Àṣà Yorùbá
Àṣà Yorùbá jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ẹ̀yà Yorùbá ń lò láti fi gbé èrò, ìmọ̀, àti ìṣe wọn kalẹ̀ tí ó sì bá àwùjọ wọn mú ní ọ́nà tí ó gun gẹ́gẹ́. Tàbí kí á sọ wípé Àṣà ni ohun gbogbo tó jẹ mọ́ ìgbé ayé àwọn ènìyàn kan, ní àdúgbò kan, bẹ̀rẹ̀ lórí èrò, èdè, ẹ̀sìn, ètò ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé, ìsẹ̀dá ohun èlò, ìtàn, òfin, ìṣe, ìrísí, ìhùwàsí, iṣẹ́-ọnà, oúnjẹ, ọ̀nà ìṣe nǹkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò kọ̀ọ̀kan padà. Pàtàkì jùlọ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, eré ìbílẹ̀, àti iṣẹ́ ìbílẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n kó ara jọ pọ̀ tí wọ́n ń jẹ́ àṣà. [1] Bí a bá sọ̀rọ̀ nípa àṣà àti ìṣe Yorùbá, nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ lórí nǹkan kan, àwọn ohun tí à ń mú enu bà ni ìhùwàsí àti ìrísí wa láàrín àwùjọ. Nínú ogún-lọ́gọ̀ àwọn àṣà àti ìṣe tí ó ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá, ọ̀kan pàtàkì ni' Àṣà ìkíní nílẹ̀ Yorùbá. Èyí jẹ́ ohun tí gbogbo àwọn ẹ̀yà tí ó kú ní agbáyé fi máa ń ṣàdáyanrí ọmọ káàrọ̀-oò-jíire bí tòótọ́ ní gbogbo ayé tí wọ́n bá dé[2]
Ẹ jẹ́ kí a jọ gbé e yèwò, kí a jọ yàn-nà-ná rẹ̀. Ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, àkọ́kọ́ ni:
Àṣà ìkíni nílẹ̀ Yorùbá
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àṣà ìkíni jẹ́ àṣà tí ó gbajúgbajà nílẹ̀ Yorùbá, àṣà yìí sì ní í ṣe pẹ̀lú ìgbà àti àkókò. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ohun tí ó ń sẹlẹ̀ ní déédé àsìkò náà. Bí Yorùbá bá jí láàárọ̀, ọmọdé tí ó bá jẹ́ ọkùnrin, yóò wà lórí ìdọ̀bálẹ̀, nígbà tí èyí tí ó bá jẹ́ obìnrin yóò wà lórí ìkúnlẹ̀, wọn a sì kí àwọn òbí wọn tàbí ẹni tí ó bá ti jùwọ́n lọ ní gbogbo ọ̀nà, wọn á máa wípé:
"Ẹ kú àárọ̀ tàbí Ẹkáàárọ̀,
ẹni tí wọ́n ń kí náà á sì dá wọn lóhùn wí pé:
Káàárọ̀ ọmọ mí, ṣé dáadáa ni o jí? tàbí aàjíırebí?"
Bí ó bá jẹ́ ọ̀sán, wọn á ṣe bákan náà, wọn á sọ wí pé:
"Ẹ kú ọ̀sán tàbí Ẹkásàn-án"
ẹni tí wọ́n ń kí náà á sì dá wọn lóhùn wí pé:
"Kú òsán tàbí Kásàn-án" bí ó bá jẹ́ ìgbà iṣé,
"Ẹ kú iṣẹ́" ni à ń kí'ni.
Bí ó sì jẹ́ àṣálẹ́,
"Ẹ kú alẹ́ tàbí Ẹkáalẹ́" ni à ń kí'ni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Nílẹ̀ Yorùbá, gbogbo àsìkò ni ó ní ìkíni tirẹ̀, ṣùgbọ́n ọmọdé ni ó kọ́kọ́ máa ń kí àgbà. Èyí tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ Yorùbá ní wí pé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò ní ẹ̀kọ́ tàbí, wọ́n kọ́ ọ ní'lé, kò gbà ni. Bí ó bá jẹ́ ìgbà ayẹ̣yẹ bíi ìsìnkú àgbà, nítorí Yorùbá kì í ṣe òkú ọ̀dọ́, ẹhìnkùnlé ni wọ́n máa ń sin òkú ọ̀dọ́ sí. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé, òfò ni ó jẹ́ fún àwọn òbí irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wàyí, bí ó bá jẹ́ òkú àgbà, wọn á ní, "Ẹ kú ọ̀fọ̀, ẹ kú ìsìnkú, Olórun yóò mú ọjọ́ jìnnà sí ara o." Bí ó bá jẹ́ ayẹyẹ Ìkómojáde/Ìsọmọlórúkọ, wọn á ní, "Ẹ kú ọwọ́lómi o", "Ẹ kú ayẹyẹ ìkọ́mọjáde." Bákan náà, oríṣiríṣì àkókò ni ó wà nínú odún. Àkókó òfìnikìn, Àkókò ọyẹ́, Àkókò oòrùn (Summer), Àkókò òjò, gbogbo wọ̀nyí sì ni àwọn Yorùbá ní bí a ṣe ń kí'ni fún. Ẹ jẹ́ kí á gbẹ́ àṣà ìsìnkú yẹ̀wò.
