Jump to content

Genevieve Nnaji

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Genevieve Nnaji
Genevieve Nnaji ní ọjọ́ tó sí ilé ìránso St.Genevieve rẹ̀ ní Èkó, Nàìjíríà, May 2008
ÌbíGenevieve Nnaji
3 Oṣù Kàrún 1979 (1979-05-03) (ọmọ ọdún 45)[1]
Mbaise, Ipinle Imo, Nigeria
Iṣẹ́Òṣèré, Aṣoge, Akọrin

Genevieve Nnaji (pípè /n'nɑːdʒɪ/,[2] (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún 1979) jẹ́ ọmọ ìlú MbaiseÌpínlè Ímò, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà,[3] jẹ́ òṣeré sinima-agbelewo ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà.[4] Ní ọdún 2005, ó gba ẹ̀bùn Akedẹ́mì sinimá-àgbéléwò ilẹ̀ Áfíríkà gẹ́gẹ́ bí Òṣeré-bìnrin tó dárajùlọ.[5]

Ìlú Èkó ni Genevieve Nnaji dàgbà sí. Òun ni àbílékẹrin ọmọ nínú àwọn ọmọ méjọ tí òbí rẹ̀ bí, ọ̀mọ̀wé sì ni àwọn òbí rẹ̀. Bàbá rẹ̀ siṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi onímọ̀ iṣẹ́-ẹ̀rọ (engineer) nígbàtí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ olùkọ́. Ò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Methodist Girls College ní ìlú Yaba, lẹ́yìn rẹ̀ ó wọlé sí ilé-ẹ̀kọ́ Fàsítì ìlú Èkó. Níbẹ̀ lówà tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣiṣẹ́ díẹ̀ díẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi òṣèré ni Nollywood.[5]

Nnaji bẹ̀rẹ̀ ìṣèré rẹ̀ láti ọmọdé ninu eré tẹlifísọ̀n Ripples nígbà tójẹ́ ọmọ ọdún méjọ. Ó tún ṣe ìpolówó ọjà bíi méèló kan nínú èyí tó jẹ́ fún Pronto àti ọṣẹ ìfọsọ Omo. Ní 2004 ó di aṣojú fún ọsẹ ìwẹ̀ Lux[6], ìbáṣe ìgbọ̀wọ́ tọ́ fa èrè ínlá wá fun.[5]

Ni 1998 nígbà tójẹ́ ọmọ ọdún 19 wọn ṣe àmúhàn rẹ̀ sí àwọn olólùfẹ́ sinima-agbelewo ni Nàìjíríà pẹ̀lú filmu tó ún jẹ́ Most Wanted. Lẹ́yìn rẹ̀ ó tún ṣe àwọn sinima-agbelewo bíi Last Party, Mark of the Beast àti Ijele. Ó ti kópa nínúu filmu tó tó 80 ni Nollywood.[7]

Nnaji ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn fún iṣẹ́ rẹ̀. Ìkan nínú wọn jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi òṣèré obìnrin tó dárajùlọ fún 2001 ní City People Awards, ó sì tún gba ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bíi Òṣèré-bìnrin tó dára jùlọ ní 2005 nínú àwọn Ẹ̀bùn Akadẹ́mì sinima-agbelewo ilẹ̀ Áfríkà.

Ní 2004, ó tọwọ́ bọ̀wé pẹ̀lú ilé ìṣẹ́ àwo-orin ilẹ̀ Ghana, EKB Records láti gbé àwo-orin àkọ́kọ́ rẹ̀ jáde tó ún jẹ́ One Logologo Line,[8] àdàlú orin R&B, Hip-Hop àti Urban.[9]

Ní 2008 ni ó ṣí ilé ìránsọ rẹ̀ tó ún jẹ́ "St. Genevieve", èyí tó ún ṣọrẹ ìdámẹ́ẹ̀wá èrè rẹ̀.[10][11][12]

Ní Nollywood, Genevieve Nnaji jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí owó iṣẹ́ wọn pọ̀jùlọ.[13]

