Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Rùwándà
Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Rùwándà | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Rwanda |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, China |
Index case | Kigali |
Arrival date | 14 March 2020 (4 years, 7 months, 1 week and 3 days) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 2,092 (as of 3 August)[1] |
Active cases | 918 (as of 3 August) |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 1,169 (as of 3 August) |
Iye àwọn aláìsí | 5 (as of 3 August) |
Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ni wọ́n fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ó dé orílẹ̀-èdè Rùwándà ní oṣù kẹta ọdún 2020.
Bí àrùn COVID-19 ṣe bẹ̀rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kini ọdún 2020, àjọ elétò ìlera àgbáyé (World Health Organization) jẹ́rìsí i pé kòkòrò àrùn ẹ̀rànkòróná ni ó fa àrùn atẹ́gùn ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìlú Wuhan ní agbègbè Hube, orílẹ̀-èdè China, èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ fún àjọ elétò ìlera àgbáyé ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2019.[2]
Ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn COVID-19 kéré púpọ̀ sí ti SARS tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2003,[3][4]ṣùgbọ́n bí àrùn COVID-19 ṣe ń tàn kaakiri pọ̀ púpọ̀ ní pàtàkì tí a bá wo iye àwọn tí ó ti jẹ́ aláìsí.[5]
Àwọn àkókò tí àrùn COVID-19 ń ṣẹ́yọ.
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oṣù Kẹta Ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àkọ́kọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn COVID-19 ní orílẹ̀-èdè Rwanda ni wọ́n fìdí ẹ múlẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹta ọdún 2020.[6] Lẹ́hìn ìṣẹ̀lẹ̀ ti àkọ́kọ́, àwọn ènìyàn mẹ́rin míràn àn ni àyẹ̀wò fi hàn pé wọ́n ní àrùn COVID-19, èyí ló mú kí ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn yí di márùn ún.[7]
Ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹta, orílẹ̀-èdè Rwanda fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ méjì míràn àn múlẹ̀ ní Kigali, èyí tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn yí di méje ní orílẹ̀-èdè yí.[8] Nínú ìgbìyànjú láti dáwọ́ títànkálẹ̀ àrùn ẹ̀rànkòrónà yí dúró, ilé-iṣẹ́ ti ìlera ní orílẹ̀-èdè Rwanda kéde ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta, láti orí ẹ̀rọ ayélujára ti Twitter pé gbogbo àwọn ọkọ̀ òfurufú akérò ni wọn yíò dádúró fún ọgbọ̀n ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ láti ogúnjọ́ oṣù kẹta.[9] Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹta ni wọ́n kéde ìsénimọ́lé olósẹ̀-méjì. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti àwọn ti aládàáni ni wọ́n sọ fún wípé kí wọ́n má a ṣe iṣẹ́ wọn láti ilé lábé àwọn ìgbésẹ̀ tó múnádóko. Gbogbo àwọn ẹnuibodè ni wọ́n tún má a di títìpa, ṣùgbọ́n wọ́n dá àwọn ọkọ̀ akẹ́rù sílẹ̀ àti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Rwanda tí wọ́n ń wọlé bọ̀ ṣùgbọ́n ó kan dandan fún wọn láti kọ́kọ́ lọ sí ibi ìfinipamọ́ ọlọ́jọ́-mẹ́rìnlá.
Ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ilé-iṣẹ́ ti ìlera ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun ti COVID-19 mẹ́fà míràn, èyí tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn tí àyẹ̀wò jẹ́rìsí pé wọ́n ní àrùn firọsi yí di ọgọ́ta.[10]
Ní òpin oṣù kẹta, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn kòrónà márùndínlọ́gọ́rin ni wọ́n fìdí ẹ múlẹ̀. Kò sí aláìsàn tí ó kú, bẹ́ ẹ̀ sì ni kò sí aláìsàn tí ó rí ìwòsàn gbà.
Oṣù Kẹrin Ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kẹsàn án oṣù kẹrin, wọ́n ṣe àwárí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun mẹ́ta ti ẹ̀rànkòróná nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti ogún(720) àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò fún ní wákàtí mẹ́rìnlélógún sẹ́yìn. Èyí mú kí àpapọ̀ iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fìdí ẹ múlẹ̀ pé wọ́n ní àrùn kòróná di mẹ́tàléláàdọ́fà(113) àwọn ènìyàn (nínú èyí tí àwọn méje ti gba ìwòsàn).
Ní oṣù kẹrin, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun méjìdínláàdọ́sàn án(168) ni ó ṣẹlẹ̀, èyí tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn kòrónà tí ó ti ń ṣẹlẹ̀ di òjìlénígba lé mẹta(243). Mẹ́rìnlélọ́gọ́rùn ún(104) àwọn aláìsàn ni wọ́n ti gba ìwòsàn, tí àwọn aláìsàn mọ́kàndínlógóje(139) ṣi n gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ní òpin oṣù kẹrin.
Oṣù Kárùn ún Ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù karùn ún, wọ́n fìdí ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ jẹ́ aláìsì múlẹ̀ ní orìlẹ̀-èdè Rwanda.[11] Iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fìdí ẹ̀ múlẹ̀ jẹ́ 370 (èyí tí ó fi ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́tàdínláàdóje(127) lọ sókè láti òpin oṣù kẹrin.). Iye àwọn aláìsàn tí wọ́n ti gba ìwòsàn lọ sókè láti méjìléláàdọ́jọ(152) sí ọ̀tàlénígba dín mẹ́rin(256) tí ó wá ṣẹ́ku àwọn aláìsàn mẹ́tàléláàdọ́fà(113) tí wọ́n ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.
