Jump to content

Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Zimbabwe

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Zimbabwe
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiZimbabwe
Index caseVictoria Falls
Arrival date20 March 2020
(4 years, 8 months, 1 week and 1 day)
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn4,075 (as of 3 August)[1]
Active cases2,938 (as of 3 August)
Iye àwọn tí ara wọn ti yá1,057 (as of 3 August)
Iye àwọn aláìsí
80 (as of 3 August)

Àjàkàlẹ-àrùn ẹ̀rànkòrónà (COVID-19) ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ pé ó dé orílẹ̀-èdè Zimbabwe ní oṣù kẹta ọdún 2020. Àwọon agbègbè tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Zimbabwe, ní pàtàkì àwọn bi i Manicaland, Masvingo àti Mashonaland tí ó wà ní ìla-òor̀ùn orílẹ̀-èdè Zimbabwe paapa ti ń tiraka pẹ̀lú ìbújáde àrùn ibà kan tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò kanna. Bíòtilẹ̀ jẹ́ wípé àrùn ibà jẹ́ àrùn tí ó ṣe é wò, ètò ìlera ń dojúko àító òògùn èyí tí ó fa kí ìgaara má a pọ̀si pẹ̀lú bí àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ṣe ń tàn kálẹ̀.[2]

Ní ọjọ́ kejìla oṣù kini ọdún 2020, àjọ ìlera ní àgbáyé (World Health Organization) fìdí rẹ múlẹ̀ pé kòkòrò àrùn ẹ̀rànkòrónà ni ó ń fa àrùn atẹ́gùn ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìlú Wuhan ní agbègbè Hube, orílẹ̀-èdè China, èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ fún àjọ ìlera ní àgbáyé ní ọjọ́o kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2019.[3]

Ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn COVID-19 kéré púpọ̀ sí ti àrùn SARS tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2003[4][5] ṣùgbọ́n bí àrùn COVID-19 ṣe ń tàn káàkàkiri pọ̀ púpọ̀, ní pàtàkì tí a bá wo iye àwọn tí ó ti jẹ́ aláìsí.[6][7]

Àwọn àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yí ń ṣẹlẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oṣù Kẹta Ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹta ni orílẹ̀-èdè Zimbabwe kéde ̀ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́ àjàkálẹ̀-àrùn kòrónà ní orílẹ̀-èdè wọn. ̀iṣẹ̀lẹ̀ yí ni ti arákùnrin kan tí ó ń gbé ni Victoria Falls tí ó padà dé láti orílẹ̀-èdè àwọn aláwọ̀ funfun (United Kingdon) tí ó sì gba gúúsù ti orílẹ̀-èdè Afrika (South Africa) wa sí orílẹ̀-èdè Zimbabwe ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta.[8] Wọn kò kéde pé ẹnikéni jẹ́ aláìsí gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn kan ti ṣèèsì sọ wípé ẹnìkan jẹ́ aláìsí láì mọ̀ pé aláìsàn yí ṣi n tẹ̀síwájú láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ ní ilé rẹ níbití ó ti n rí àpeere ìwòsàn.[9]

Ìṣẹ̀lẹ̀ méjì míràn ni ó tún ṣẹlẹ̀ ní Harare[10], orílẹ̀-èdè Zimbabwe ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹta. Ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ pé olókìkí akọ̀ròyìn ọmọ orílẹ̀-èdè Zimbanwe tí orúko rẹ̀ ń jẹ́ Zororo Makamba ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ jẹ́ aláìsí ní orílẹ̀-èdè Zimbabwe látàrí àjàkálẹ̀-àrùn kòrónà.[11][12][13]

Ní oṣù kẹta, ènìyàn mẹ́jo ni àyẹ̀wò fi hàn pé wọ́n ní àrùn kòrónà, ènìyàn kan jẹ aláìsí nígbà tí àwọn ènìyàn méje tí ó ṣẹ́kù ń gba ìtọ́jú títí di òpin oṣù kẹta.

Oṣù Kẹrin Ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn ikú arákùnrin Zororo, ènìyàn méjì míràn ló tún ṣe aláìsí tí àwọn tí ó ti kú wá di mẹ́ta.[14] Nítorí àító àwọn ohun èlò fún ìlera, àwọn oníṣègùn kọ ìwé fi ẹ̀sùn kan ìjọba nítorí kí wọn lè ní ìdáábòbò tí ó péye nígbàtí wọ́n bá ń tọ́jú àwọn aláìsàn tí àrùn yí ń bájà.[15] Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹrin, wọ́n kéde ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ta òmíràn èyí tí ó mú kí àpapọ̀ iye ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn kòrónà ní orílẹ̀-èdè Zimkbabwe di mẹ́tàdínlógún.

