Jump to content

Alexander Akínyẹlé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Alexander Babátúndé Akínyẹlé, CBE ni wọ́n bí ní (5 September 1875 - 1 October 1968) je Bíṣọ́ọ̀bù àgbà àkọ́kọ́ ní ìjọAnglican Diocesan ní ìlú Ìbadàn, ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. igeria. Òun ni èni àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn tí ó kọ́kọ́ gba oyè B.a ní ilé ẹ̀kọ́ Fásitì, tí ó sì kọ́kọ́ jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìwé gíga sẹ́kọ́ndìrì àkọ́kọ́ tí a mọ̀ sí ní ìlú Ìbàdàn Grammar School ni ìlú Ìbàdàn .

Ìbẹ́rẹ̀ ìgbésí-ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bolude, tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ tí ó sì jẹ́ Oníṣègùn ìbílẹ̀ tí ó tún jẹ́ ìlú Ìbàdànjagunjagun tí ó lààmì laaka lásìkò ìjọba Ọ̀yọ . Ni ó bí ọ̀gbẹ́ni Jòdià Akínyẹlé tí ó jẹ́ àkọ́bí rẹ̀, tí Jòdià sìjẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ọ̀gbẹ́ni David Hinderer , tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jamaní, tí ó sì tún jẹ́ olùṣọ́ Onigbagbọ (CMS), tí ọ̀gbẹ́ni Jòsià sì jẹẹ́ ọ̀kan lára àwọn mẹ́fà tí ó mú ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́ni wọ ìlú Ìbàdàn ní ọdún 1851. Josiah Akinyele jèrè ọkàn Abigail Lápènọ̀ sí inú ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì tí ó jẹ́ ọmọbìrin Kukomi, tí ó jẹ́ alágbára mìíràn ní ìlú Ìbàdàn lásìkò yí nípasẹ̀ ọ̀gbẹ́ni Hinderer gẹ́gẹ́ bí ìyàwó kejì ní ọdún 1870. Abigail bí ọmọ àkọ́kọ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ ọkùnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alexander Babátúndé Akínyẹlé. Bákan náà ni ó tún bí àwọ̀n àbúrò mẹ́ri lẹ́yìn rẹ̀, àmọ́ tí ọ̀kan nínú wọn jọ Babátúndé tìwà tìṣe, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Isaac Babátúndé Akínyẹlé tí gbogbo wọn sì jẹ́ ọ̀mọ̀wé, ẹlẹ́sìn àti òṣèlú pàtàkì ní ìlú Ìbàdàn ṣe ibùgbé láti ọ̀rùndún kọkàndínlógún.

Etò Ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lílọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Alexander Akínyẹlé lásìkò ológun ilẹ̀ Ìbadàn lásìkò náà dá lórí ẹọ̀pọ̀ ẹ̀bẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn Olùṣọ́ lé ìjọsìn , tí ó sì jẹ́ ohun tó lewu fún àwọn Lùṣọ́ náà. Àsìkò tí a ń wí yìí jẹ́ àsìkò òwò ẹrú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìjọba Britain ti fòpin sí òwò yìí, àwọn ará Ìbàdàn sì ń ṣe ọòwò náà lábẹ́lẹ̀, ìdí nìyí ìwà ìpani-ṣowó, ìjọ́mọ-gbé, fi wọ́pọ̀ lásìkò náà. Látàríàwọn ìdí wọ̀nyí, àwọn díẹ̀ lára àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n kàwé lásìkò yí ni àwọn jagunjagun tí ọ̀gágun wọn tí wọ́n ń pè ní Babambo ma ń gbé Alexander sí èjìká láti sìn wọ́n lọ sílé-ẹ̀kọ́. Alexander lọ sí ilé ẹ̀kọọ́bẹ̀rẹ̀ St. Peter's ní ìlú Ìbàdàn ní ọdún 1880, tí ó sì parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Abọ́badé tí ó wà ní Arọ́lọ́yà ní ìpínlẹ̀ Èkó. Tí àwọn ìjọ Church Missionary Society dá sílẹ̀. Lẹ́yìn èyì, Ó ltún lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ìkọ́ni ti àwọn olùkọ́ni ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ gboyè nípa ìmọ̀ ìkọ́n, lẹ̀yìn èyí, ó di olùkọ́ tí ó sìn tún ń ṣe iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùta dùrù(Organist), ọ̀gá akọrin, nínú ìjọ rẹ̀ lápá kan . Ọ̀gbẹ́ni Olùsọ́ Tugwell ṣe àbẹ̀wọò sí ìlú Abẹ́òkúya nígbàtí ó ń jáde ká ní ọdún 1903, tí ó sì ṣàkíyèsí iṣẹ́ akínkanjú Alex nípa títa dùrù ní ilé ìjọsìn tí ó wà ní Aké lÁbẹ́òkúta.nígbà ntí ó dé ọ̀dọ̀ wọn, tí ó sì gba Alex níyànjú wípé kí ó wá ṣe ìdánwò wọlé ẹ̀kọ́ Furh Bay ege, tií ó wà nì orílẹ̀ èdè Sierra Leone, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ ilẹ̀ Britain. Ó wọ iké ẹ̀kọ́ náà ní ọjọ́karùnlélógún 1qoṣù kínní ọfún 1904,(25 January,1904). Wọ́n fi oyè Licentiate ni Ẹ̀kọ́ nipa ìmọ̀ Ọlọ́run (LTh), lẹ́yìn èyí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè àkọ́kọ́ B.a ( Dunelm ) ni ọdun 1912, bayi ni ó sì di ẹni àkòkọ́ tójẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn tó kọ́kọ́ gba oyè àmì ẹ̀kọ́ Fásitì.

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùtàn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àbúrò rẹ̀ HRH Isaac Babalola Akinyeloni ó padà gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ Olúbàdàn ti Olúbàdàn tí òun náà jẹ́ Olúbàdàn àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ ọ̀mọ̀wé. Àwọn méjèjìbsì fẹ́ràn ilẹ̀ baba wọn. Ní ọdún 1949, wọ́n yan Alexander Akínyẹlé gẹ́gẹ́ bí Alákòóso Olùdarí Order ti ilẹ̀ Bíritènì. Bíṣọ́bù náà ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìtagbangba ní ọ̀jọ́ oṣù kejìlá ọdún 1956 nígbà tí Queen Elizabeth II ṣe àbẹ̀wọò sí ilẹ̀ Nàìjíríà, ní St. James Cathedral, Oke Bola , nílùú Ìbàdàn láti lo ọkàn, ọwọ́, àti ẹ̀yà ara gbogbo láti fi sin Jesu Kristi . Alexander Babalola Akinyele jẹ́oè Oluódùmarè ní ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́sàán ní ọdún 1968.


  • Theophilus Adeleke Akinyele : "Ibadan - ilu, ẹwà ati owurọ" ti a ti inu Awọn kika ni Iṣowo Iselu ati Ijoba ni Nigeria . Atejade nipasẹ CSS Ltd. 2002
  • Theophilus Adeleke Akinyele: "Awọn igbesi aye ati Akosile ti Bishop AB Gbigba" ọrọ kan ti a firanṣẹ ni 25 July 2002, ni Ibadan Grammar School.
  • Falola, Toyin (2000). Yoruba Gurus. Africa World Press. ISBN 0-86543-699-1.