The Antique (fíìmù)
| The Antique | |
|---|---|
| Adarí | Darasen Richards DJ Tee |
| Olùgbékalẹ̀ | Darasen Richards |
| Òǹkọ̀wé | Darasen Richards |
| Àwọn òṣèré |
|
| Orin | Cobhams Asuquo |
| Ìyàwòrán sinimá | DJ Tee |
| Olóòtú | Dipo Teniola DJ Tee Darasen Richards |
| Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Darasen Richards Films |
| Olùpín | Silverbird Film Distribution |
| Déètì àgbéjáde |
|
| Àkókò | 105 minutes |
| Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
| Èdè | English |
The Antique jẹ́ fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà ti ọdún 2014, Darasen Richards àti DJ Tee jẹ́ olùdarí rẹ̀. Lára àwọn gbajúmọ̀ òṣèré inú fíìmù yìí ni Olu Jacobs, Bimbo Akintola, Gabriel Afolayan, Ricardo Agbor, Seun Akindele àti Funsho Adeolu.[1][2][3]
Àhunpọ̀ ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fíìmù náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú agbègbè aláyọ̀ kan tí wọ́n ń gbádùn ara wọn nínú ìlú. Àmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan kan ṣẹlẹ̀, ní kété tí àwọn àjèjì ènìyàn mẹ́ta wọ inú ìlú náà láti wá ṣàwárí nǹkan àtijọ́ kan tó ní agbára láti ṣe ìdábóòbò àwọn ènìyàn inú ìlú yẹn. Wọ́n borí àwọn jagunjagun ìlú náà, àwọn àjèjì yìí sì gbé nǹkan àtijọ́ náà lọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì mú kí ègún wọ ilẹ̀ náà.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ọmọ kan ṣoṣo tí ọba bí wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, tó sì wá ní bèbè ikú. Babaláwo fi tó wọn létí pé àìsí nǹkan àtijọ́ náà ló fa àìsàn yẹn. Nítorí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ yan ọmọbìnrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Uki (Oge Indiana) láti lọ sínú igbó àwọn irúnmọlẹ̀, láti gba nǹkan àtijọ́ náà bọ̀,nítorí èyí ló le dẹ́kun ikú òjìji àti ìyàn tó ń mú ní ilẹ̀ náà.
Wọ́n sì tún yan àwọn jagunjagun mẹ́ta tó máa tẹ̀lé Uki títí tí wọ́n yóò fi rí nǹkan náà gbà padà. Ìrìn-àjò náà jọ èyí tí kò lè ṣe é ṣe nítorí wọ́n pàdé àwọn abàmì ẹ̀dá nínú igbó náà tó gbìyànjú láti dá wọ́n lọ́nà.
Àwọn akópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Olu Jacobs kópa gẹ́gẹ́ bíi Ọba Ekpen
- Bimbo Akintola kópa gẹ́gẹ́ bíi Queen 1
- Gabriel Afolayan kópa gẹ́gẹ́ bíi Uyi
- Ricardo Agbor bíi kópa gẹ́gẹ́ bíi Ọba Akugba
- Seun Akindele kópa gẹ́gẹ́ bíi Lead Invader
- Funso Adeolu kópa gẹ́gẹ́ bíi Enoma
- Oge Indiana kópa gẹ́gẹ́ bíi Ukinebo
- Kiki Omeili kópa gẹ́gẹ́ bíi Isoken
- Akpororo kópa gẹ́gẹ́ bíi Oriri
- Omowunmi Dada kópa gẹ́gẹ́ bíi Osas
- Theresa Edem kópa gẹ́gẹ́ bíi Princess
- Samuel Ajibola kópa gẹ́gẹ́ bíi Ọmọba
- Temitope Solaja[4]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Olu Jacobs, Bimbo Akintola, Gabriel Afolayon & More in 'The Antique' Watch Trailer". bellanaija.com. 10 October 2014. Retrieved 21 March 2015.
- ↑ "Epic movie, 'The Antique' to hit cinemas". The NET NG. Retrieved 21 March 2015.
- ↑ "WATCH THE TRAILER: "THE ANTIQUE" MOVIE STARRING OLU JACOBS, BIMBO AKINTOLA, KIKI OMEILI & AKPORORO". Modern Ghana. Retrieved 21 March 2015.
- ↑ Lala, Emmanuel (2014-03-28). "Olu Jacobs, Bimbo Akintola, Funsho Adeolu & Rykardo Agbor Play Royal Family In New Movie Titled “The Antique” | Photos". 36ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2026-02-14. Retrieved 2025-06-28.