Nigeria Advance Party

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

 Egbe oselu  Nigeria Advance Party (NAP) ni won da sile ni asiko isejoba awa arawa  elekeji  (Second Nigerian Republic) ni ile Naijiria ti o si foruko sile fun eto idibo odun 1983. Eni ti o je olori egbe oselu naa ni  Tunji Braithwaite, ti o je agbejoro. Won faye gba egbe naa lati fa oludupo ti yoo kopa ninu eto idiboyan odun 1983. Awon ti won korajo po sinu egbe  naa ni won je eniyan apa ariwa orile ede Naijiria ti won duro lori atutnto eto isejoba awa arawa ile Naijiria.[citation needed]

Itan egbe oselu naa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Won fi egbe naa loole ni ojo Ketala osu Kewaa odun 1978 (13 October 1978)  ni ilu Ibadan. Awon adari egbe naa gbe igbese ti o nipon lori eto eko ofe, sugbon ti won pada yi ipinu won pada wipe ki eto eko ile eko alakoobere ati ile eko agba Fasiti (Universities) gbogbo o je ofe fun teru tomo.  Egbe naa duro lori wipe awon yato awon si dara ju awon egbe oselu ti o ti koko wa ni asiko isejoba awa arawa  first republic alakooko lo.

Laarin odun meji akoko ti won da egbe nan kale ni ile olominira Naijiria foju wina isejoba ologun ti ogagun  Olusegun Obasanjo je eni ti o keyin olori ologun orile ede naa nigba ti o gbejoba kale fun alagbada ki won le dibo odun 1983. Tunji Braithwaite ti o je oju lowo omo ipinle Eko ni o fese re mule wipe ijoba awa arawa ko le se aseyori bi ko ba se atunto ki o si fopin si iwa ajebanu. Lara awon laami laaka alenu-loro ti o fara mo aba Tunji Braithwaite yi ni ojogbon Wole Soyinka, ati  Fela Anikulapo Kuti, eni ti awon omo ogun ile seku pa iya re ti won si ba ile re (Kalakuta Republic) je lasiko ijoba ologun ti ogagun  Obasanjo je ogagun orile ede Naijiria

Eto ipolongo ibo egbe naa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni December 1978,meta lara egbe ti kii se ti ijoba dara po mo egbe oselu naa. Awon egbe naa ni: Ajo awon ayale gbe ati ajo osise (Nigeria Tenants and Labour Congress) ile Naijiria, ti ogbeni  I.H. Igali, je olori won. Ajo  (Nigeria Social Democratic Congress),ti ogbeni Balali Dauda je olori won, ati Ajo (Youth Force Alliance), ti ogbeni Olayinka Olabiwonu je olori won. Sugbon, won fagile iforuko sile won leyin osu meji ti won ti foruko sile sodo ajo eleto idibo, latari aini iranlowo to lati odo awon eniyan labele (grass-root support).

Idibo odun 1983[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Egbe oselu yii ti  Tunji Braithwaite je okan lara awon mefa ti o dupo dije su ipo Aare labe asia egbe oselu naa ni odun 1983. Awon eniyan dibo yan Shehu Shagari ti o je omo ebge oselu  National Party of Nigeria (NPN) sipo Aare  nigba ti o jawe olubori pelu ami ibo ti o to  45%.

Ni  7 December 2012, egbe oselu (NAP) je okan lara awon egbe oselu mejidinlogbo ti won yoo tun oruko fi sile labe ajo eleto idibo  INEC fun eeto ipolongo ibo odun  2015.