Ugali ní South Africa
Ugali ní orílẹ̀-èdè South Africa
Pap, /ˈpʌp/, èyí tí à tún mọ̀ sí mieliepap (Afrikaans fún àgbàdo) ní orílẹ̀-èdè South Africa, jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ àsáró/polenta àti pé ó jẹ́ oúnjẹ tí ó yára láti sè fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà pàápàá jùlọ àwọn tí wọ́n ń bẹ ní apá gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà (a mú orúkọ yìí láti inú èdè Dutch èyí tí ó túmọ̀ sí "àsáró") èyí tí a ṣe láti ara àgbàdo (èyí tí a lọ̀). Onírúurú ẹ̀yà oúnjẹ yìí ni a lè rí ní orílẹ̀-èdè South Africa [1]). A sáábà máa rí Phuthu ní àwọn apá etíkun orílẹ̀-èdè South Africa.[2]
Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa tí wọ́n ń bẹ ní apá àríwá orílẹ̀èdè South Africa máa ń jẹ ẹ́ gẹ́gẹ́ bíi oúnjẹ òwúrọ̀, pẹ̀lú mílìkì, bọ́tà, àti súgà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú ọbẹ̀ ẹran àti ọbẹ̀ tòmátò (ó sáábà máa ń jẹ́ tòmátò àti àlùbọ́sà). Nígbà tí wọ́n bá ní braai, Bogobe tàbí "Stywe" (ẹ̀kọ́) pẹ̀lú onírúurú ọbẹ̀ bíi tòmátò àti àlùbọ́sà tàbí mushroom jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì nínú jíjẹ oúnjẹ yìí. Ẹ̀kọ phutu jẹ́ ohun tí wọ́n sáábà máa ń jẹ pẹ̀lú boerewors, èyí tí ó padà di pap en wors (tí wọ́n tún ń pè ní "pap en vleis", èyí tí ó le kó ọbẹ̀ ẹran sínú).[3]
Ní Cape Province ti orílẹ̀-èdè South Africa, wọ́n ka oúnjẹ yìí sí oúnjẹ òwúrọ̀.Nígbà tí mielie-meal kò ti wọ́n, àwọn tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ lówó máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú ẹ̀fọ́. A le jẹ ẹ́ ni gbígbóná tàbí lẹ́yìn tí ó bá tutù, bẹ́ẹ̀ ni a le dín in pẹ̀lú. Àsâró phutu nígbà mìíràn jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń jẹ pẹ̀lú chakalaka àti braais.[4]
Ní ẹkùn àríwá oúnjẹ yìí jẹ́ èyí tí ó sáábà máa ń rọ̀ dáadáa, wọ́n máa ń lo àgbàdo rírẹ èyí tí kìí jẹ́ kí oúnjẹ náà ó tètè bàjẹ́ nítorí pé ẹkùn àríwá gbóná ju ẹkùn gúúsù lọ.
Uphuthu jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ará South Africa máa ń gbà se mealie níbi tí èsì tí ó máa fún wa ti máa jẹ́ èyí tí ó dùn tí a le jẹ pẹ̀lú ẹ̀fọ́ àti ẹran ní Kwa Zulu Natal àti ní ẹkùn ìlà-oòrùn Cape ti orílẹ̀-èdè South Africa tàbí gẹ́gẹ́ bíi ìràwọ̀ oúnjẹ pẹ̀lú amasi tàbí Maas ní ẹkùn Gauteng. Àwọn àṣà kan máa ń fi ṣúgà sí uphuthu àti amasi láti le jẹ ìgbádùn oúnjẹ náà.
Phuthu tàbí Uphuthu ( /ˈpʊtuː/), tí àṣìpé rẹ̀ ń jẹ́ putu tàbí phutu, jẹ́ ìlànà ìbílẹ̀ láti pèsè oúnjẹ àgbàdo nínú àwọn oúnjẹ ilẹ̀ South Africa. Wọ́n máa ń jẹ phuthu pẹ̀lú ẹran, ẹ̀wà, gravy, àti amasi.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Putu pap / Krummelpap / Crumbly porridge | Rainbow Cooking".
- ↑ "Phutu Recipe (African Maize Flour Porridge)". EpersianFood (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-04-07. Archived from the original on 2021-05-12. Retrieved 2020-05-29.
- ↑ "TINK". frankline-ozekhome.squarespace.com. Archived from the original on 2021-02-06. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Rosengarten, David (2012-10-03). "Foods of South Africa: The Roots". Wine4Food (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-29.