Kesari (fíìmù 2018)
Kesari jẹ́ fíìmù Yorùbá ti Nàìjíríà tó jáde ní ọdún 2018[1], èyí tí Ibrahim Yekini gbé jáde. Tope Adebayo sì ni olùdarí fíìmù yìí.[2][3][4]
Ìṣàgbéjáde
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nùwo kan, Ibrahim Yekini tó jẹ́ òǹkọlwé àti olùgbéjáde sọ ọ́ di mímọ̀ pé fíìmù Black Panther tí òun wò ló fún òun ní ìwúrí láti kọ fíìmù yìí.[5]
Àwọn akópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Femi Adebayo
- Ibrahim Yekini
- Akin Olaiya
- Kemi Afolabi
- Adebayo Salami
- Muyiwa Ademola
- Toyin Abraham
- Antar Laniyan
- Bimbo Akintola Odunlade
Ìsọníṣókí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọlọ́ṣà kan tó ní oògùn burúkú lọ́wọ́ pàdé ẹni tó kápá rẹ̀, àmọ́ ọlọ́pàá ni ẹni yìí jẹ́.
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fíìmù yìí gba àmì-ẹ̀yẹ fún fíimù tó dára jù àti olùgbéjáde tó dára jù ní abẹ́ ìsọ̀rí fíìmù Yorùbá ní ayẹyẹ City People Entertainment Awards.[6]
Àwọn èyí tó tẹ̀le
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fìímù náà ni apá mẹ́ta, tí í ṣe: Kesari 2, Return of Kesari, àti Return of Kesari 2. Yekini gba àmì-ẹ̀ye fún òṣèré tó dára jù lọ ní ayẹyẹ Best of Nollywood Awards, ti ọdún 2019, fún ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù Return of Kesari.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Àdàkọ:Cite AV media
- ↑ Online, Tribune (2019-07-06). "Why I dumped boxing for acting —Actor Itele". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-30.
- ↑ "I was inspired by Black Panther to write Kesari – Itele". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-07-21. Retrieved 2022-07-30.
- ↑ Alao, Biodun (2019-10-14). "ITELE's New Movie, KESARI Gathers 1.8 Million Views". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-30.
- ↑ "I was inspired by Black Panther to write Kesari – Itele". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-07-21. Retrieved 2022-07-30.
- ↑ Reporter (2019-10-14). "Yoruba Movie Winners Emerge @ City People Movie Awards". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-30.
- ↑ "Best Of Nollywood Lights Up Kano". The Guardian Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-12-21. Archived from the original on 2019-12-21. Retrieved 2022-07-30.