Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ní Orílẹ̀-èdè Senegal
Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ní orílẹ̀-èdè Senegal | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Senegal |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | France |
Index case | Dakar |
Arrival date | Ọjọ́ kejì oṣù kẹ́ta ọdún 2020 (4 years, 8 months and 1 day) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 6,459 (as of 27 June) [1] |
Active cases | 2,102 (as of 27 June) |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 4,255 (as of 27 June) |
Iye àwọn aláìsí | 102 (as of 27 June) |
Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ní Orílẹ̀-èdè Senegal is jẹ́ ọ̀kan lára Ìbúrẹ́kẹ́ àjakálẹ̀ àrùn Kòrónà tí a tún mọ̀ sí Kofid-19 tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní gbogbo àgbáyé. Ohun tí ó ń ṣokùnfà àìsàn yí ni àrùn ọ̀fun, àyà, ati imú tí wọ́n ń pè ní severe acute respiratory syndrome coronavirus 2 (SARS-CoV-2). Wọ́n fìdí ìwọlé sí orílẹ̀-èdè Senegal ní ọjọ́ Kejì oṣù Kẹ́ta ọdún 2020.
Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àjọ ìṣọ̀kan tí ó ń rí sí ìlera ní àgbáyé fìdí àrùn Kòrónà tí a tún ń pè ní Kofid-19 ní orílẹ̀-m àgbáyé ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kínní ní ọdún 2020. Tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àrùn yí bẹ̀rẹ̀ ní ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Wuhan, ní ẹkùn Hubei ní orílẹ̀-èdè China. Àmọ́ ó tó ọjọ́ Kẹtalélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019 kí wọ́n tó fi tó àjọ ìṣòkan àgbáyé létí.[2][3]
Wón tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ siwájú si wípé bí àrùn yí bá ti mú ènìyàn, oun ni ó ń fa ìfúnpinpin ní ní inú káà ọ̀fun ati àyà, tí ó sì ma ń fa kàtá tàbí kí ènìyàn ó ma wú ikọ́ tàbí sín léra léra. Iye ìjàmbá tí àrùn Kòrónà ti fà lágbáyé kéré sí iye ìjàmbá tí àìsàn àrùn ọ̀fun SARS ti fà láti ọdún 2003. Àmọ́ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n tó àrùn Kòrónà látàrí ríràn tí ó.ń ràn kálẹ̀ ti.pọ̀ ju ti SARS lọ.,[4][5][6][4]
Àwọn àsìkò kọ̀ọ̀kan tí ó ṣẹlẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ Kejì oṣù Kẹ́ta ọdún 2020. Arákùnrin kan tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Faranse ni ẹni akọ́kọ́ tí ó kó àrùn [[COVID-19 náà wọ orílẹ̀-èdè Senegal. [7] Arákùnrin yí ni ó ń gbé ní agbègbè Almadies Arrondissement ní ìlúDakar, nígba tí wọ́n ṣe àyéwò fun ní Pasteur Institute ní ìlú Dakar, ni wọ́n tó ri wípé ó ní àrùn Kòrónà. [7] Àmọ́ ṣáájú kí wọ́n tó ṣàyẹ̀wò fun ni ó ti kọ́kọ́ ṣe ìrìn-àjò tí ó sì wọ ọkọ̀ òfurufú Air Senegal ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejì, ọdún 2020.[7] Báyí ni orílẹ̀-èdè Senegal di orílẹ̀-èdè Kejìtí yóò ní akọsílẹ̀ àrùn àkóràn Kòrónà ní ilẹ̀ ìyàngbẹ Adúláwọ̀, lẹ́yìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Akọsílẹ̀ àrùn Kòrónà ẹlẹ́kejì ni ti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kan tí ówá sí Dakar láti ìlú Faransé.