Àwọn àkójọ sinima-agbelewo rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Filmu Eré Àjákọ
1998 Most Wanted
1999 Camouflage pẹ̀lú Ramsey Nouah
2001 Love Boat with Ramsey Nouah
Death Warrant
2002 Valentino pẹ̀lú Ramsey Nouah
Sharon Stone Sharon Stone
Runs! pẹ̀lú Gorgina Onuoha
Power of Love Juliet pẹ̀lú Ramsey Nouah, Grace Amah
Formidable Force pẹ̀lú Gorgina Onuoha
Battle Line pẹ̀lú Ramsey Nouah & Pete Edochie
2003 Above Death: In God We Trust pẹ̀lú Pete Edochie, Kate Henshaw-Nuttal, Ramsey Nouah & Zack Orji
Blood Sister pẹ̀lú Omotola Jalade-Ekeinde & Tony Umez
Break Up pẹ̀lú Ramsey Nouah
Butterfly pẹ̀lú Ramsey Nouah
By His Grace pẹ̀lú Tony Umez
Church Business pẹ̀lú Ramsey Nouah & Segun Arinze
Deadly Mistake
Emergency Wedding pẹ̀lú Tony Umez
Emotional Tears Helen
For Better for Worse
Honey pẹ̀lú Ramsey Nouah & Pete Edochie
Jealous Lovers Chioma
Keeping Faith: Is That Love? pẹ̀lú Richard Mofe-Damijo
Last Weekend pẹ̀lú Ramsey Nouah
Late Marriage
Love Anita pẹ̀lú Richard Mofe-Damijo & Segun Arinze
My only Love Angela pẹ̀lú Ramsey Nouah
Not Man Enough
Passion & Pain pẹ̀lú Ramsey Nouah & Desmond Elliot
Passions pẹ̀lú Stella Damasus-Aboderin & Richard Mofe-Damijo
Player: Mr. Lover Man
Private Sin Faith pẹ̀lú Richard Mofe-Damijo & Stephanie Okereke
Sharon Stone in Abuja Sharon Stone
Super Love pẹ̀lú Ramsey Nouah & Pete Edochie
The Chosen One
Women Affair
2004 Bumper to Bumper pẹ̀lú Georgina Onuoha
Critical Decision pẹ̀lú Richard Mofe-Damijo & Stephanie Okereke
Dangerous Sister pẹ̀lú Tony Umez & Dakore Egbuson
Goodbye New York pẹ̀lú Rita Dominic
He Lives in Me
Into Temptation pẹ̀lú Ramsey Nouah
My First Love pẹ̀lú Tony Umez
Never Die for Love
Promise Me Forever pẹ̀lú Stephanie Okereke
Stand by Me
Treasure
Unbreakable pẹ̀lú Ramsey Nouah
We Are One pẹ̀lú Stella Damasus-Aboderin
2005 Darkest Night pẹ̀lú Richard Mofe-Damijo & Segun Arinze
Games Women Play pẹ̀lú Stella Damasus-Aboderin, Desmond Elliot & Zack Orji
Rip-Off pẹ̀lú Ramsey Nouah
2006 Girls Cot pẹ̀lú Rita Dominic & Ini Edo
30 Days Chinora Onu pẹ̀lú Segun Arinze
2007 Letters to a Stranger pẹ̀lú Segun Arinze
Warrior's Heart
2008 Beautiful Soul Olivia
Broken Tears pẹ̀lú Van Vicker, Kate Henshaw-Nuttal and Grace Amah
My Idol
River of Tears Yvonne

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Actress Genevieve Nnaji clocks 43". Punch Newspapers. May 3, 2022. Retrieved May 29, 2022. 
  2. Movie trailer calling Nnaji's name at 2:36 into the trailer
  3. Genevieve Nnaji, Date of Birth
  4. "Genevieve Nnaji post first video afta she remove everitin from her Instagram page - BBC News Pidgin". BBC News Pidgin. May 11, 2022. Retrieved May 29, 2022. 
  5. 5.0 5.1 5.2 "Africa’s Most Famous Movie Star?". Archived from the original on 2010-05-02. Retrieved 2009-09-26. 
  6. "Genevieve Nnaji & Lux advertisement". Archived from the original on 2009-07-26. Retrieved 2009-09-26. 
  7. Àkójọ àwọn filmu Genevieve Nnaji
  8. "Genevieve at Blue Pie Productions". Archived from the original on 2012-05-24. Retrieved 2009-09-26. 
  9. "Genevieve: One Logologo Line". Archived from the original on 2008-12-03. Retrieved 2009-09-26. 
  10. "Genevieve starts clothing line". Archived from the original on 2010-05-13. Retrieved 2009-09-26. 
  11. "Genevieve Nnaji at TalkZimbabwe.com". Archived from the original on 2008-10-15. Retrieved 2009-09-26. 
  12. Genevieve Nnaji at Gistmaster.com
  13. Best Paid Nollywood Actresses Revealed

Ìjápọ̀mọ́ nínu ero-ayelujara

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]