Ó kéré tán, àwọn akọ̀ròyìn márùn ún ni wọ́n ti mú fún ẹ̀sùn pé wọ́n ṣe àkójọpọ̀ ìròyìn lórí àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19.[16]

Nínú oṣù kẹrin ọdún, ènìyàn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni àyẹ̀wò fi hàn pé wọ́n ní àrùn kòrónà tí ènìyàn mẹ́ta si jẹ́ aláìsí nínú un wọn. Iye ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fìdí rẹ múlẹ̀ látìgbà tí ìbújáde àrùn yí ti bẹ̀rẹ̀ ti di mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n. Iye àwọn tí wọ́n ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ní òpin oṣù kẹrin ti di márùndínlọ́gbọ̀n (èyí tí ó ti lọ sókè pẹ̀lú ìdá ọ̀tàlénígba dín mẹ́ta nínú ọgọ́rùn ún(257%) láti oṣù kẹta.)

Oṣù kárùn ún Ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nínú oṣù kárùn ún, ènìyàn mẹ́rìnlélógóje(144) ni àyẹ̀wò fi hàn pé wọ́n ní àrùn kòrónà. iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fìdí rẹ múlẹ̀ látìgbà tí ìbújáde àrùn yí ti bẹ̀rẹ̀ ti di méjìdínlọ́gósàn án(178). Iye àwọn tí wọn ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ní òpin oṣù kárùn ún jẹ́ márùndínláàdọ́jọ(145) (èyí tí ó ti lọ sókè pẹ̀lú ìdá 480 nínú ọgọ́rùn ún(480%) láti oṣù kẹrin.)

Oṣù Kẹfà Ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹfà, ẹgbẹ́ aláré ìdárayá ti kirikẹti (Indian national cricket team) kéde wípé àwọn ti fagilé ìrìn-àjò wọn tí wọ́n ti gbèrò pé àwọn fẹ́ ṣe lọ sí orílẹ̀-èdè Zimbabwe ní oṣù kẹjọ ọdún 2020.[17]

Mínísítà fún ètò ìlera, Obadiah Moyo, ni wọ́n mú lábẹ́ òfin nítorì ẹ̀sùn èèrú ṣíṣe lórí owó tí ó lé ní milionu mẹ́rin dọ́là owó ilẹ̀ Améríkà (US$4million) pẹ̀lú ọmọ Alákòso ọkùnrin, Collins Mnangagwa, èyí tí ó ní ṣe pẹ̀lú ríra àwọn ǹ kan èlò fún ídáàbòbò ara ẹni fún àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ní ọ̀nà àìtọ́.[18]

Ní oṣù kẹfà, àwọn ènìyàn irinwó àti mẹ́tàlá(413) ni àyẹ̀wò fi hàn pé wón ní àrùn kòrónà èyí tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fìdí rẹ múlẹ̀ láti ìgbàtí ìbújáde àrùn yí ti bẹ̀rẹ̀ di 591. Iye àwọn tí wọ́n ti jẹ́ aláìsí lọ sókè si méje. Ní òpin oṣù kẹfà, àwọn aláìsàn 422 ni ó ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́, èyí tí ó lọ sókè pẹ̀lú ìdá mọ́kànléláàdọ́wàá nínú ọgọ́rùn ún(191%) láti òpin oṣù kárùn ún.

Oṣù Keje Ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ti kéde wípé àwọn ènìyàn 105,000 ni àwọn ti mú fún ẹ̀sùn lílòdì sí àwọn ìgbésẹ̀ ètò ìlera láti dẹ́kun àrùn COVID-19 láti oṣù kẹta; eléyì í pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ̀rún ún ènìyàn tí wọ́n mú nítorí pé wọn kò wọ ìbòmú ní ọjọ́ kejìdínlógún àti ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù keje.[19]

