Olawale Adeniji Ige
Olawale Adeniji Ige | |
---|---|
Minister of the Federal Ministry of Aviation | |
In office 1993–1994 | |
Minister of the Federal Ministry of Communications | |
In office 1990–1992 | |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Lagos, Nigeria | 13 Oṣù Kẹ̀wá 1938
Aláìsí | 9 May 2022 | (ọmọ ọdún 83)
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Non-Partisan |
Olawale Adeniji Ige MFR (13 October 1938 – 9 May 2022)[1] fìgbà kan jẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ àti mínísítà tó ń rí sí ètò ìbánisọ̀rọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, láti ọdún 1990 wọ 1992.[2] Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i mínísítà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ọkọ̀ òfuurufú(1993).[3]
Ayé àti iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí i ní 13 October, ọdún 1938 ní Ògbómọ̀ṣọ́, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní orílẹ̀-èdè Naijiria. Ó kàwé ní Baptist Boys High School, ní Abẹ́òkúta, tó jẹ́ olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn, ní Nàìjíríà, láti ọdún 1951 wọ 1956. Ibí sì ni ó ti gba ìwé-ẹ̀rí West African School Certificate (WASC). Ó tẹ̀síwájú láti lọ Polytechnic, Regent Street, London tó ti di University of Westminster, níbi tí ó ti gba oyè Diploma nínú ìmọ̀ electrical engineering.[4] Ó padà di akẹ́kọ̀ọ́ gboyè láti Institute of Electrical and Electronics Engineers ní ọdún 1965.[5]
Ó padà sí Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ ní ọdún 1967, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Federal Ministry of Communications níbi tí ó ti di olùdarí àgbà ní ọdún 1989.[6][7] Wọ́n yàn án sí ipò mínísítà tó ń rí sí ètò ìbánisọ̀rọ̀ ní ọdún 1990, títí wọ ọdún 1992. Wọ́n sì tún yàn án gẹ́gẹ́ bí i mínísítà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ọkọ̀ òfuurufú, ni họdún 1993.[8] Òun ni alága àkọ́kọ́ ti Nigerian Telecommunications Limited, NITEL, tí kì í ṣe ológun. Bákan náà, òun ni alága ìgbìmọ̀ Nigerian Internet Group,[9] ó sì tún wà lára àwọn ìgbìmọ̀ Nigerian Communications Commission, NCC.[10]
Àmì-ẹ̀yẹ àti ẹgbẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Member of the Order of the Federal Republic, MFR (1979)
- Fellow of the Nigerian Academy of Engineering[11]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ex-Minister Of Communications, Ige, Dies At 83". 12 May 2022. Retrieved 11 May 2023.
- ↑ Awoyemi Femi. "NIG has been pivotal to ICT in Nigeria-Engr Olawale Ige MFR Former Minister of Communications, Nige". proshareng.com. http://www.proshareng.com/news/20098.
- ↑ "Nigeria: NIG to Focus On Broadband Devt At 2013 AGM". ictafrica.info. Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2024-02-08.
- ↑ RapidxHTML. "The Nigeria Academy of Engineering :: promoting excellence in technology and engineering training and practice to ensure the technological growth and economic development of Nigeria". nae.org.ng. Archived from the original on 2016-12-17. Retrieved 2024-02-09.
- ↑ Cyril Okoye (14 September 2010). "Ige, Ndukwe to Lead Talks at ICT Celebration". allAfrica. Vanguard. http://allafrica.com/stories/201009150435.html. (subscription required)
- ↑ "open access fibre Archives - Technology Times Hub". Technology Times Hub.
- ↑ "Rural Telephony: MTN covers 350 uncovered villages with smart technology". Vanguard News. 26 October 2010.
- ↑ "Ndukwe, Ige for celebration of 50 years of ICT tomorrow". Vanguard News. 28 September 2010.
- ↑ "Nigeria Internet Group - Board of Trustees". nig.org.ng. Archived from the original on 2016-03-03. Retrieved 2024-02-09.
- ↑ "Olawale Ige". Nigeria CommunicationsWeek. Archived from the original on 2016-03-24. Retrieved 2024-02-09.
- ↑ "GMD Bags Fellowship of Nigerian Academy of Engineering > NNPC". nnpcgroup.com. Archived from the original on 2016-04-05. Retrieved 2024-02-09.