Agustín Pedro Justo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Agustín Pedro Justo
President of Argentina
In office
20 February 1932 – 19 February 1938
Vice PresidentJulio Argentino Pascual Roca
AsíwájúJosé Félix Uriburu
Arọ́pòRoberto M. Ortiz
Minister of War
In office
12 October 1922 – 12 October 1928
ÀàrẹMarcelo Torcuato de Alvear
AsíwájúJulio Moreno
Arọ́pòLuis Dellepiane
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1876-02-26)26 Oṣù Kejì 1876
Concepción del Uruguay, Entre Ríos
Aláìsí11 January 1943(1943-01-11) (ọmọ ọdún 66)
Buenos Aires, Argentina
Ọmọorílẹ̀-èdèArgentine
Ẹgbẹ́ olóṣèlúUCR-A
Other political
affiliations
Concordancia
ProfessionMilitary
Signature
Military service
Branch/serviceArgentine Army
Years of service1892–1931
RankMajor General

Agustín Pedro Justo Rolón tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 1976 jẹ́ Ààrẹ apàṣẹwàá orílẹ̀-èdè Argentina tẹ́lẹ̀ láàrin ọdún 1932 sí 1938, ó sì tún jẹ́ olóṣèlú pẹ́lú ni.[1] Justo kòpa nínú ìdìtẹ̀-gbàjọba ti ọdún 1930, lẹ́yìn èyí ni ó di Ààrẹ pẹ́lú ìdìbò èrú. Ó jẹ Ààrẹ láàrín ọdún 1930 sí ọdún 1943. Òun ni ó da country's central bank sílẹ̀ tí ó sì da gbígba owó-orí sílẹ̀ pẹ̀lú.[2]

Ó yan olórí ìjọba Marcelo Torcuato de Alvear, pẹ̀lú ìrírí rẹ̀ lábẹ́ ìjọba alágbádá, ati ipa rẹ̀, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi 1931 campaign. Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kọkànlá ọdún 1931, pẹ́lú Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú (Partido Demócrata Nacional), Radical Civic Union (Unión Cívica Radical) (UCR), àti Socialist Independent Party (Partido Socialista Independiente). Wọ́n fi ẹ̀sùn ìṣèrú ìbò tí wọ́n fún lórúkọ patriotic fraud kàn án láàrín ọdún 1931 àti 1943. Lásìkò yí, àwọn olóṣèlú alátakò bíi Yrigoyen tí ó wá láti ẹgbẹ́ ìṣèlú Radical Civil Union. gbénáwojú ìṣèjọba rẹ̀.[3] Iṣẹ́ takuntakun tí Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè rẹ̀ Carlos Saavedra Lamas, ni ó jẹ́ àṣeyọrí pàtàkì fún ìṣèjọba rẹ̀, amọ̀ wọ́n fi ẹ̀sùn àjẹbánu rẹpẹtẹ kan ìṣèjọba rẹ̀ pẹ̀lú bí ó ṣe jọ̀wọ́ ètò ọrọ̀ Ajé orílẹ̀-èdè sọ́wọ́ àwọn British pàá pàá jùlọ ní ìgbà kejì rẹ̀ ọ̀gbẹ́ni Julio A. Roca Jr. ṣe tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn Roca-Runciman Treaty.

Nípa rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 1976 ní ìlú Concepción del Uruguay, ní ẹkùn Entre Ríos Province. Bàbá rẹ̀ Agustín,ti fìgbà kan rí jẹ́ Gómìnà fún ẹkùn Corrientes Province, kò pẹ́ púpọ̀ tí ó sì fi di ìgbà kejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè náà. Ó kópa nínú ìṣèlú orílẹ̀-èdè rẹ̀ títí ó fi bí ọmọ rẹ̀ Justo tí òun àti ẹbí rẹ̀ tó kó lọ sí Buenos Aires. Iya rẹ̀ Otilia Rolón, ní ó wá láti inú ẹbí Corrientes. Nígbà tí Justo wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Colegio Militar de la Nación (National Military College). Ó sì dra pọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tókù nínú Revolución del Parque, níbi tí wọ́n ti gba àwọn ohun ija fún àwọn ajìjangbara, wọ́n mú wọn amọ́ wọ́n da wọn sílẹ̀ẹ̀ láìpẹ́. Ó jáde nílé ẹ̀kọ́ yí pẹ̀lú ipò ensign.[4]

Awon itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Agustín P. Justo, Luciano de Privitellio, 1997, ISBN 9789505572397 
  2. La moneda y su historia, Rioja, Leonci, ISBN 9789870271017 [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. Hipólito Yrigoyen, Instituto Yrigoyeneano, 1978 
  4. Historia argentina: 1830-1992, Torcuato S. Di Tella, 1993, ISBN 9789501662467