Ní ọjọ́ kankàndílógún oṣù keje, orílẹ̀-èdè Zimbabwe kéde ìsénimọ́lé kónílé ó gbélé ṣùgbọ́n wọ́n gba àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì nìkan láàyè láti ṣe iṣẹ́ laarin agogo mẹ́jọ òwúrọ̀ sí agogo mẹ́ta ọ̀sán.[20][21] Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ìjọba pé ìjọba ń lo ànfààní àjàkálẹ̀-àrùn yí láti fi lòdì sí ìwọ́de tí àwọn kan ń gbèrò láti gùnlé lórí ṣíṣe owó ilu mọ́kumọ̀ku.[22]

Láti ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù keje ọdun 2020, orílẹ̀-èdè Zimbabwe kéde ̀ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tó 2,817 nínú èyí tí ogójì àwọn aláìsàn ti jẹ́ aláìsí. Àpapọ̀ iye àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n ti ṣe jẹ́ 124,194 nínú èyí tí 68,194 ti ṣe àyẹ̀wò tí ó múnádóko (Rapid Diagnostic Test).[23] Ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun 2,578 ni ó ṣẹ́yọ ní oṣù keje èyí tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fìdí rẹ múlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìbújáde àrùn yí lọ sókè sí 3,169. Iye àwọn tí wọ́n ti jẹ́ aláìsí ti di mẹ́tàdínláàdọ́rin(67). Iye àwọn aláìsàn tí wọ́n ti gba ìwòsàn ti di 1,004 ó wá ku àwọn aláìsàn 2,098 tí wọ́n ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ní òpin oṣù keje.

Ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù keje, Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀, ètò ọ̀gbìn àti ìgbèríko (Minister of Lands, Agriculture and Rural Resettlement), Perrance Shiri ṣe aláìsí látipasẹ̀ àrùn COVID-19 lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí awakọ̀ rẹ na ti farakó àrùn yí.[24][25]

Oṣù Kẹjọ Ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n jẹri si bi ìṣẹ̀lẹ àrùn kòrónà ṣe ń pọ̀ si ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹjọ pẹ̀lú àwọn aláìsàn tó kú látipasẹ̀ àrùn COVID-19 tí wọ́n jẹ́ ìlópo, láti ogójì sí ọgọ́rin laarin ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù keje àti ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ.[26]

Ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ, márùn ún nínú àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ bí owó ṣe ń wọlé (Revenue Authority officials) ní orílẹ̀-èdè zimbabwe tí wọ́n wá láti Beitbridge níbi ààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè South Africa ni àyẹ̀wò fi hàn pé wọ́n ní àrùn kòrónà. Eléyì í ló mú kí ilé-iṣẹ́ ìlera àti ìtọ́jú ọmọdè (Ministry of Health and Child Care) gùnlé ṣíṣe àyẹ̀wò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ wọn àti ṣíṣe ìmọ́tótó sí àwọn ohun èlò wọn.[27]

Àwọn ọ̀nà láti fi dènà àrùn COVID-19 àti àwọn ipa tí àwọn ọ̀nà yí ń kó

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kí ó tó di wípé wọ́n fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn COVID-19 múlẹ̀ rárá ni orílẹ̀-èdé Zimbabwe ni alákòso Emmerson Mnangagwa ti kọ́kọ́ kéde àkókò pàjáwìrì ní orílẹ̀-èdè Zimbabwe tí wọ́n sì dáwó rínrin ìrìn-àjò dúró àti fífagilé àwọn ìpéjọpọ̀ ńlá.[28] Ọ̀rọ̀ tí Mínísítà fún ààbò ní orílẹ̀-èdè Zimbabwe, Oppah Muchinguri, sọ wípé ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn ẹ̀rànkòrónà le jẹ́ ìbáwí Ọlọ́run lórí àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀ funfun fún fífi ìyà jẹ orílẹ̀-èdè Zimbabwe fa àríyànjiyàn.

Ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, alákòso Mnangagwa kéde àfikún àwọn ìlànà míràn láti dẹ́kun àrùn kòrónà.

