Koseegbe
Koseegbe | |
---|---|
Fáìlì:Koseegbe poster.jpeg | |
Adarí | Tunde Kelani |
Olùgbékalẹ̀ | Tunde Kelani |
Òǹkọ̀wé | Akinwunmi Isola |
Àwọn òṣèré | Kola Oyewo Wole Ameleo Jide Kosokoo Toyin A Babatope |
Olóòtú | Idowu Nubi |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Mainframe Films and Television Productions |
Olùpín | Alasco Video Film Production Blessed J.O. Adeoye Alelele Bros. & Co |
Déètì àgbéjáde | 1995 |
Àkókò | 102 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | Yoruba Language |
Kòseégbé jẹ́ fíìmù Yorùbá ti ọdún 1995, tí Tunde Kelani darí. Fíìmù yilí dá lórí eré orí-ìtàgé kan tí Akínwùmí Iṣọ̀lá ṣe. Àwọn akópa náà jẹ́ òṣèré láti tíátà Obafemi Awolowo University.[1] Wọ́n ṣàgbéjáde rẹ̀ láti ọwọ́ Mainframe Films and Television Productions.[2]
Àhunpọ̀ ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Koseegbe jẹ́ ìtàn tó dá lórí òṣìṣẹ́ kọ́sítọ́ọ̀mù kan tó ń hùwà tó tọ́. Òṣìṣẹ́ yìí ni wọ́n fi rọ́pọ̀ ọ̀gá kan tó ń hùwá̀ ìbàjẹ́, tí wọ́n sì lé lọ. Ní ibi iṣẹ́ tuntun rẹ̀, ó gbìyànjú láti tún ibiṣẹ́ náà ṣe àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó kéré níbẹ̀ ò gbà fún un. Nínú ìgbìyànjú wọn láti le kúrò ní ibiṣẹ́, wọ́n fi ẹ̀sùn burúkú kan kàn án. Ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó borí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe fún ìparun rẹ̀.[3][4]
Àwọn Akópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Kola Oyewo
- Wole Amele
- Jide Kosoko
- Toyin A Babatope
- Yetunde Ogunsola
- Joke Muyiwa
- Yemi Sodimu
- Laide Adewale
- Gboyega Ajayi
- Jimoh Fakoyejo
- Faith Eboigbe
- Taiye Adegboyega
- Feso Oyewole
- Peter Fatomilola
Ìgbéjáde
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Koseegbe jẹ́ fíìmù ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí Tunde Kelani á ṣe, ó sì jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ pẹ̀lú Akínwùmí Iṣọ̀lá. Ó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i eré orí-ìtàgé, pẹ̀lú àkólé kan náà láti ọwọ́ Isola. Wọn ò rí àkọsílẹ̀ fún fíìmù náà ní ìgbà yẹn. Kelani ló ṣẹ̀ wá fún wọn ní Driving Miss Daisy láti fi ṣe àtẹ̀gùn.[5] Wọ́n gbe jáde ní ọdún 1995.[6]
Wọ́n sì tò ó pọ̀ mọ́ ọ̀kan lára àwọn fíìmù Yorùbá mẹ́wàá tó tà jù lọ ní lásìkò náà.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Ogunleye, Foluke (2003) (in en). African Video Film Today. Integritas Services. pp. 146. ISBN 978-0-7978-2931-2. https://books.google.com/books?id=zRFT6I6vM_sC&dq=Koseegbe&pg=PA146.
- ↑ Izuzu, Chibumga (2017-03-09). "Who remembers Tunde Kelani's 1995 movie "Koseegbe?"". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-08-20.
- ↑ Ogundipe, Ayodele (2004). Gender and Culture in Indigenous Films in Nigeria. pp. 93–94. Archived from the original on 2022-03-05. https://web.archive.org/web/20220305174322/https://codesria.org/IMG/pdf/GA_Chapter-6_ogundipe.pdf. Retrieved 2021-07-07.
- ↑ Afolabi, Omoniyi (2011). "Yoruba Films By Tunde Kelani: Primary Cultural And Linguistic Data Collection" (PDF). Archived from the original (PDF) on 2021-10-14. Retrieved 2024-02-13.
- ↑ Haynes, Jonathan (2016-10-04) (in en). Nollywood: The Creation of Nigerian Film Genres. University of Chicago Press. pp. 131. ISBN 978-0-226-38795-6. https://books.google.com/books?id=cHUpDQAAQBAJ&dq=Koseegbe&pg=PA131.
- ↑ Oyewo, Kola; Babatope, Toyin A; Amele, Wole; Kosoko, Jide; Ogunmola, Peju; Shodimu, Yemi; Ojeyemi, Tunji; Eboigbe, Faith; Ogunsola, Yetunde (1995), Kòṣeégbé, Lagos [Nigeria: Mainframe : Distributors Alasco Video Film Production, Blessed J.O. Adeoye, Alelele Bros. & Co., OCLC 39878333, retrieved 2021-08-20
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:02