Jump to content

Barry Jhay

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Barry Jhay
Orúkọ àbísọOluwakayode Junior Balogun
Ọjọ́ìbí13 Oṣù Kejì 1993 (1993-02-13) (ọmọ ọdún 31)
Ibadan, Oyo State, Nigeria
Irú orin
Occupation(s)Musician
Years active2018-present
LabelsCash Nation Entertainment

Oluwakayode Junior Balogun (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Kejì, ọdún,1993), tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Barry Jhay, jẹ́ olórin Afrobeats, ní Nàìjíríà, ó sì gbajúmọ̀ fún ìṣọwọ́kọrin rẹ̀ bí i ti orin ìbílẹ̀. Ìlú Ìbàdàn ni wọ́n bí i sí, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní Nàìjíríà, àmọ́ Eko ló dàgbà sí.[1][2] Wọ́n bí Barry sínú ìdílé ìlú mọ̀ọ́kà àwọn olorin olókìkí, orúkọ bàbá-bàbá rẹ̀ ń jẹ́ I. K. Dairo, tó jẹ́ olórin Juju, bàbá rẹ̀ sì ni Sikiru Ayinde Barrister, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ orin Fuji. [3][4] Ìdílé àwọn olórin ló dàgbà sí, ó sí mú orin ìgbàlódé ti Hip-pop mọ́ orin Juju, tó wá di orin Afro-Juju. Àhunpọ̀ àọn orin yìí sì mú orin aládùn wá, tó fara pẹ́ orin ìbílẹ̀ lápá kan, tó sì tún fara pẹ́ orin ìgbàlódé ti Hip-hop.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láti ìgbà èwe rẹ̀ ló ti nífẹ̀ẹ́ sí orin kíkọ nítorí ìdílé olórin ló ti wá. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ orin láti ọmọdún márùn-ún.[5] Ó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó jẹ́ ìwúrí fún un, tí í ṣe ìṣọwọ́kọrin bàbá rẹ̀.[6]

Orin rẹ̀ àkọ́kọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2018, ó ṣe àgbéjáde orin àkọ́kọ́ rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ “Aiye”, èyí tó fún un ní òkíkí àti ìtẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ orin kíkọ. Orin náà sọ nípa ayé, àti bí ayé ṣe jẹ́, pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń gbé nínú rẹ̀. Lẹ́yìn orin gbajúmọ̀ yìí, ó ṣe àgbéjáde àwo-orin alákọ̀ọ́kọ́ rẹ̀, ìyẹn "Barry Back" ní ọdún 2020. Àwo-orin yìí ní àwọn orin bí i “Ashe She” àti “Ma So Pe” nínú. Àwo-orin yìí bákan náà ṣe àfihàn Davido, tó jẹ́ gbajúgbajà olórin ní Nàìjíríà.[7] Lẹ́yìn àwo-orin yìí, Barry Jhay tọwọ́ bọ ìwé àdẹ́hùn pẹ̀lú Cash Nation Entertainment. Bí ó ṣe di olókìkí sí, ó ní àǹfààní láti ṣe orin pẹ̀lú àwọn olórin bí i Bad Boy Timz, Rhaman Jago, Lyta, àti Jawton.[8] Pẹ̀lú àwo-orin àkọ́kọ́ yìí, Barry Jhay gba àmì-ẹ̀yẹ City People Music Award fún Best New Act àti Rookie of the Year ní The Headies ti ọdún 2019.[9]

Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Ayẹyẹ ìgbàmì-ẹ̀yẹ Ẹbùn Olùgbà Èsì Ìtọ́kasí
2018 City People Music Awards Best New Act of the Year Himself Gbàá [9]
Most Promising Act of the Year Wọ́n pèé
2019 The Headies Rookie of the Year Gbàá

Àtòjọ àwọn orin rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Ashe She
  • Only you
  • Olodo
  • Sokale
  • Ori
  • Japa
  • Muje
  • Solemuje
  • Aiye[10]
  • Kabiyesi
  • Barry Back (2020)
  • Son of God- EP (2022)
  • Party Boy Barry- EP(2023)
  • Barry Back 2-EP (2023)[11]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Onye, Harry (May 10, 2022). "Breaking Singer Barry Jhay's bio: age, father, net worth, music". https://www.kemifilani.ng/breaking-news/singer-barry-jhays-bio-age-father-net-worth-music. 
  2. Eve, Edwards. "Who is Barry Jhay? Nigerian singer's career explored". https://www.hitc.com/en-gb/2021/03/08/barry-jhay/. 
  3. Nasir Ahmed, Achile (21 July 2021). "Pioneering His Own Legacy Meet Barry Jhay, the Nigerian artist conveying moving messages capable of standing the test of time.". Audiomack. 
  4. Olonilua, Ademola (2021-03-08). "It’s painful I never met my grandpa, IK Dairo ― Barry Jhay". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-11-17. 
  5. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :2
  6. "Barry Jhay Reaffirms His Stance as A ‘Son Of God’ - Radr Africa". radrafrica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-03-07. Retrieved 2024-11-17. 
  7. admin (2021-01-21). "Barry Jhay Biography, Real Name, Age, Musics and Net Worth". Contents101 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-11-17. 
  8. Thabit, Khadijah (2022-05-10). "Singer Barry Jhay’s biography: age, father, net worth, music". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-11-17. 
  9. 9.0 9.1 Eve, Edwards. "Who is Barry Jhay? Nigerian singer's career explored". https://www.hitc.com/en-gb/2021/03/08/barry-jhay/. 
  10. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :1
  11. "Barry Jhay Profile and Discography | African Music Library". africanmusiclibrary.org. Retrieved 2024-11-17.