Ìpínlẹ̀ Plateau
Ìpínlẹ̀ Plateau jẹ́ Ìpínlẹ̀ ìkejìlá tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó tòní jùlọ. Ìpínlẹ̀ yí wà ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí àwọn òkè àpáta orísiríṣi sì yi ka, pàá pàá jùlọ ìlú Jos tí ó jẹ́ olú ìlú fún Ìpínlẹ̀ náà. [5] Ìnagijẹ tí wọ́n ń pe Ìpínlẹ̀ yí ni Ilé Àlááfíà àti abẹ̀wò, ìdí ni wípé Ìpínlẹ̀ náà kún fún orísiríṣi ohun mère-mère tí ó ń wu ojú rí bíi iṣàn omi, àpáta láriṣiríṣi, òkè ńlá-ńlá ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Iye àwọn olùgbé ibẹ̀ jẹ́ mílíọ́nù mẹ́ta àti abọ̀. [6]
Ìrísí Ìpínlẹ̀ náà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn Ìpínlẹ̀ tí wọ́n múlé tìí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Bauchi State – ní apá ìlà Oòrùn gúsù
- Kaduna State – ní apá ìwọ̀ Oòrùn gúsù
- Nasarawa State – ní apá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà
- Taraba State – ní apá ìlà Oòrùn ilé Nàìjíríà
Àwọn Ẹnu Ààlà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìpínlẹ̀ Plateau wà ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ òkè ọya, ó sì jẹ́ ìkan lára àwọn ẹkùn mẹ́fà tí wọ́n pín ilẹ̀ Hausa sí. [7] Tí sare ilẹ̀ wọn sì tó 26,899 iye ìwọ̀n bí Ìpínlẹ̀ náà fi gùn ní òró tó 08°24'N and longitude 008°32' and 010°38' east.[8] Wọ́n sọ Ìpínlẹ̀ yí ní orúkọ rẹ̀ Jos Plateau tí ó jẹ́ agbègbè kan tí òkè pọ̀ sí jùlọ ní Ìpínlẹ̀ náà.[9] òkúta ati àpáta oríṣiríṣi ni wọ́n pọ̀ jàntìrẹrẹ ní àárín igbó àti ijù.
Ojú ọjọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Ìpínlẹ̀ Jos wà ní àárín gbùngbùn òkè ọya, síbẹ̀ ojú ọjọ́ ibẹ̀ fanimọ́ra látàrí bí Oòrùn ríràn kò ṣe kí ń ju ìdá mẹ́tàlá sí ìdá méjìlélógún (13 - 22 °C) lọ. Bí ọyẹ́ bá mú ní àsìkò oṣù Kejìlá sí oṣù kejì ọdún, ojú ọjọ́ wọn yóò tutù mìnìjọ̀. Pẹ̀lú bí oru ṣe ma ń mú lásìkò ọ̀gbẹlẹ̀, Ìpínlẹ̀ Jos ma ń tutù ní tìrẹ̀ ni. Rírọ̀ òjò ní Ìpínlẹ̀ yí ma ń le ju ara wọn lọ ju ti bí a ṣe ri nínú àtẹ yí 131.75 cm (52 in) apá àríwá 146 cm (57 in) Ìpínlẹ̀ plateau, bí ó ṣe jẹ́ wípé ọwọ́ òjò ma ń le níagbègbè yí làsìkò òjò. Bí ojú ọjọ́ ìpínlẹ̀ yí ti rí ni ó jẹ́ kí àdínkù bá àwọn oríṣiríṣi àjakálẹ̀ àrùn ní ìpínlẹ̀ náà yàtọ̀ sí bí a ti ń ri ní àwọn ìpínlẹ̀ tí ó múlé tì wọ́n. Ìpínlẹ̀ Jos tún jẹ́ orísun iṣàn [[omi] fún àwọn odò ìpínlẹ̀ tí ó múlé tiwaọ́n bíi: Kaduna, Gongola, Hadeja àti odò Damaturu rivers. lásìkò ọ̀gbẹlẹ̀.
Jiọ́lọ́jì
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìpínlẹ̀ Plateau jẹ́ ibi tí oríṣiríṣi òkúta pọ̀ sí, pàá pàá jùlọ àwọn àfọ́kù àpáta tí wọ́n gbọ̀n sílẹ̀. Àwọn òkúta tí a ti mẹ́nu bá yí yóò tó mílíọ́nù lónà 160 níye, èyí sì mú kí Ìpínlẹ̀ Plateau ó yàtọ̀ ní ìrísí. Bákan náà ni àwọn òkè òun pẹ̀tẹ́lẹ̀ pọ̀ níbẹ̀ látàrí bí òkè ṣe pọ̀ sí. Ẹ̀wẹ̀, ìsẹ̀lẹ̀ ìrúsókè iná láti inú àpáta (volcano) mú kí orísiríṣi ohun àlùmọ́nì [10] pọ̀ níbẹ̀ ju àwọn Ìpínlẹ̀ tó kú ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ. [11]
Àwọn itọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "2006 PHC Priority Tables – NATIONAL POPULATION COMMISSION". population.gov.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2017-10-10. Retrieved 2017-10-10. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ See List of Governors of Plateau State for a list of prior governors
- ↑ 3.0 3.1 "C-GIDD (Canback Global Income Distribution Database)". Canback Dangel. Retrieved 2008-08-20.
- ↑ "Sub-national HDI - Area Database - Global Data Lab". hdi.globaldatalab.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-09-13.
- ↑ "Nigeria | Culture, History, & People". Encyclopedia Britannica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-28.
- ↑ Ibrahim, Abubakar (28 February 2022). "Add citation".
- ↑ "Geopolitical zones in Nigeria and their states". 20 March 2017.
- ↑ "Plateau | state, Nigeria | Britannica". www.britannica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-04.
- ↑ Online, Tribune (2017-10-10). "SHERE HILLS: Amazing hills and rock formations". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-04.
- ↑ "Exploring the resource control option - Plateau State, by Futureview CEO, Elizabeth Ebi". Vanguard News. 2014-12-30. Retrieved 2022-11-13.
- ↑ Hodder, B. W. (1959). "Tin Mining on the Jos Plateau of Nigeria". Economic Geography 35 (2): 109–122. doi:10.2307/142394. ISSN 0013-0095. JSTOR 142394.