Àjakálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Bùrúndì
COVID-19 pandemic in Burundi | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Burundi |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, China |
Index case | Bujumbura |
Arrival date | 31 March 2020 (4 years, 8 months and 1 day) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 191 (as of 6 July)[1] |
Active cases | 72 (as of 6 July) |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 118 (as of 6 July) |
Iye àwọn aláìsí | 1 (as of 21 June) |
Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ní orílẹ̀-èdè Burundi Àrùn Kòrónà wọ orílẹ̀-èdè Burundi ní ọjọ́ Kínní oṣù Kẹrin ọdún 2020.[2]
Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kíní ọdún 2020, Àjọ ìṣọ̀kan tí ó ń rí sí ìlera ní àgbáyé fìdí àrùn Kòrónà tí a tún ń pè ní Kofid-19 ní orílẹ̀-m àgbáyé ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kínní ní ọdún 2020. Tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àrùn yí bẹ̀rẹ̀ ní ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Wuhan, ní ẹkùn Hubei ní orílẹ̀-èdè China. Àmọ́ ó tó ọjọ́ Kẹtalélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019 kí wọ́n tó fi tó àjọ ìṣòkan àgbáyé létí.[3][4]
Wón tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ siwájú si wípé bí àrùn yí bá ti mú ènìyàn, oun ni ó ń fa ìfúnpinpin ní ní inú káà ọ̀fun ati àyà, tí ó sì ma ń fa kàtá tàbí kí ènìyàn ó ma wú ikọ́ tàbí sín léra léra. Iye ìjàmbá tí àrùn Kòrónà ti fà lágbáyé kéré sí iye ìjàmbá tí àìsàn àrùn ọ̀fun SARS ti fà láti ọdún 2003. Àmọ́ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n tó àrùn Kòrónà látàrí ríràn tí ó.ń ràn kálẹ̀ ti.pọ̀ ju ti SARS lọ, [5][6] bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé ìtànkálé àrùn COVID-19 ń gbópọn si lójojúmọ́ tí ó sì ti ṣekú pa ọ̀pọ̀l9pò ènìyàn lágbáyé.[7][5] .[8]
Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ní àwọn àsìkò kọ̀ọ̀kan
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àdàkọ:2019–20 coronavirus pandemic data/Burundi medical cases chart
Oṣù Kẹ́ta ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Mínísítà fún ètò ìlera fún orílẹ̀-èdè Burundi, ọ̀gbẹ́ni Thadée Ndikumana fìdí bí àrùn Kòrónà ṣe wọ orílẹ̀-èdè náà látara àwọn ènìyàn méjì kan wọ́n jẹ́.ọmọ.orílẹ̀-èdè Burundi tí wọ́n ń darí bọ̀ láti orílẹ̀-èdè Rwanda àti Ìlú Dubai. ní ọjọ́ Kẹtàlélọ́gbòn oṣù Kẹ́ta ọdún 2020.[9]
Oṣù Kẹrin ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ Kejì oṣù Kẹrin, wọ́n tún fìdí àìsàn yí múlẹ̀ lára àwọn ènìyàn bí obìnrin tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju mẹ́rìndílọ́gbọ̀n lọ, nígbà tí àwọn ènìyàn méjìlélógún tókù kò ní àrùn yí lẹ́yìn àyẹ̀wọ̀ àìsàn àrùn Kòrónà.[10] Lápapọ̀, iye àwọn tí wọ́n tún ní àrùn yí ní àárín oṣù Kẹ́rin ń lọ bí Mẹ́tàlá, tí ó sì mú kí iye àwọn aláìsàn Kòrónà jẹ́ Mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ẹnìkan ṣoṣo ni ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú àìsàn náà ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹrin,àwọn mẹ́jọ ní ìmúlára dá rí ó sì mú kí ó jẹ́.wípé.àwọn àwọn mẹ́fà péré ló ṣì ní àrùn yí ní ìparí oṣù náà. [11]
Oṣù Karùún ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Karùún, aṣojú ilẹ̀ Burundi kọ ìwé kan sí ilé iṣẹ́ àjọ ìṣọ̀kan tí ó ń rí sí ìlera ọmọnìyàn lágbàáyé tí ẹ̀ka rẹ̀ tó wà ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, tí ó sì pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́rin ilé-iṣẹ́ ètò ìlera náà tí ó ń ṣagbátẹrù ìdáhùn sí èsì àrùw Kòrónà ní orílẹ̀-èdè Burundi wípé.kí wọ́n palẹ̀ ẹrù wọn mọ́, kí wọ́n sì kúrò ní orílẹ̀-èdè.wọn kíá. Ìwé tí aṣojú orílẹ̀-èdè Burundi náà kọ sọ wípé àwọn òṣìṣẹ́ náà ti kọlu òfin tí wọ́n pè ní persona non grata , tí ó túmọ̀ sí wípé wọn kò ní àṣẹ kan kan bí ó ti wù kí ó rí láti wọ orílẹ̀-èdè.Burundi wá tàbí kí wọ́n pẹ́ kọjá gbèdéke tí ìjọba bá fún wọn lọ. Fúndí èyí, wọ́n g ọ́dọ̀ kúrò ní orílẹ̀-èdè àwọn kí Mẹ́ta ó tó pé. Bákan náà, Mínísítà tí ó rí sí ètò ìlera ní orílẹ̀-èdè Burundi náà.tún fi ẹ̀sùn kan ilé-iṣẹ́ àjọ ìṣọ̀kan agbáyé tí ó rí sí ètò ìlera wípé wọ́n ń dá.sí ọ̀rọ̀ ètò ìlera orílẹ̀-èdè àwọn ju bí ó ti yẹ lọ nípa bí àwọn ṣe ń mójú tó àjakálẹ̀ àrùn Kòrónà.[12]
Nínú oṣù yí kan náà, wọ́n tún ní akọsílẹ̀ ènìyàn tí iye wọn tó méjìdínláàdọ́ta tí wọ́n ti ní arùn COVID-19, tí ó sì mú kí iya àwọn tí wọ́n ti ní àrùn yí ó fò fẹ̀rẹ̀ lọ sí mẹ́tàlélọ́gọ́ta, àmọ́ tí wọn kò pàdánú ẹ̀mí kọkan yàtọ̀ sí àwọn ti tẹ̀.[13]