  1. Títi ẹnubodè orílẹ̀-èdè Zimbabwe pa fún àwọn ìrìn-àjò tí kò bá ṣe pàtàkì ṣùgbọ́n wọ́n yànda àwọn ará ìlú àti àwọn ẹrù tí wọ́n bá ń bọ̀.
  2. Títìpa àwọn ilé ọtí, àwọn ibi ìgbafẹ́ alẹ́, àwọn ibi eré sinimá, àwọn ibi ìlúwẹ̀ inú odò, àti àwọn ètò eré ìdárayá.[29]
  3. Ìpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn kò gbọ́dọ̀ tó ààdọ́ta.[30]
  4. Ṣíṣe àbẹ̀wò sí ilé ìwòsàn kò gbọdọ̀ ju ẹẹkan lọ ní ọjọ́ kan.[31][32]

Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ìjọba kéde pé orílẹ̀-èdè Zimbabwe yíò lọ fún ìsénimọ́lé ọlọ́jọ́ mọ́kànlélógún bẹ̀rẹ̀ láti ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹta títí di ìgbà tí wọn ko i ti le kéde. Agbègbè ìwòran ti Victorial Falls ni wọ́n tún tì pa gẹ́gẹ́ bí i arapa àwọn ìgbésẹ̀ ìsénimọ́lé orílẹ̀-èdè Zimbabwe àti ti Zambia.[33] Lára àwọn àgbékalẹ̀ fún ìsénimọ́lé ọlọ́jọ́ mọ́kànlélógún ni wọ́n ti mú rọrùn látàrí bí wọ́n ṣe gba àwọn ilé-ìtajà ńlá ńlá laaye láti tún má a ta ọtí.[34] Ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹrin, orílẹ̀-èdè olómìnira Zimbabwe ṣe àjọyọ̀ ológójì ọdún tí wọ́n gba òmìnira lábẹ́ ẹ ìsénimọ́lé fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Zimbabwe. Ní àkókò ìsénimọ́lé yi, ọ̀kànlénígba àwọn ìbújáde àrùn ibà ni wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ wọn, àádọ̀rún(90) nínú wọn ni wọ́n lè kápá nígbà tí mọ́kànléláàdóje(131) àwọn ènìyàn ń kú.

Àjọ IMF ṣe ìṣirò pé ó ṣe é ṣe kí ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè Zimbabwe jooro pẹ̀lú ìdá 7.4% ní ọdún 2020 nítorí àbájáde ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn kòrónà.[35]