[8] Nígbà tí yóò fi di ọjọ́ Kẹ́rin oṣù Kẹta ọdún 2020, iye àwọn ènìyàn tí ó ti ní àrùn Kòrónà ti pé mẹ́rin, tí gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀rin sì jẹ́ àjòjì. Ẹni tí ó jẹ́ ẹni kẹ́ta tí ó ní àrùn yí ni ìyàwó ẹni akọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ kó àrùn náà wọ orílẹ̀-èdè Senegal, òun ni ó dẹ́ sí Ìlú Dakar ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Kẹta, nígba tí ọmọ ilẹ̀ Britain kan tí ó wá láti Ìlú Lodon wọ orílẹ̀-èdè Senegal ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kejì ọdún 2020.[9] Àwọn àjọ tí ó rí sí bọ́ọ̀lù aláfọwọ́-gbá , ìyẹn Basketball Africa League fagilé eré ìdíje ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ní ọjọ́ Kẹfà oṣù Kẹ́ta ọdún 2020, tí ó yẹ kó wáyé ní ìlú Dakar. [10] Èyí wáyé látàrí ìbẹ̀rù tí ó múlẹ̀ ṣinṣin tí àrùn náà ti dá sílẹ̀, tí ó sì mú kí àwọn ènìyàn ó má lè kóra jọ pọ̀ mọ́ nínú Ilé Ìjọsin, ayẹyẹ pàá pàá jùlọ ayẹyẹ Grand Magal, tí ó níṣe pẹ̀lú ọdún Mouride tí ó ma ń wáyé ní Touba tabí ìrìnà-àjò káàkiri orílẹ̀-èdè Senegal, àti gbogbo agbáyé[11]
Ní ọjọ́ Kẹwàá oṣù Kẹ́ta, Mínísítà fún ètò ìlera ọ̀gbẹ́ni Abdoulaye Diouf Sarr, fi tó àwọn oníròyìn létí wípé ìjọba orílẹ̀-èdè Senegal yóò fòfin de ìpéjọoọ̀ tí ó jọ mọ́ ti ẹ̀sìn ìyẹn bí àwọn ará-ìlú bá fọwọ́ si. Ní ọjọ́ tí Mínísítà fún ètò ìlera sọ̀rọ̀ yí náà ni wọ́n tún fìdí àrùn yí múlẹ̀ lára ìkan nínú ọmọ orílẹ̀-èdè Senegal tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti orílẹ̀-èdè Italy, èyí sì mú kí iye aláìsàn ó gòkè sí márùún gedengbe.[12]
Ní ọjọ́ kejìlá oṣù Kẹ́ta, ìjọba orílẹ̀-èdè Senegal tún kéde akọsílẹ̀ àrùn Kòrónà márùún mìíra lára àwọn ènìyàn márún ọ̀tọ̀tò, tí wón jẹ́ ẹbí aláìsàn Karùún tí ó dé láti orílẹ̀-èdè Italy [13] Ọ̀kan lára nínú àwọn ẹbí márùún tí wọ́n fara káṣá àrùn ni ó wá ní ilẹ̀ mímọ́ ti Touba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn olórí ẹlẹ́sìn ní Touba ti dánu wípé àrùnkárùn kò lè mú ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìlú Touba náà.[14]
Nígba tí yóò fi di ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù Kẹta, iye àwọn ènìyàn tí ó ti ní àrùn Kòrónà ti tó mẹ́rìnlélógún.[15] Ìjọba orílẹ̀-èdè Senegal fòfin de lílọ-bíbọ̀ àwọn ènìyàn , wọ́n ti gbog o ilé-ẹ̀kọ́ pa fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, wọ́n tún fòfin fagilé ìpéjọ-pọ̀ tí ó níṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn èyíkéyí léte ati dẹ́kun ìtankálẹ̀ àrùn COVID-19.[16].[17]
Ní ọjọ́ kọkànlá oṣù Karùún ọdún 2020, orílẹ̀-èdè Senegal ti ní akọsílẹ̀ tí ó ti tó ìdá ọgbọ̀n. [18] wọ́n sì sì gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin málọ mábọ̀, wọ́n tú ní kí gbogbo ilé-ìjọsìn ó padà sẹ́nu ìsìn wọn ní 9jọ́ Kejìlà oṣù Karùún. Iye ènìyàn tí ó ti kó àrùn COVID-19 ní àpapọ̀ jẹ́ 1,886, nígbà tí àwọn mọ́kàndínlógún pàdánù ẹ̀mí wọn sí ọwọ́ àrùn Kòrónà.
