba àmì-ẹ̀yẹ wúrà, ó padà sí ilé ìwé gíga ti ìlú Ìbàdàn láti kàwé gboyè nínú ìmọ̀ sáyẹ́nsì ní odún 1954. Ó darapọ̀ mọ́ àwọn akegbe tí wọ́n jẹ́ olóṣèlú nínú ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti UniversityCollege Ìbàdàn .

Ó wà lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sigma Club, tí o wà ní ilé-ẹ̀kọ́ University of Ibadan nígbà náà. Sigma Club jẹ́ ẹgbẹ́ tí àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kó tó ríṣe láwùjọ dá sílẹ̀ láti ma fi ṣe apèjẹ orin tí wọ́n pè ní Havana Musical Carnival nínú ilé-ẹ̀kọ́. Lásìkò tí Ifeajuna jẹ́ akẹ́kọ́, ó jẹ́ ọ́rẹ́ pẹ̀lú Christopher Okigbo àti J.P. Clark, tí wọ́n padà di akéwì jànkàn ní orílẹ́-èdè Nàìjíríà. [6] Bákan náà ni Ifeajuna tún jẹ́ ọ̀rẹ́ pẹ̀lú Emeka Anyaoku, tí ó padà di Commonwealth Secretary-General. Ó sì jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn akẹ́kọ́ olóṣelu inu ilé-ẹ̀kọ́ Fásití Ìbàdàn. Ó padà di adarí ìròyìn fún Egbe akeko tí ó sì ń ṣàtìlẹyìn fún ìfẹ̀hónúhàn oríṣirísi.[7]. Bákan náà ni ó tún ṣàtìlẹyìn fún ẹgbẹ́ Dynamic Party, tí di onímọ̀ ìṣirò Chike Obi. Uche Chukwumerije, tí ó jẹ́ akẹgbẹ́ rẹ̀ tí òun náà padà di Sẹ́nétọ̀ fẹnu baá wípé Ifeajuna sábà ma ń ṣagbékalẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn, amọ́ kìí kópa nínú rẹ̀. Bákan náà ni J.P. Clark náà tún sọ wípé ifẹ̀hónúhàn tí Ifeajuna gbé kalẹ̀ tí ó lágbára jùlọ nínú ilé ilé-ẹ̀kọ́ náà ni bí wọ́n ṣe ti ilé-ìgbé àwọn akẹ́ẹ́kọ̀ọ́ pa. Títi ilé-ìgbé náà pa ni ó ní ṣe pẹ̀lú bí àwọn kan tí wọn kò mọ̀ ṣe Ṣé kú pa akẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ben Obumselu tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ sí Ifeajuna. Ifeajuna ṣagbékalẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn náà amọ́ kò bá wọn kópa nínú rẹ̀ nígbà tí ó di wàhálà.[8]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Emmaunel Ifeajuna". Brinkster. Retrieved 2014-07-13.
  2. Siollun, Max (2005-10-30). "The Inside Story Of Nigeria’s First Military Coup (I)". Nigeria Matters. Retrieved on 2014-07-13.
  3. 3.0 3.1 Oliver, Brian (2014-07-13). "Emmanuel Ifeajuna: Commonwealth Games gold to facing a firing squad". The Guardian. Retrieved 2014-07-13.
  4. Onyema, Henry (2013-10-23). "EMMANUEL IFEAJUNA – The Man Called Emma Vancouver". Naija Stories. Retrieved 2014-07-13.
  5. Major Emmanuel Ifeajuna Archived 14 July 2014 at the Wayback Machine. Ilesa Grammar School. Retrieved 2014-07-13.
  6. "The Journey of a Manuscript". AuthorMe. Retrieved 2014-07-13.
  7. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Guardian
  8. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Naija