Ìyanṣẹ́lódì àwọn òṣìṣẹ́ oníṣègùn mú ìpalára wá fún dídènọ̀ àrùn kòrónà àti ìtọ́jú àwọn aláìsàn àrùn kòrónà ní oṣù mẹ́rin àkọ́kọ́ ti i ọdún 2020.[36]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Zimbabwe Coronavirus - Worldometer" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-08-03. 
  2. Chingono, Nyasha (2020-04-21). "Zimbabwe faces malaria outbreak as it locks down to counter coronavirus". the Guardian. Retrieved 2020-08-07. 
  3. Reynolds, Matt; Weiss, Sabrina (2020-02-24). "How coronavirus started and what happens next, explained". WIRED UK. Retrieved 2020-08-07. 
  4. "Crunching the numbers for coronavirus - Imperial College London". Imperial News. 2020-03-13. Retrieved 2020-08-07. 
  5. "High consequence infectious diseases (HCID)". GOV.UK. 2018-10-22. Retrieved 2020-08-07. 
  6. Higgins, Annabel (2020-08-07). "Coronavirus". World Federation Of Societies of Anaesthesiologists. Archived from the original on 2020-03-12. Retrieved 2020-08-07. 
  7. "Crunching the numbers for coronavirus - Imperial College London". Imperial News. 2020-03-13. Retrieved 2020-08-07. 
  8. Perraudin, Frances; Quinn, Ben; Farrer, Martin; Rawlinson, Kevin; Marsh, Sarah; Goñi, Uki; Greenfield, Patrick; Cowie, Sam; Wintour, Patrick; Willsher, Kim; Smith, Helena; Duncan, Pamela; Kuo, Lily; Jolly, Jasper; Oltermann, Philip; Walker, Amy; Kirchgaessner, Stephanie; Dodd, Vikram; McKernan, Bethan; Kassam, Ashifa; Hern, Alex; Bakare, Lanre; Brown, Mark; Mohdin, Aamna; Topham, Gwyn; Topping, Alexandra; Adams, Richard; Doherty, Ben; McCurry, Justin; Ratcliffe, Rebecca; Davidson, Helen; Phillips, Dominic (2020-03-21). "Coronavirus as it happened: global cases top quarter of a million, as Italy sees biggest daily rise in deaths". the Guardian. Retrieved 2020-08-07. 
  9. Chirisa, Sharon (2020-03-20). "Zimbabwe Confirms Its First Case Of Coronavirus.. More Results Pending". iHarare News. Retrieved 2020-08-07. 
  10. eDuzeNet (2020-03-21). "BREAKING: Two new coronavirus cases confirmed in Harare". Bulawayo24 News. Archived from the original on 2023-05-16. Retrieved 2020-08-07. 
  11. Maphanga, Canny (2020-03-23). "Journalist Zororo Makamba becomes Zimbabwe's first Covid-19 death". News24. Retrieved 2020-08-07. 
  12. "Journalist is first person in Zimbabwe to die from Covid-19". TimesLIVE. 2020-03-23. Retrieved 2020-08-07. 
  13. Daniels, Lou-Anne (2020-03-23). "Media personality Zororo Makamba becomes first Zimbabwe coronavirus fatality". IOL. Retrieved 2020-08-07. 
  14. Twitter https://twitter.com/MoHCCZim/status/1247956570341810178. Retrieved 2020-08-07.  Missing or empty |title= (help)
  15. "Coronavirus: Zimbabwe doctors sue over 'dire shortage' of protective gear". News24. 2020-04-07. Retrieved 2020-08-07. 
  16. "Press freedom violations throughout Africa linked to Covid-19 coverage". RFI. 2020-04-14. Retrieved 2020-08-07. 
  17. "COVID-19: After SL Series Postponement, BCCI Calls Off India's Tour of Zimbabwe". India News, Breaking News, Entertainment News | India.com. 2020-06-12. Retrieved 2020-08-07. 
  18. India, Business Insider (2020-06-20). "Zimbabwe's health minister arrested in COVID-19 graft case". Business Insider. Retrieved 2020-08-07. 
  19. "Zimbabwe arrests 100,000 for Covid-19 'breaches'". BBC News. 2020-07-19. Retrieved 2020-08-07. 
  20. Kuyedzwa, Crecey (2020-07-21). "Zimbabwe imposes dusk-to-dawn curfew after spike in Covid-19 cases". Fin24. Retrieved 2020-08-07. 
  21. "Zimbabwe". BBC News (in Èdè Latini). 2020-07-31. Retrieved 2020-08-07. 
  22. Matenga, Moses (2020-07-26). "Mnangagwa snaps as July 31 beckons". Zimbabwe Situation. Retrieved 2020-08-07. 
  23. Twitter https://twitter.com/MoHCCZim/status/1288227157911764993. Retrieved 2020-08-07.  Missing or empty |title= (help)
  24. Kuyedzwa, Crecey (2020-07-29). "Zimbabwe's land minister dies days after personal driver is buried". News24. Retrieved 2020-08-07. 
  25. "Zimbabwe government minister died from COVID-19". Yahoo News. Retrieved 2020-08-07. 
  26. "Zimbabwe Coronavirus: 4,395 Cases and 97 Deaths". Worldometer. Retrieved 2020-08-07. 
  27. Muleya, Thupeyo (2020-08-03). "Zimbabwe: Covid-19 - Border Post Conducts Mass Testing". allAfrica.com. Retrieved 2020-08-07. 
  28. "Are you a robot?". Bloomberg. 2020-03-17. Retrieved 2020-08-07. 
  29. "#COVID19: Nightclubs, bars banned, borders closed in Zimbabwe". Three Men On A Boat. 2020-03-23. Retrieved 2020-08-07. 
  30. "In Zimbabwe, 'you win coronavirus or you win starvation'". ABC News. 2020-03-30. Retrieved 2020-08-07. 
  31. Chirisa, Sharon (2020-03-24). "Coronavirus Zim Update: Ministry Of Health Statement". iHarare News. Retrieved 2020-08-07. 
  32. Chingono, Nyasha; Busari, Stephanie (2020-03-23). "Prominent 30-year-old Zimbabwe broadcaster dies of coronavirus". CNN. Retrieved 2020-08-07. 
  33. "Zimbabwe". BBC News (in Èdè Latini). 2020-07-31. Retrieved 2020-08-07. 
  34. "Zimbabwe". BBC News (in Èdè Latini). 2020-07-31. Retrieved 2020-08-07. 
  35. Zwinoira, Tatira (2020-04-16). "Economy to contract by 7,4% : IMF". Zimbabwe Situation. Retrieved 2020-08-07. 
  36. "Zimbabwe billionaire offers health workers support in coronavirus fight". Yahoo News. 2018-08-26. Retrieved 2020-08-07.