Ẹ̀yà Awori

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Awori jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà àwọn ọmọ Yorùbá tí ń sọ èdè kan pàtó, èyí tí í ṣe èdè Yorùbá.

Ìwọ̀n agbègbè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ìbámu pẹ̀lú àṣà, àwọn ẹ̀yà Àwórì wà ní Ìpínlẹ̀ Ògùn àti Ìpínlẹ̀ Èkó, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[1] [2] Àwọn ìlú bíi Ikorodu, Epe, Badagry, Ota, Ado-Odo, Isheri, Igbesa, Agbara, Ilobi, àti Tigbo jẹ́ ibùgbé àwọn Awori, láàárín ìpínlè Ògùn, tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1976, ní orílè-èdè Nàìjíríà.[3]

Àwọn ará Awori ní ìtàn-àkọọ́lẹ̀ pípẹ́ nípa níní ibùgbé sí àárín Èkó, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìjọba amúnisìn. Àwọn ni wọ́n dá ìlú Èkó sílẹ̀, wọ́n jẹ́ pẹjapẹja àti oníṣòwò, ó sì fìdí múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òwò tí wọ́n ń ṣe ní apá Ìwọòrùn Áfíríkà.

Ìtàn orísun[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìtàn náà ni pé, Olófin àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kúrò ní ààfin Ọba Odùduwà (tó jẹ́ olùṣẹ̀dásílẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá) ní Ilé-Ifẹ̀, wọ́n sì ṣí lọ síhà Gúúsù létí odò kan. Odùduwà ti fún Olófin ní àwo kan tí wọ́n mọ, ó ní kí ó gbé e sórí omi, kí ó tẹ̀lé e títí tí ó fi máa rì sínú odò.[4]

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tí wọ́n kúrò ní Ilé-Ifẹ̀, àwo náà dúró lójijì sí agbègbè Olókèméjì, nítòsí Abeokuta tòde òní. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́tàdínlógún, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ, ó sì dúró sí Òkè-Ata fún ọjọ́ mẹ́tàdínlógún mìíràn. Ní ìparí ọjọ́ mẹ́tàdínlógún, àwo náà tún bẹ̀rẹ̀ síí lọ, ṣàdédé ni ó dúró sí ìhà Gúúsù ti Abẹ́òkuta lónìí, níbi tó ti dúró fún ọjọ́ mẹ́t̀dínlógún mìíràn. Níbí yìí ni àwọn ọmọ Ọlọ́fin kan pinnu láti dúró, tí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Osho Aro-bi-ologbo-egan sì jẹ́ olórí. Àwo náà tẹ̀síwájú sí ìsàlẹ̀, ó sì tún dúró ní Isheri. Ọlọ́fin bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn ìletò kan sílẹ̀. Àwọn ọmọlẹ́yìn náà sì béèrè pé "níbo ni àwo náà wà?", ó sì dáhùn pé "àwo ti rì". Báyìí ni wọ́n ṣẹ̀dá orúkọ wọn "Awori".[5]

Ọlọ́fin ní ìyàwó méjì, orúkọ wọn sì ni Akesan àti Ajaiye. Akesan bímọ ọkùnrin méjì (ìyẹn Ogunneru àti Ogunbiyi), tí Ajaiye sì yàgàn. Lẹ́yìn tí wọ́n tẹ̀dó sí ìlú Ìṣerì, Olófin lọ wádìí ọ̀rọ̀-onífẹ̀ẹ́ Ifá níbi tí wọ́n ti ní kí wọ́n lọ síbi tí omi iyọ̀ wà. Wọ́n si ṣí kúrò ní Iṣeri, tí wọ́n wá lọ sí Iddo, níbi tí wọ́n sì gbé. Ajaiye bí ọmọ mẹ́jọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tí wọ́n sì máa dàgbà di Idejo òde-òní. Ó fún wọn ní ilẹ̀ láti máa ṣe oko. Àwọn Idejo náà ni: Aromire, Ojora, Onikoyi, Oniru, Oluwa, Oloto, Olumegbon àti Elegushi.[5]

Ogunneru ló padà gorí oyè lẹ́yìn Ọlọ́fin, tí ó sì di Ọlọ́fin Isheri, nígbà tí Ogunbiyi sì lọ tẹ àwọn ìlú mìíràn dó ní Awori.[5]

Ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orò àti Oree, Egúngún, Elegba, Ìgunukó, Opa, Osugbo àti Gẹ̀lẹ̀dé wà lára àwọn ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ tí wọ́n máa ń ní ní ìlú Awori. Wọ́n sì máa ń ṣayẹyẹ àwọn ọdún ẹ̀sìn mìíràn, bíi ẹ̀sìn Musulumi àti ọdún Kérésìmesì fún àwọn Kìrìsìtẹ́ẹ́nì. Èyí sì máa ń mú kí àwọn ọmọ-ìlú tó wà nílẹ̀ òkèèrè padà wálé láti wá bá wọn ṣàjọyọ̀.[6][7][8]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. E. A. Ajayi; R. O. Ajetunmobi; Akindele S. A. (1998). A History of the Awori of Lagos State. Adeniran Ogunsanya College of Education. ISBN 978-978-142-035-1. https://books.google.com/books?id=TH0uAQAAIAAJ. 
  2. Jeremy Seymour Eades (1980). The Yoruba Today. Cambridge University Press Archive. ISBN 978-0-521-22656-1. https://books.google.com/books?id=fwc5AAAAIAAJ&pg=PA15. 
  3. Cities, Towns and Villages in Ogun State Cities, Towns and Villages in Ogun State: Ilaro, Ota, Nigeria, Ijebu Ode, Sagamu, Abeokuta, Odogbolu, Ilaro. https://www.betterworldbooks.com/product/detail/cities-towns-and-villages-in-ogun-state-cities-towns-and-villages-in-ogun-state-115714991X. 
  4. Lloyd, Peter Cutt (1962) (in en). Yoruba Land Law /P.C. Lloyd. Published for the Nigerian Institute of Social and Economic Research. https://books.google.com/books?id=uf-XXwAACAAJ. 
  5. 5.0 5.1 5.2 Lloyd, Peter Cutt (1962) (in en). Yoruba Land Law /P.C. Lloyd. Published for the Nigerian Institute of Social and Economic Research. https://books.google.com/books?id=uf-XXwAACAAJ.  Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name ":0" defined multiple times with different content
  6. Refugees, United Nations High Commissioner for. "Refworld | Nigeria: Oro festival including the role of the Oro priest and whether, or not, he or she is masked; whether there are any penalties invoked against those who observe the priest performing his rituals". Refworld (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-01-24. 
  7. "UNESCO - Oral heritage of Gelede". ich.unesco.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-01-24. 
  8. "Egungun Masquerade Dance Costume: Ekuu Egungun". africa.si.edu. Retrieved 2023-01-24.