Àṣà ìsìnkú nílẹ̀ Yorùbá
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú wípé ó ní àwọn òkú tí Yorùbá máa ń ṣe ayẹyẹ fún, àwọn bíi òkú àgbà, nítorí wọ́n gbà wí pé, olóògbé lọ sinmi ni, àti wí pé, wọ́n lọ'lé. Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé, ọjà ni ayé, gbogbo wa wá ná ọjà láyé ni, ṣùgbọ́n ọ̀run ni ilé, gbogbo wa ni a ó padà lọ sí ilé lọ rè é jábọ́ gbogbo iṣẹ́ tí a gbé ilé ayé ṣe.
Bí ó bá jẹ́ òkú ọ̀dọ́ tàbí ọmọdé, òkú ọ̀fọ̀ àti ìbànújẹ́ ló jẹ́. Wọ́n á gbà wí pé, àsìkò rẹ̀ kò tíì tó. Àwọn Yorùbá máa ń ná owó àti ara sí ìsìnkú àgbà, pàápàá bí olóògbé náà bá jẹ́ ẹni tí ó ní ipò àti ọlá nígbà tí ó wà láyé, tí ó sì tún bí ọmọ. Ìsìnkú àwọn wọ̀nyí máa ń lárinrin.
Ní ayé àtijọ́, bí aláwo bá kú, àwọn àwọn Olúwo ní ń sìnkú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wọn á pa adìyẹ ìrànà, wọn á sì máa tu ìyẹ́ rẹ bí wọ́n ṣe ń gbé òkú rẹ̀ lọ. Lẹ́yìn tí wọn bá sin òkú tán, àwọn aláwo náà á sun adìye náà jẹ. Ìdí rèé tí àwọn Yorùbá fi máa ń sọ wí pè, "Adìyẹ ìrànà kì í ṣ'ọhun à jẹ gbé." Nítorí pé, kò sí ẹni tí kò ní kú.
Ọ̀fọ̀ ni ó máa ń jẹ́ tí ìyàwó ilé bá sáájú ọkọ rẹ̀ kú. Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé, ọkọ ló máa ń sáájú aya rẹ̀ kú, kí ìyàwó máa bójú tó àwọn ọmọ. Fún ìdí èyí, bí ọkùnrin bá kú, àwọn ìyàwó irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ṣe opó pẹ̀lú ìlànà àti àṣà Yorùbá. Ogójì ọjọ́ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n máa ń fi ṣe opó. Lẹ́yìn ìsìnkú, àwọn àgbà ilé ni wọ́n máa pín ogún olóògbé fún àwọn ọmọ rẹ̀, bí ó bá jẹ́ òkú ọlọ́mọ. Àmọ́ tí kò bá bí’mọ, àwọn ẹbí rẹ̀, ní pátàkì jùlọ, àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ tí ó jù ú lọ ní wọ́n máa pín ogún náà láàárín ara wọn. Ó tún jẹ́ àṣà Yorùbá òmíì kí wọn máa ṣú opó olóògbé fún àwọn àbúrò rẹ̀, láti fi ṣe aya. Ohun tí ó jẹ́ orírun àṣà ni ‘àrà’, ó lè dára tàbí kí ó burú.
Àwọn ohun tí ó kórá jọ di àṣà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àṣà jẹ mọ́ ìgbàgbọ́, bí àpẹẹrẹ; Olódùmarè, àbíkú, àkúdàáyà, iṣẹ́-ọnà tí a lè fojú rí tàbí fẹnu sọ.
Ìsọ̀rí Àṣà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A lè pín àṣà sí ìsọ̀rí mẹ́ta, èyí tí ó jẹ mọ́:
(a) Ọgbọ́n ìmọ̀, ète, tàbí ètò tí à ń gbà ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ:
- ilà kíkọ,
- irun dídì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
(b) Iṣẹ́-ọnà. Àpẹẹrẹ:
- Igi gbígbẹ́,
- Igbá fínfín
- Ilé kíkọ́
- Ẹní híhun
- Ara dídá /fínfín àti bẹ̀ẹ́ bẹ̀ẹ́ lọ.
(d) Bí a ṣe ń darí ìhùwàsí àwọn ẹgbẹ́ tàbí ẹ̀yà kan.
