Adolfo Rodríguez Saá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Rodríguez Saá

Adolfo Rodríguez Saá(tí a bi ni 25 July 1947) jé Aare orile-ede Argentina tele. A bi sínú ìdíle olórò ni agbegbe San Luis, níbi tí bàbá-bàbá rè ti jé Gomina télè rí, tí bàbá rè sì jé olopa ní ìlú náà. Adolfo padà did Gomina agbègbè náà ní odun 1983 títí di odún 2001.[1]

Ni odún kan náà(odun 2001), Ààré Fernando de la Rúa kòwé fisé sílè nitori àìsimi ìlú, ìwóde ifehonuhan àti iwà ìpá ti o selè ní December 2001, àwon àpapò asofin ìlú náà sì yan Adolfo Rodriquez gegebi ààre orílè-èdè náà sùgbón Adolfo kòwé fipo náà sílè léyìn ojó mewa tó dé bè nitori àìsimi ìlú.[2] Adolfo padà díje fún ipò ààré orílè-èdè náà ní odún 2003 àti 2015, sùgbón ofidi remi.

Àárò ayé àti èkó rè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adolfo lo ilé-ìwé "Juan Pascual Pringles", ó padà tèsíwájú ní Yunifásitì ti Buenos Aires níbi tí o ti kékó gboyè nínú ìmò òfin ní odun 1971. Léyìn ìgbà to parí ìwé, o darapò egbé òsèlú Petronist ó sì tún sisé gégé bi olukoni ní ilé-ìwé tó ti kékó jáde fún odún méjì.

Ni 21 October 1993, àwon gbémo-gbémo méta, Walter Alejandro Salgado, Nélida Esther Sesín àti Eduardo Alberto Doyhenard jí Adolfo gbé, oun ni Gomina San Luis nígbà náà, àwon gbémo-gbémo yi gbe lo ilé-ìtùra "Y no C" níbi tí wón ti fi ìpá mu láti se filmu onihoho kan. Wón sì tún gba milionu meta dólà kí wón tó fi kalè séyìn moto kan. Àwon odaran méta yìí ko fi filmu náà síta, wón sì padà gbá won mú, a jù wón sé wòn ní odun 1995.[3]

Àwon ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Who is Adolfo Rodríguez Saá? Everything You Need to Know". Famous People in the World. 1947-07-25. Retrieved 2022-08-29. 
  2. País, El (2001-12-30). "Rodríguez Saá abandona la presidencia al no lograr el apoyo de los peronistas". El País (in Èdè Sípáníìṣì). Retrieved 2022-08-29. 
  3. Andes, Diario Los (2014-06-13). "Secuestro de Rodríguez Saá: los 3 condenados libres". archivo.losandes.com.ar. Archived from the original on 2015-10-06. Retrieved 2022-08-29.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)