Ijakumo
Ijakumo | |
---|---|
Adarí | Adebayo Tijani Steve Sodiya |
Olùgbékalẹ̀ | Toyin Abraham |
Òǹkọ̀wé | Kehinde Joseph |
Àwọn òṣèré | Toyin Abraham Kunle Remi Lolade Okusanya Bimbo Akintola Olumide Oworu |
Orin | Abosede Peace |
Ìyàwòrán sinimá | Idowu 'Mr Views' Adedapo |
Olóòtú | Steve Sodiya Agboola Ola'Kazeem |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Toyin Abraham Films Production |
Olùpín | FilmOne Distribution |
Déètì àgbéjáde | 23 December 2022 |
Àkókò | 120 Minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | English, Yoruba, Igbo, Hausa |
Owó àrígbàwọlé | ₦278,496,384[1] |
Ijakumo (The Born Again Stripper) jẹ́ fíìmù ajẹmọ́-ìṣiyèméjì ti ọdún 2022, èyí tí Toyin Abraham gbé jáde, tó sì di àgbéléwò ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kejìlá, ọdún 2022.[2] Àwọn tó kópa nínú eré náà ni Toyin Abraham, Kunle Remi, Lolade Okusanya, Bimbo Akintola, Olumide Oworu, Lillian Afegbai àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[3] Kehinde Joseph ni olùkọ̀tàn, nígbà tí Adebayo Tijani sì jẹ́ olùdarí.[3]
Ìsọníṣókí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ijakumo (The Born Again Stripper) sọ nípa ìtàn Asabi (Toyin Abraham), tó jẹ́ ọmọ oníṣègùn alágbára kan tó ń lépa láti ba ayé olólùẹ́ àtijọ́ rẹ̀ jẹ́, ní ẹni tó ti di pásítọ̀ ńlá kan ní ìlú Èkó, ìyẹn Jide(Kunle Remi) tó yàn án jẹ, tó sì fi í lẹ̀ kó kú. Pastor Jide tí kì í ṣe ènìyàn Ọlọ́rún, àmọ́ tó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ òkùnkùn kan tó máa ń wùwà àìtọ̀. Nínú ìgbìyànjú rẹ̀ láti ba ayé Jide jẹ́, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Sharon(Lolade Okusanya), ẹni tó jẹ́ oníjó-kílọ́ọ̀bù àti akọrin ní ṣọ́ọ̀ṣì Jide, tó wá ń wá ìṣubú rẹ̀.[4]
Àwọn akópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Toyin Abraham ni Asabi
- Kunle Remi nii Pastor Jide
- Lolade Okusanya nii Sharon and Mary
- Olumide Oworu ni Young Jide
- Debbie Shokoya ni Young Asabi
- Bimbo Akintola
- Kolawole Ajeyemi
- Lilian Afegbai
- Antar Laniyan
- Eso Dike
- Tomiwa Tegbe
- Deborah Ajijolajesu Shokoya
Ìgbéjáde
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn bí i Gómínà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo Olu, àti àwọn gbajúmọ̀ òṣèré mìíràn ló farahàn níbi ìṣàfihàn àkọ́kọ́ ti fíìmù yìí. Àwọn ẹlòmìíràn tó farahàn ni Odunlade Adekola, Iyabo Ojo, Lateef Adedimeji àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[5] [6]
Àmì-ẹ̀yẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Award | Category | Recipient | Result | Ref |
---|---|---|---|---|---|
2023 | Africa Magic Viewers' Choice Awards | Best Picture Editor | Steve Sodiya | Wọ́n pèé | [7][8] |
Best Sound Editor | Kazeem Agboola | Wọ́n pèé | |||
Best Cinematographer | Idowu Adedapo | Wọ́n pèé |
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Top 20 films 30th December - 1st January 2023 - Cinema Exhibitors Association of Nigeria". www.ceanigeria.com.
- ↑ Udugba, Anthony (2022-12-17). "Ijakumo: Toyin Abraham’s first Christmas holiday release promises to be unlike any tale seen on the big screen (Exclusive Interview)". Businessday NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-24.
- ↑ 3.0 3.1 "Toyin Abraham Plays Stripper in ‘Ijakumo’ – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2022-12-24.
- ↑ Nwogu, Precious 'Mamazeus' (2022-09-13). "Toyin Abraham unveils first photos of forthcoming thriller 'Ijakumo'". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-24.
- ↑ "Toyin Abraham attracts Sanwo-Olu, others for ‘Ijakumo’ premiere". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-12-24. Retrieved 2022-12-24.
- ↑ BellaNaija.com (2022-12-20). "Nollywood Stars Stepped Out for the Premiere of Toyin Abraham Ajeyemi’s Film “Ijakumo: The Born Again Stripper” | See Photos". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-24.
- ↑ "Full List: Here are all our AMVCA 9 Nominees". AMVCA - Full List: Here are all our AMVCA 9 Nominees (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-04-23.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "AMVCA 2023 Winners List: Osas Ighodaro, Tobi Bakre, Anikulapo win for dis year Africa Magic Viewers Choice Award". BBC News Pidgin. 2023-05-20. Retrieved 2023-06-04.