Flora Shaw

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Flora Shaw, Aya Lugard
Lord and Lady Lugard.
Spouse of the Governor of Hong Kong
In office
29 July 1907 – 16 March 1912
GómìnàSir Frederick Lugard
AsíwájúEdith Blake
Arọ́pòHelena May
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Flora Louise Shaw

(1852-12-19)19 Oṣù Kejìlá 1852
Woolwich, England
Aláìsí25 January 1929(1929-01-25) (ọmọ ọdún 76)
Surrey, England
Ọmọorílẹ̀-èdèBritish
(Àwọn) olólùfẹ́
Frederick Lugard (m. 1902)
OccupationJournalist, novelist

Dame Flora Louise Shaw tí wọ́n ń dà pè ní Flora Shaw Jẹ́ aya alákòóso ilẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí ìyẹ Frederick Lugard ní àsìkò tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà ní oko ẹrẹ́ àmúnisìn àwọn Gẹ̀ẹ́sì. Wọ́n bi ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Kejìlá ọdún 1852, ó ṣaláìsí ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kíní ọdún 1929 (19 December 1852 – 25 January 1929). Ó jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdèBritani oníṣẹ́ ìròyìn àti ònkọ̀wé.[1] She is credited with having coined the name "Nigeria".[2]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Flora ní ojúlé kejì àdúgbò Dundas Terrace, ní agbègbè Woolwich ní Ìlú London, ó jẹ́ ọmọ àbílé k3rin nínú ọmọ mẹ́rìnlá ti bàbá rẹ̀ tí ó jẹ́ Gẹ̀ẹ́sì George Shaw bí, tí ìyá rẹ̀ Adrirenne Josephine sì jẹ́ ọmọ bíbí Mauritius ará Faransé.[1]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ ìròyìn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tí yàn láàyò ní ọdún 1886, nígbá tí ó kọ ìròyìn fún ilé-iṣẹ́ ìròyìn Pall Mall Gazette ati Manchester Guardian.[3] Òun ni ilé-iṣẹ́ Ìwé-ìròyìn ti Manchester Guardian rán lọ láti lọ kó àwọn ìròyìn kan jọ nípa àpérò tí ó fẹ́ wáyé ní orí awuye-wuye ìkorò ojú sí àti fífagi lé òwò-ẹrù tí ó fẹ́ wáyé ní Brussels. Lẹ́yìn iṣẹ́ yí, ó di ògbóntagì ònkọ̀ròyìn lórí "Ìmúnisì" fú ilé-iṣẹ́ The Times, èyí sì ni ó mu di obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ònkọ̀wé ìròyìn tí ó ń gba owó gidi jùlọ lásìkò náà. [3][4] Fúndí èyí, wọ́n ran ní iṣẹ́ pàtàkì kan tí ó jẹ́ iṣẹ́ àkanse sí apá Ìla Oòrùn Áfíríkà ní ọdún 1892 àti 1901. South Africa ní ọdún 1892 orílẹ̀-èdè Austrálíà ní ọdún 1901, New Zealand ní ọdún 1892,láti kọ́ nípa ohun tí ó ń lọ ní Kanaka tí àwọn òṣìṣẹ́ ti ń ṣíṣe nínú oko ìrèkéQueensland. Ìlú Penneshaw, South Australia ni wọ́n fi díẹ̀ lára orúkọ ìlú náà sorí Flora.[5] Ón tún kọ àwọn ìròyìn ọlọ́kan-ò-jọkan nípa ìlú Canada ní ọdún 1893 àti 1898. Ó tún kọ nípa ìwakùsà góòlùKlondike.[6][7]

Bí ó ṣe sọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórúkọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní àpilẹ̀kọ rẹ̀ kan tí ó jáde ní inú Ìwé-ìròyìn The Times ní ọjọ́ Kẹjọ oṣù Kíní ọdún 1897, ó dábàá orúkọ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú bí ó ṣe ṣe àfàyọ rẹ̀ láti ara orúkọ odò kan tí ó ń jẹ́ Niger River[2]. Nínú àpilẹ̀kọ ẹ̀ náà, ó fẹ́ kí orúkọ tí wọ́n ń pe ilé iṣẹ́ tí ó ń kọ́ ilé ọlọ́pọ̀ èrò tí ó jẹ́ ti àwọn Gẹ̀ẹ́sì tó ń jẹ́ "Royal Niger Company Territories" ó wà ní ìkékúrú bíi South Sudan ni ó fi ronú tí ó sì gbé Nigeria jáde. Ó ṣe èyí nínú ìrònú rẹ̀ wípé Sudan nííṣe pẹ́lú odò Náìlì, ìwòye yí ni ó wò tí ó fi to River Niger pọ̀ láti fi dá orúkọ fún náà sílẹ̀. Ó kọ nínú àpilẹ̀kọ rẹ̀ kan ní inú Ìwé-ìròyìn The Times ti ọjọ́ Kẹjọ oṣù Kíní ọdún 1897, wípé: "The name Nigeria applying to no other part of Africa may without offence to any neighbours be accepted as co-extensive with the territories over which the Royal Niger Company has extended British influence, and may serve to differentiate them equally from the colonies of Lagos and the Niger Protectorate on the coast and from the French territories of the Upper Niger."[8][9][10]

Àwọn Ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

[[Ẹ̀ka:Ìtàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà]]

  1. 1.0 1.1 Helly, Dorothy O.; Callaway, Helen (2004). Lugard, Dame Flora Louise, Lady Lugard (1852–1929) (May 2006 ed.). Oxford: Oxford Dictionary of National Biography. http://www.oxforddnb.com/index/38/101038618/. Retrieved 11 October 2014. 
  2. 2.0 2.1 Omoruyi, Omo (2002). "The origin of Nigeria: God of justice not associated with an unjust political order". ReworkNigeria. 
  3. 3.0 3.1 "Flora (née Shaw), Lady Lugard (1852-1929), Author and journalist; wife of Frederick Lugard, 1st Baron Lugard". National Portrait Gallery. Retrieved 11 October 2014. 
  4. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Meyer
  5. Rodney Cockburn (1908) What's in a name? Nomenclature of South Australia: Fergusson Publications ISBN 0-9592519-1-X
  6. Usherwood, Stephen. "From Our Own Correspondent: Flora Shaw on the Klondike". History Today. http://www.historytoday.com/stephen-usherwood/our-own-correspondent-flora-shaw-klondike. Retrieved 12 October 2014. 
  7. Àdàkọ:Cite EB1922
  8. Shaw, Flora (8 January 1897). "Letter". The Times of London: p. 6. 
  9. Correspondent, Special (2008). "Flora Shaw gives the name Nigeria" (PDF). Hogarth Blake. Retrieved 13 October 2014. 
  10. Kwarteng, Kwasi (2012). Ghosts of Empire : Britain's Legacies in the Modern World. (1st ed.). New York: Perseus Books Group. ISBN 978-1-61039-120-7. https://books.google.com/books?id=oQi7KqK6efQC&pg=PA273.