Oṣù Kẹfà Ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ní agbègbè Rusizi (Rusizi District) ní apá ìwọ-òòrùn Rùwándà, tí í ṣe ààlà ilẹ̀ olómìnira ti orílẹ̀-èdè Congo (Orílẹ̀-èdè Olómìnira Òṣèlú ilẹ̀ Kóngò) ló fà á tí iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fìdí ẹ̀ múlẹ̀ fi lọ sókè. Eléyì í, pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ díẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ní Rusumo tí í ṣe ààlá ìla-òòrùn pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Tanzania, ló mú kí iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fìdí ẹ̀ múlẹ̀ lọ sókè láti 370 ní òpin oṣù kárùn ún sí 572 ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹfà.[12]
Ní oṣù kẹfà, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun 655 ni ó ṣẹlẹ̀, èyí tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti ṣẹlẹ̀ di 1,025. Iye àwọn tí ó ti kú di méjì. Iye àwọn aláìsàn tí wọ́n ti gba ìwòsàn lọ sókè láti mọ́kànléláàdọ́wàá(191) sí 447, tí ó sì wá ṣẹ́ku àwọn aláìsàn 576 tí wọ́n ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ní òpin oṣù kẹfà.
Oṣù Keje Ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lára àwọn Ìpínlẹ̀ tí ó wà ní ìha-Sàhárà ti orílẹ̀-èdè Rwanda nìkan ni wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ rẹ pé àwọn ará ìlú Rwanda àti àwọn olùgbé ìlú Rwanda lé è rìn ìrìn-àjò lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n parapọ̀ jẹ́ ìdàpọ̀ Yuroopu (European Union) láti oṣù keje.[13]
Ní oṣù kẹfa, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ 997 ni ó ṣẹlẹ̀, èyí tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti ṣẹlẹ̀ di 2022. Iye àwọn tí ó ti kú lọ sókè sí márùn ún. Iye àwọn aláìsàn tí wọ́n ti gba ìwòsàn fi 659 lọ sókè si i títí dé 1106, ó wá ṣẹ́ku àwọn aláìsàn 911 tí wọn ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ní òpin oṣù keje (èyí lọ sókè pẹ̀lú ìdá méjìdínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn ún, 58% láti òpin oṣù kẹfà.)
Ìgbésẹ̀ Ìjọba
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní àfikún sí àwọn ìgbésẹ̀ ìsénimọ́lé tí ìjọba gbé ní oṣù kẹta, àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Rwanda kéde lílo àwọn ọkọ̀ òfurufú gẹ́gẹ́ bí i àwọn ohun èlò láti fi ìfiránṣẹ́ ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn agbègbè lórí àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà láti dẹ́kun àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀rànkòrónà.[14]
-
Ọmọdékùnrin kan tí ó wọ ìbòmú ní abúlé kan ní ìla-òòrùn (Àdàkọ:Ọjọ́).
Awon Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Rwanda Coronavirus - Worldometer". www.worldometers.info (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-08-03.
- ↑ Reynolds, Matt; Weiss, Sabrina (2020-02-24). "How coronavirus started and what happens next, explained". WIRED UK. Retrieved 2020-08-15.
- ↑ "Crunching the numbers for coronavirus - Imperial College London". Imperial News. 2020-03-13. Retrieved 2020-08-15.
- ↑ "High consequence infectious diseases (HCID)". GOV.UK. 2018-10-22. Retrieved 2020-08-15.
- ↑ Higgins, Annabel (2020-08-15). "Coronavirus". World Federation Of Societies of Anaesthesiologists. Archived from the original on 2020-03-12. Retrieved 2020-08-15.
- ↑ Uwiringiyimana, Clement (2020-03-14). "Rwanda confirms first case of coronavirus - health ministry". U.S. Retrieved 2020-08-15.
- ↑ "Coronavirus: Mu Rwanda abandi bantu bane bashya bayibasanzemo". BBC News Gahuza (in Èdè Ruwanda). 2020-03-16. Retrieved 2020-08-15.
- ↑ "Rwanda confirms seventh coronavirus case". The East African. 2020-03-17. Retrieved 2020-08-15.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Mbabazi, Eunniah; \ (2020-03-19). "Rwanda Suspends All International Flights". Kenyan Wallstreet. Retrieved 2020-08-15.
- ↑ "Rwanda COVID-19 cases increase to 60; all patients recovering well". The New Times | Rwanda. 2020-03-28. Retrieved 2020-08-15.
- ↑ Editorial, Reuters (2020-05-31). "Rwanda reports its first death from the new coronavirus". U.S. (in Èdè Ruwanda). Retrieved 2020-08-15.
- ↑ Xinhua (2020-06-15). "Cluster of Covid-19 cases in western Rwanda continue to cause new infections". IOL. Retrieved 2020-08-15.
- ↑ "Rwanda’s Covid-19 response: A great indicator of a strong state". The New Times | Rwanda. 2020-07-06. Retrieved 2020-08-15.
- ↑ "Rwanda deploys drones to raise Covid-19 awareness in communities". The New Times | Rwanda. 2020-04-12. Retrieved 2020-08-15.
- CS1 Èdè Gẹ̀ẹ́sì-language sources (en)
- CS1 Èdè Ruwanda-language sources (rw)
- All articles with dead external links
- Articles with dead external links from October 2023
- Articles with invalid date parameter in template
- Articles with permanently dead external links
- Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè
- Rùwándà