Ìdánilẹ́kọ́ nípa àrùn Kòrónà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní orílẹ̀-èdè Senegal, púpọ̀ nínú àwọn ayàwòrán ni wọ́n fi àwòrán yíyà ṣe ìdánilẹ́kọ́ àti ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nípa bí wọ́n ṣe lè dẹ́kun àrùn Kòrónà tí ó ń ràn kiri. [19]
Ẹ tún lè wo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- COVID-19 pandemic in Africa
- COVID-19 pandemic by country and territory
- 2020 in Senegal
- HIV/AIDS in Africa
- Western African Ebola virus epidemic
- 1918 Spanish flu pandemic
- 1957–1958 influenza pandemic
Àpilẹ̀kọ nípa àrùn Kòrónà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Leveau Mac Elhone, A., 2020. Le Graffiti pour sauver des vies : l'art s'engage contre le coronavirus au Sénégal, Paris : Éditions Dapper.
Àwọn Ìtókasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "COVID-19 Dashboard by the Center for Systems Science and Engineering (CSSE) at Johns Hopkins University (JHU)". 27 June 2020.
- ↑ Elsevier. "Novel Coronavirus Information Center". Elsevier Connect. Archived from the original on 30 January 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Reynolds, Matt (4 March 2020). "What is coronavirus and how close is it to becoming a pandemic?". Wired UK. ISSN 1357-0978. https://www.wired.co.uk/article/china-coronavirus.
- ↑ 4.0 4.1 "Crunching the numbers for coronavirus". Imperial News. Archived from the original on 19 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "High consequence infectious diseases (HCID); Guidance and information about high consequence infectious diseases and their management in England". GOV.UK (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 3 March 2020. Retrieved 17 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "World Federation Of Societies of Anaesthesiologists – Coronavirus". www.wfsahq.org. Archived from the original on 12 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 7.0 7.1 7.2 "Coronavirus : Le Sénégal enregistre son premier cas". Le Quotidien (in French). 2 March 2020. Retrieved 22 March 2020.
- ↑ "Second case of coronavirus in Senegal as African sports shelved". RFI (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 5 March 2020. Retrieved 14 March 2020.
- ↑ "Senegal confirms third and fourth coronavirus cases" (in en). Reuters. 4 March 2020. https://www.reuters.com/article/us-health-coronavirus-senegal-idUSKBN20R31G.
- ↑ "Basketball Africa League postpones start of inaugural season". NBA.com (Press release) (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 3 March 2020. Retrieved 14 March 2020.
- ↑ Paquette, Danielle & Tall, Borso (6 March 2020). "Coronavirus fears rise in Senegal as thousands travel for religious festivals". The Washington Post (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 14 March 2020.
- ↑ "Senegal confirms fifth case of COVID-19". aa.com.tr. Retrieved 14 March 2020.
- ↑ "Senegal announces 5 new coronavirus cases". News24. 12 March 2020. Retrieved 14 March 2020.
- ↑ "Coronavirus hits Senegal's holy city as cleric declares faithful are immune". Africanews (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 12 March 2020. Retrieved 14 March 2020.
- ↑ "Senegal orders all schools closed in response to coronavirus". Reuters. 14 March 2020. Retrieved 22 March 2020.
- ↑ Magome, Mogomot Si (15 March 2020). "Several African nations roll out measures to fight virus". Yahoo News. Associated Press. Retrieved 22 March 2020.
- ↑ "Ivory Coast, Senegal declare emergencies, impose curfews in coronavirus response". Reuters (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 23 March 2020. Retrieved 23 March 2020.
- ↑ "Senegal: Govt Eases COVID Restrictions Tuesday, a Day After Surge in Cases". allAfrica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 12 May 2020. Retrieved June 13, 2020.
- ↑ "Graffiti to save lives". African Studies Centre Leiden (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2 July 2020. Retrieved 18 July 2020.
Àwọn Ìjásòde
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Senegal: Street Children Among Those Most at Risk for COVID-19 (VOA)
- Senegal: Opening Mosques During Pandemic Divides Muslim Community (VOA)
- Senegal: "My main weapons: my smartphone and my voice"