Rachel Oniga
Rachel Oniga | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 23 Oṣù Kàrún 1957 Ebute Metta, Lagos, Lagos State, Nigeria. |
Aláìsí | 2021 |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Orúkọ míràn | Tabuno |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | film actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 1993-2022 |
Notable work | Sango (Film) |
Rachel Oniga (tí a bí ní 23 Oṣù Kaàrún, Ọdún 1957) jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[1]
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti iṣẹ̀ ìṣe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Rachel Oniga wá láti agbègbè Eku, ní Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà ṣùgbọ́n tí a bí ní Èbútté Mẹ́tta, Ìpínlẹ̀ Èkó.[2] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ní ọdún 1993 ní kété tí ó pínyà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀.[3] Ó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ fún ìgbà díè ní ilé-iṣẹ́ alámọ̀ràn Ascoline Nigeria Limited, ṣááju kí ó tó kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀, èyí tó wáyé nínu sinimá tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Ọnọmẹ́. Ṣùgbọ́n àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu eré èdè Yorùbá wáyé níbi kíkópa rẹ̀ nínu Owó Blow.[4] Ó ti wá ṣe bẹ́ẹ̀ kópa nínu àwọn fíìmù míràn tó lórúkọ bíi fíìmù Ṣàngó, èyí tí Wálé Ògúnyẹmí kọ, tí Ọbáfẹ́mi Lasode sì ṣe àgbékalẹ̀ àti ìdarí rẹ̀.[5] Ó sì tún ti kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù Super story tí Wálé Adénúgà ṣe.
Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Rachael ti ní ọmọọmọ lẹ́hìn tí ọmọ bíbí inú rẹ̀ obìnrin náà ti di ìyá.[6]
Àwọn àṣàyàn eŕe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Sango (1997)
- Out of Bounds (1997)
- Owo Blow (1997)
- Passion of Mind (2004)
- Power Of Sin,
- Restless Mind
- Doctor Bello (2013)
- 30 Days in Atlanta (2014)
- [The Royal Hibiscus Hotel] (2017)
- Power of 1 (2018)
- The Wedding Party
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "My Late Husband Abandoned Me For Another WomanRachael Oniga Laments - nigeriafilms.com". nigeriafilms.com. Retrieved 20 January 2015.
- ↑ BOLDWIN ANUGWARA. "I’ll never marry except... – Rachael Oniga - Newswatch Times". Newswatch Times. Retrieved 20 January 2015.
- ↑ BOLDWIN ANUGWARA. "I’ll never marry except... – Rachael Oniga - Newswatch Times". Newswatch Times. Retrieved 20 January 2015.
- ↑ "I was a tomboy –Rachael Oniga". Daily Independent, Nigerian Newspaper. Retrieved 20 January 2015.
- ↑ "Africultures - Fiche film : Sango". africultures.com. Retrieved 20 January 2015.
- ↑ Dayo Showemimo. "Veteran actress, Rachael Oniga, becomes grandmother". Nigerian Entertainment Today. http://thenet.ng/2014/09/veteran-actress-rachael-oniga-becomes-grandmother/. Retrieved March 29, 2015.