Oṣù Kẹfà ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ Kẹjọ oṣù Kẹfà, Ààrẹ ilẹ̀ Burundi ògbẹ́ni Pierre Nkurunziza ṣe aláìsí látàrí àìsàn àyà jíjá tí ó ma ń wáyé látara éjẹ̀ ríru, gẹ́gẹ́ bí àwọn olóòtú ìjọba wọn ti sọ. Amọ́ ṣá, àwọn ará Ìlú ń fẹ̀sùn kan àwọn olóòtú ìjọba wọ̀nyí wípé wọ́n kò ṣòtítọ́ nípa bí àjakálẹ̀ àrùn náà ṣe ń lọ sí ní orílẹ̀-èdè wọn, nítorí wípé wọ́n gbé ìyàwó Ààrẹ wọn lọ sí olú-ìlú Kenya fún ìtọ́jú látàrí bí ó ṣe ní àrùn Kòrónà ní ọjọ́ mẹ́wàá ṣáájú ikúọkọ eẹ̀. [14] some have speculated that the president died of COVID-19.[15]
Nínú oṣù Karùún, iye àwọn tí wọ́n ti ní àrùn Kòrónà ti gùnkè sí 170, nígbà tí wọ́n tún ní akọsílẹ̀ iye àwọn ènìyàn tí ó tó ọgọ́rùún kan àti ẹyọ méje. Amọ́ ẹnìkọkan kò kú, nígbà tí iye àwọn tí wọ́n ti rí ìwòsàn lápapọ̀ ti fi ọgọ́rùún kan àti ẹyọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. gba ìwòsan. [16]
Àwọn ìgbésẹ̀ ìdènà àrùn Kòrónà tí wọ́n gbé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìjọba orílẹ̀-èdè Burundi bẹ̀rẹ̀ ìyàsọ́tọ̀ ọ́jọ́ mẹ́rìnlá gbáko fún àwọn ènìyàn tí wọ́n bá wọ orílẹ̀-èdè náà wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míran tí àrùn yí bá ti tan dé sọ́tọ̀ sí iyàrá àdágbé ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹ́ta ọdún 2020. [17][18]
Ẹ̀wẹ̀, Ààrẹ ilẹ̀.Burundi ọ̀gbẹ́ni Nkurunziza kọ̀ jálẹ̀ láti fagilé ìgbòkè-gbodò ati lílọ-bíbò awọn ènìyàn ní orílẹ̀-èdè rẹ̀, nígbà tí ó sì fi àyè gba ìpolongo àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ati eré ìdárayá lápapọ̀.[15]
Ẹ tún lè wo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Burundi Coronavirus - Worldometer". www.worldometers.info (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-07-06.
- ↑ "Burundi confirms first 2 COVID-19 cases". www.aa.com.tr. Retrieved 2020-05-25.
- ↑ Elsevier. "Novel Coronavirus Information Center". Elsevier Connect. Archived from the original on 30 January 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Reynolds, Matt (4 March 2020). "What is coronavirus and how close is it to becoming a pandemic?". Wired UK. ISSN 1357-0978. https://www.wired.co.uk/article/china-coronavirus.
- ↑ 5.0 5.1 "Crunching the numbers for coronavirus". Imperial News. Archived from the original on 19 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "High consequence infectious diseases (HCID); Guidance and information about high consequence infectious diseases and their management in England". GOV.UK (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 3 March 2020. Retrieved 17 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "World Federation Of Societies of Anaesthesiologists – Coronavirus". www.wfsahq.org. Archived from the original on 12 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Future scenarios of the healthcare burden of COVID-19 in low- or middle-income countries, MRC Centre for Global Infectious Disease Analysis at Imperial College London.
- ↑ "Coronavirus: Burundi's first cases, death in Botswana, Ghana's mass recoveries". Africa News. 1 April 2020. https://www.africanews.com/2020/04/01/coronavirus-hub-impact-of-outbreak-across-africa/. Retrieved 1 April 2020.
- ↑ Burundi, IWACU (2020-04-02). "#Burundi Urgent Le ministre de la santé annonce le 3ème cas de covid-19. Une jeune fille de 26 ans. Le test pour 22 autres personnes a été négatif". @iwacuinfo (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-04-02.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 101" (PDF). World Health Organization. 2020-04-30. p. 8. Retrieved 2020-07-03.
- ↑ Burundi expels WHO officials coordinating coronavirus response
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 133" (PDF). World Health Organization. 1 June 2020. p. 7. Retrieved 3 July 2020.
- ↑ Junior, Mireri. "Burundi First Lady hospitalised at Aga Khan with Covid-19". The Standard (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-09.
- ↑ 15.0 15.1 correspondent, Jason Burke Africa (2020-06-09). "Burundi president dies of illness suspected to be coronavirus". The Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-09.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 163" (PDF). World Health Organization (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 1 July 2020. p. 7. Retrieved 2020-07-03.
- ↑ "Burundi extends quarantine to travelers from U.S., Britain, Australia". China (Xinhua) (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-17. Retrieved 2020-03-17.
- ↑ "Travelers to Burundi to be quarantined for coronavirus". Anadolu Agency (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-12. Retrieved 2020-03-17.