Jump to content

King of Boys

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
King of Boys
AdaríKemi Adetiba
Olùgbékalẹ̀
Òǹkọ̀wéKemi Adetiba
Àwọn òṣèré
Ìyàwòrán sinimá
  • Idowu Adedapo
  • Olabode Lawal
Ilé-iṣẹ́ fíìmùKemi Adetiba Visuals
OlùpínFilmOne Distributions
Déètì àgbéjáde
  • 20 Oṣù Kẹ̀wá 2018 (2018-October-20)
Àkókòìṣẹ́jú 169
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Èdè
Owó àrígbàwọlé₦ 245 mílíọ̀nù [1]

King of Boys jẹ́ fíìmù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jáde ní ọdún 2018 tí ó dálé lórí ọ̀ràn dídá àti ìjàkadì fún agbára àti ipò. Kemi Adetiba ló kọ fíìmù yìí, òun sì ni ó darí rẹ̀ tí ó sì gbe jáde pẹ̀lú. Fíìmù yìí jẹ́ fíìmù ẹlẹ́ẹ̀kejì tí arábìnrin Kemi Adetiba gbé jáde lẹ́yìn tí ó gbé The Wedding Party[2] jáde. Fíìmù yìí tún so arábìnrin yìí papọ̀ mọ́ Adesua Etomi àti Sola Sobowale lẹ́ẹ̀kan si lẹ́yìn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ lórí fíìmù The Wedding Party.[3] Fíìmù yìí dojúkọ rògbòdìyàn tí ó wáyé láti pasẹ̀ ìjàkadì fún agbára. Àwọn olórin bíi Illbliss àti Reminisce kópa nínú fíìmù yìí.[4][5][6] Àwọn akópa mìíràn ni Paul Sambo, Osas Ajibade, Toni Tones, Sani Muazu, Demola Adedoyin àti Akin Lewis.[7]

King of Boys sọ̀rọ̀ nípa ìtàn arábìnrin Alhaja Eniola Salami tí Sola Sobowale ṣe, ó jẹ́ obìnrin oníṣòwò àti ẹlẹ́yinjúàánú pẹ̀lú ọjọ́ iwájú tó dáa nínú ètò òṣèlú. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ja ìjàkadì fún ipò àti agbára, èyí sì mú ìbẹ̀rùbojo bá gbogbo ohun tó yí i ká nítorí ìwà ọ́kánjúà fún ipò òṣèlú. Akitiyan láti borí èyí mu kí ó bá ara rẹ̀ nípò àìrẹ́nigbẹ́kẹ̀lé, èyí sì sọ ọ́ di àìláàánú èèyàn.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "King of Boys (2018) Box Office - nlist". Nollywood, Nigerian Movies & Casting. 2018-10-26. Retrieved 2022-10-29. 
  2. Izuzu, Chidumga (21 May 2018). "Plot for Kemi Adetiba's anticipated movie revealed". Pulse Nigeria. Archived from the original on 14 October 2018. https://web.archive.org/web/20181014091622/https://www.pulse.ng/entertainment/movies/plot-for-kemi-adetibas-new-film-king-of-boys-id8402047.html. Retrieved 9 October 2018. 
  3. Dayo, Bernard (13 August 2018). "You guys, the trailer for Kemi Adetiba’s "King of Boys" is here and it will make your heart race". YNaija. https://www.ynaija.com/you-guys-the-trailer-for-kemi-adetibas-king-of-boys-is-here-and-it-will-make-your-heart-race/amp/. Retrieved 9 October 2018. 
  4. Ono, Bello (18 January 2018). "Watch Out For Reminisce As He Makes Debut In Nollywood Movie "King Of Boys"". OnoBello. Archived from the original on 28 November 2020. https://web.archive.org/web/20201128204936/http://onobello.com/watch-out-for-reminisce-as-he-makes-debut-in-nollywood-movie-king-of-boys/. Retrieved 9 October 2018. 
  5. Alli, Mutiat (20 January 2018). "Illbliss joins cast list of Kemi Adetiba’s ‘King of Boys’". Daily Times. https://dailytimes.ng/illbliss-joins-cast-list-kemi-adetibas-king-boys/. Retrieved 9 October 2018. 
  6. Odejimi, Segun (18 January 2018). "Illbliss, Reminisce, Omoni Oboli, Adesua Etomi To Star In Kemi Adetiba’s "King Of Boys"". TNS. Archived from the original on 22 October 2020. https://web.archive.org/web/20201022035835/https://tns.ng/illbliss-reminisce-omoni-oboli-adesua-etomi-to-star-in-kemi-adetibas-king-of-boys/amp/. Retrieved 9 October 2018. 
  7. Cable Lifestyle (2 May 2018). "Boys’ teaser reveals little but will keep you in suspense". The Cable Nigeria. https://lifestyle.thecable.ng/kemi-adetiba-king-of-boys-teaser/. Retrieved 29 October 2018.