Fábùnmi Òkèmẹ̀sí
Fábùnmi Ìṣọ̀lá | |
---|---|
Balogun of the Ekiti-Parapo and Loja-Oke of Imesi-Ile
| |
Reign | 1902 - 1903 |
HRM Ladokun Adefenwa Fabunmi II | |
Falola | |
Issue | |
Ladokun Adefenwa | |
Father | Prince Adesoye |
Born | c. 1849 Okemesi |
Died | Àdàkọ:Death year (age 54) Imesi-ile, Southern Nigeria Protectorate |
Occupation | Warlord and King |
Fábùnmi Òkèmẹ̀sí(c. 1849 - 1903) ti ó jẹ́ ọmọ aládé Fábùnmi Ìṣọ̀lá, tí a tún mọ̀ sí Ọrara l’ada, jẹ́ jagunjagun Ilẹ̀ Yorùbá, olóyè àti Ọba[1] Ó di ìlúmọ̀ọ́ká akọni látàrí ogun Kírìjí tí ó jẹ́ ogun abẹ́lé tí ó gun jù lọ ní Nàìjíríà tí ó jà nígbà ìwáṣẹ̀.
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọmọba Fábùnmi Ìsọ̀lá jẹ́ ọmọ ìlú Òkèmẹ̀sí (tí a mọ sì Ìmẹ̀sí Ìgbòdò) tí a bí ní ọdún 1849.[1] Bàbá rẹ̀ ni Adésóyè, tí í ṣe Àbúrò Fátìmẹ́hìn Apọ́nlẹ́sẹ̀, tí ó jẹ́ Ọwá Ooyè Kẹ̀sán -án ti ìlú Òkèmẹ̀sí. Ìyáa rẹ̀ jẹ́ Ọmọba tí ó wà láti ìlú Ogotun Èkìtì. Ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá nígbà tí Ìjẹ̀ṣà ṣẹ́gun ìlú Òkèmẹ̀sí, tí ó sì di eni wọ́n ta l'ójì sẹ́yìn odi òun àti Baba rẹ̀,. .[2] Ìlú Ìlá yìí ni Bàba rẹ̀ kú sí, tí ó sì fi gbogbo ọlá tí ó ní àti àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrú lé Fábùnmi tí í ṣe ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jù ninu ẹbí lọ́wọ́.[2] Ìyaarẹ̀ jẹ́ Ọmọba ìlú Ogotun ni Èkìtì.[2] Ìlú Ìlá tí ó wà ni o ti kọ́ ìṣe aṣọ ríran [2] Ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́-tímọ́ sí ọmọba Adéyalé tí Ìlú Ìlá tí ó sì padà jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun ní Ìlú Ìlá. Nígbà tí ó rín ìrìn àjò lọ sí Ìlú Ìbàdàn ló di ọmọ ogun leyin Akíntọ́lá, tí ó jẹ́ ọmọ kejì sí Balógun Ìbíkúnlé. Ó kópa nínú àwọn orísìírísìí ìgbáradì fún Ogun. Ó sá kúrò n'ílùù Ìbàdàn ni oru ọjọ́ kan nígbà tí ó gbọ́ pe wọ́n fẹ́ fi òun rúbọ àti fi òun ṣe nǹkan ètùtù fún Òrìsà ìlú wọn. Nígbà tí ó dé Ìlú Òkèmẹ̀sí láti Ìbàdàn, Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ránṣọ àti fi aṣọ yàwòrán tí ó sì ń kọ́ àwọn ẹrú baba rẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn ọ̀dọ́ ìlú tí wọ́n fẹ̀ nípa ogun jíjà ní ìgbáradì fún ogun tí ó ti mọ̀.[3] Wọ́n ṣàlàyé pé ènìyàn tí ó ga, tí ó sì mọ́ra tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dáńtọ́ tí kìí sì bẹ̀rù nípa ohun tí ó bá sọ ní ó jẹ́.
Ìgbẹ́ ayé gẹ́gẹ́ bí ológun
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 1878, òkìkí Fábùnmi kàn, ó sì di ìlú mọ̀ọ́ọ̀kaá látàrí ogun Kirìji tí ó jà tí ó sì ṣẹ́gun káàkiri ilé Yoruba.[3][4]
Ìgbé ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lẹ́yìn ogun Kírìjí, àwọn ọmọ ogun Fábùnmi bẹ̀rẹ̀ sí í hùwàkíwà bí i wíwọ oko olóko ní ọ̀nà àìtọ́, kíkó àwọn ohun ìní àwọn èèyàn, ìjínigbé.[5] Àmọ́ ni ọdún 1895, ọwọọ́ òfin bá Fábùnmi, tí wọ́n sì gbé lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn agbófinró aláwọ̀ funfun ní Odò -Otin, tí wọ́n sì kìí nílọ̀ gidi.[5] Lẹ́yìn ìgbà náà, Ó padà sí Òkèmẹ̀sí níbi tí ó gbìyànjú láti gba Adé ṣùgbọ́n pàbó ló jásí, èyí tí ó sì fà á kí wón le kúrò láàárín ìlú. .[6] Ní ọdún 1902, àwọn ará ìlú Ìmẹ̀sí -ilé wa lọ, wọ́n sì yàn -án sí pò gẹ́gẹ́ bí Ọba Aládé Kejìdínlógójì..[6] Ó wà ní pò fún odindin Oṣù Mẹ́fà kí ó tó kú ní ọdún 1903=":7" /> Ọmọ rẹ̀ L'ọjà Òkè Ládòkun Adéfénwá Fábùnmi kejì nii ó jẹ́ lẹ́yìn rẹ̀.[6]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Adekanla, Olabisi (1999). Imesi-Ile : the ancient Kiriji camp. Ibadan: Peetee Nigeria Ltd. pp. 96–98. ISBN 978-35009-0-2. OCLC 49823357. https://www.worldcat.org/oclc/49823357.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 2.3 Akintoye, S.A (1971). Revolution and Power Politics in Yorubaland 1840-1893. USA: Humanities Press Inc. pp. 89–90.
- ↑ 3.0 3.1 Akintoye, S.A (1971). Revolution and Power Politics in Yorubaland 1840-1893. USA: Humanities Press Inc. pp. 90–91.
- ↑ William., Ojo (1953). Folk history of Imesi Ile. Nigeria Magazine. pp. 98–117. OCLC 44043857. http://worldcat.org/oclc/44043857.
- ↑ 5.0 5.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:6
- ↑ 6.0 6.1 6.2 Adekanla, Olabisi (1999). Imesi-Ile : the ancient Kiriji camp. Ibadan: Peetee Nigeria Ltd. pp. 99. ISBN 978-35009-0-2. OCLC 49823357. https://www.worldcat.org/oclc/49823357.