Wikipedia:Àyọkà ọṣẹ̀ 52 ọdún 2010

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Africa (orthographic projection).svg

Áfríkà ni orile keji titobijulo ati toni awon eniyan julo lagbaye leyin Asia. Ni bi 30.2 egbegberun km² (11.7 million sq mi) lapapo mo awon erekusu to sunmo, ile re je 6% apapo gbogbo oju Aye ati 20.4% gbogbo ile Aye. Pelu egbegberunkeji kan eniyan (ni 2009, e wo tabili) ni awon agbegbe 61, eyi je bi 14.72% gbogbo iye eniyan Agbaye. Ni ariwa re ni Okun Mediterraneani wa, si ariwailaorun re ni Ilaodo Suez ati Okun Pupa wa legbe Sinai Peninsula, si guusuilaorun re ni Okun India, ati si iwoorun re ni Okun Atlantiki wa. Afrika ni orile-ede 54 lapapo mo Madagascar, opolopo erekusu ati orile-ede Olominira Sahrawi Arabu Toseluaralu, to je omo egbe Isokan Afrika botilejepe Morocco lodi si eyi.

Afrika, agaga gbongan apailaorun Afrika, je gbigba lopolopo latowo awon awujo onisayensi pe ibe ni ibi ti awon eniyan ti bere ati Hominidae clade (great apes), gege bi o se han pelu iwari awon hominids pipejulo ati awon babanla won, ati awon ti won wa leyin won ti won peju bi odun legbegberun meje seyin – lapapomo Sahelanthropus tchadensis, Australopithecus africanus, A. afarensis, Homo erectus, H. habilis and H. ergaster – pelu eyi to pejulo ninu won Homo sapiens (eniyan odeoni) ti o je wiwari ni Ethiopia to je odun bi 200,000 seyin.

Afrika bo ibiagedemeji mole, o si ni orisirisi awon agbegbe ojuojo; o je orile kan soso to gun lati agbegbe apaariwa aloworo de apaguusu alaworo.

Afri ni oruko awon eniyan ti won gbe ni Ariwa Afrika leba Carthage. Oruko awon wonyi je siso mo "afar" ti awon Finiki, to tumosi "eruku", sugbon ero 1981 kan ti so pe o wa lati oro ede Berber ifri tabi Ifran totumosi "iho", ni tokasi awon ti ungbe inuiho ni oruko Banu Ifran lati Algeria ati Tripolitania (Eya Berber ti Yafran).

Labe ijoba awon Ara Romu, Carthage di oluilu Igberiko Afrika, to tun je kikomo apa eba odo Libya oni. "-ka" ("ca") to je ilemeyin Afrika je awon Ara Romu to tokasi "orile-ede tabi ile". Bakanna, ile-oba Musulumi ayeijoun Ifriqiya to wa leyin, ti a mo loni bi Tunisia, na tun lo iru oruko yi. (ìyókù...)