Kíndìnrín

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Kidneys
The kidneys lie in the retroperitoneal space behind the abdomen, and act to filter blood to create urine.
View of the kidneys from behind, showing their blood supply and drainage.
Details
SystemUrinary system and endocrine system
ArteryRenal artery
VeinRenal vein
NerveRenal plexus
Identifiers
LatinRen
GreekNephros
TAA08.1.01.001
FMA7203
Anatomical terminology

kíndìnrín jẹ́ àwọn ẹ̀yà ara inú méjì tí Ìrísí wọn dà bí ẹ̀wà, tí a lè ṣalábàápàdé rẹ̀ ní árá gbógbó ẹranko élégúngún. Àwọn kíndìrín yí wà ní apá ọ̀tún àti apá òsí ní ìsàlẹ̀ àyà. Àwọn kíndìnrín wọ̀nyí ma ń gba ẹ̀jẹ̀ sára láti ara iṣan tí ó só pọ̀ mọ́ ọkàn tí wọ́n ń pè ní renal arteriee. Kíndìnrín kọ̀ọ̀kan ni ó tún so mọ́ iṣan mìíràn tí wọ́n ń pè ní (ureter), iṣan yí ni ó ń ran àwọn kíndìnrín yí lọ́wọ́ láti máa gbé ìtọ̀ láti inú kíndìnrín lọ sí inú ilé tàbí àpò ìtọ̀ tí wọ́n ń pè ní (bladder).

Àtúpalẹ̀ iṣẹ́ Kíndìrín[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nínú kíndìnrín kọ̀ọ̀kan ni a ti rí àwọn iṣàn wẹ́wẹ̀wẹ́ í orúkọ wọn ń jẹ́ (nephron) tí ó tó Mííọ́nù kan níye, tí wọn kò tẹ́ẹ́rẹ́ ju irun orí lọ tí ojú lásán kò lè rí, àyàfi pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìwògbè (microscope), tí àwọn iṣan wẹ́wẹ̀wẹ́ wọ̀nyí náà tún gbọ́mọ pọ̀n. Nínú àwọn iṣan wẹ́wẹ́ yìí ni ìṣàyípadà ní omi àti ẹ̀jẹ̀ tí kò wúlò fún ara mọ́ ti ma ń yí padà sí ìtọ̀ tí yóò sì bá ojú ara ọkùnrin àti obìnrin jáde láti ilé ìtọ̀. Bákan náà ni kíndìnrín tún ń kópa pàtàkì nínú ṣíṣètò àti dídarí omi,ẹ̀jẹ̀, ásíídì, àti yíyọ àwọn ohun tí kò da kúrò lára. Kíndìnrín ni a lè pè ní asẹ́ tí ó ń jọ gbogbo ohun bíi omi, ẹ̀jẹ̀, àti ásíídì àti àwọn nkan mìíràn tó bá gba ọ̀dọ̀ rẹ̀ kọjá .[1]

Àwọn Ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Cotran, RS S.; Kumar, Vinay; Fausto, Nelson; Robbins, Stanley L.; Abbas, Abul K. (2005). Robbins and Cotran pathologic basis of disease. St. Louis, MO: Elsevier Saunders. ISBN 978-0-7216-0187-8.