Àbùdá Àṣà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lára àbùdá àṣà ni pé:
(a) Kò lè è súyọ láìsí ènìyàn, ìdí ni wípé ẹ̀mí àṣà gùn ju ti ènìyàn lọ.
(b) Ó jẹ mọ́ ohun tí a lè fojú rí;
(d) Àṣà kọ̀ọ̀kan ló ní ìdí kan pàtó.
Àlàyé nípa Àṣà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀](a) Àṣà lè jẹyọ nínú oúnjẹ: Òkèlè wọ́pọ̀ nínú oúnjẹ wa. Àkókó kúndùn ẹ̀bà, Ìlàjẹ fẹ́ràn púpurú,Igbó ọrà kìí sì í fi láfún òṣèré.
(b) Àṣà lè jẹyọ nínú ìtọ́jú oyún, aláìsà,òkú; ètò ẹbí, àjọṣepọ̀; ètò ìṣàkóso àdúgbò, abúlé tàbí ara dídá nípa iṣẹ́-ọnà.
Aáyẹ tí ó de bá àṣà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí:
(a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́.
(b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́.
(d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́.
(e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́.
(ẹ) A kò fi èdè abínibí wa kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́.
Àwọn ọ̀nà tí àṣà máa ń gbà yípadà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀](a) Bí àṣà tó wà nílẹ̀ bá lágbára ju èyí tó jẹ́ tuntun lọ, èyí tó wà tẹ́lẹ̀ yóò borí tuntun. Bí àpẹẹrẹ, aṣọ wíwọ̀.
(b) Àyípadà lè wáyé bí àṣà tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ bá dógba pẹ̀lú àṣà tuntun, wọ́n lè jọ rìn pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àṣà ìgbéyàwó.
(d) Bí àṣà tuntun bá lágbára ju èyí tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, yóò sọ àṣà ti àtẹ̀hìnwá di ohun ìgbàgbé. Bí àpẹẹrẹ, bí a ṣe ń kọ́'lé.
Tí a bá wá wò ó fínnífínní, à á ri wí pé, àṣà, lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà máa ń dá lé:
(a) Ìmọ̀ ìṣe sáyẹ́ǹsì
(b) Ìṣe jẹun wa
(d) Ìsọwọ́ kọ́lé
(e) Iṣẹ́ ọwọ́ ní síṣe
ÀKÍYÈSI:
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Èdè àwọn ènìyàn jẹ́ kókó kan pàtàkì nínú àṣà wọn. Kò sí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò nínú àṣà àti èdè. Ìbejì ni wọ́n. Ọjọ́ kan náà ni wọ́n délé ayé nítorí pé kò sí ohun tí a fẹ́ sọ nípa àṣà, tí kì í ṣe pé èdè ni a ó fi gbé e kalẹ̀. Láti ara èdè pàápàá ni a ti lè fa àṣà yọ. A lè fi èdè Yorùbá sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni, a lè fi kọrin, a lè fi kéwì, a lè fi jọ́sìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láti ara àwọn nǹkan tí à ń sọ jáde lẹ́nu wọ̀nyí ni àṣà wa ti ń jẹyọ. Ara èdè Yorùbá náà ni òwe àti àwọn àkànlò-èdè gbogbo wà. A lè fa púpọ̀ nínú àwọn àṣà wa yọ láti ara òwe àti àkànlò èdè.
Nítorí náà, èdè ni ó jẹ́ òpómúléró fún àṣà Yorùbá. Àti wí pé, òun ni ó fà á tí ó fi jẹ́ pé, bí àwọn ọmọ Odùduwà ṣe tàn kálẹ̀, orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n, èdè kan náà ni wọ́n ń sọ níbikíbi tí wọ́n lè wà. Ìṣesí, ìhùwàsí, àṣà àti ẹ̀sìn wọn kò yàtọ̀. Fún ìdí èyí, láìsí ènìyàn, kò le è sí àṣà rárá.àsà jẹ́ nnkan gbòógì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ṣùgbọ́n àwọn yorùbá mu ní ọ̀kúnkúndùn kí gbogbo wa sì gbe lárugẹ
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Yoruba - people". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2020-01-05.
- ↑ "Yoruba - Introduction, Location, Language, Folklore, Religion, Major holidays, Rites of passage". World Culture Encyclopedia. 2007-04-03. Retrieved 2020-01-05.
1. Adeoye C.L. (1979) Àṣà àti iṣe Yorùbá Oxford University Press Limited
2. J.A. Atanda (1980) An introduction to Yoruba History Ibadan University Press Limited
3. Adeomola Fasiku (1995) Igbajo and its People Printed by Writers Press Limited
4. G.O. Olusanya (1983) Studies in Yorùbá History and Culture Ibadan University Press Limited.
5. Rev. Samuel Johnson (1921) The History of the Yorubas A divisional of CSS Limited.