Jump to content

Deyemi Okanlawon

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Déyẹmí Ọ̀kánlàwọ́n
Ọjọ́ìbíAdéyẹmí Ọ̀kánlàwọ́n
Èkó, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Iṣẹ́Òṣèré orí-ìtàgé
Ìgbà iṣẹ́2010 – present
Websitedeyemitheactor.com

Déyẹmí Ọ̀kánlàwọ́n jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, oníṣẹ́ orí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán, ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó di ìlú-mọ̀ọ́ká látàrí ipa rẹ̀ tí ó kó nínú eré onípele ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Gidi Up tí wọ́n ṣàfihàn rẹ̀ lórí ẹrọ amóhù-máwòrán. Ò tún kópa nínú eré An African City, If Tomorrow Comes àti eré Road to Yesterday. Ó tún kópa nínú fọ́nrán àwo ori No be You ti Waje àti Soldier ti Falz.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀kánlàwọ́n ni wọ́n bí ní ìlú Èkó [2]. Wọ́n bí sí inú ẹbí òṣìṣẹ́ atún ọkò òfurufú kan ṣe tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adéyínká Ọ̀kánlàwọ́n. Déyẹmí lọ sílé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Taikenny Nursery and Primary School ní Ìpínlẹ̀ Èkó, ó lọ ilé-ẹ̀kọ́ International School, ní ìpínlẹ̀ Èkó. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì Èkó láti kọ́ nípa ìmọ̀. [2] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gba ìwé-ẹ̀rí nínú eré-oníṣe láti ilé-ẹ̀kọ́ New York Film Academy.[3]

Ọ̀kànlàwọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún márùn-ún níbi tí ó ti kópa nínú eré orí-ìtàgé ìparí ọdun nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.[4] Nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹsàn án Ó kòpa nínú ìpolówó orí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán pẹ̀lú Kunle Bamtefa. Lásìkò tí ó jẹ́ ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ní ọgbà Yunifásitì Ìpínlẹ̀ Èkó, ó tún dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eléré oníṣẹ́ ti Gf(x) (Harvesters Company), Xtreme Reaction and Snapshots (Covenant Christian Centre).[4]

Òkánlàwọ́n di ìlú-mòọ́ká nípa ip tí ó kó nínú eré ZR-7, ní ọdún 2010. [4] Ó tún kópa nínú eré A Grain of wheat. Lẹ́yìn èyí, ó tún kópa tí ó sì tún jẹ́ olùgbéré-jáde pẹ̀lú Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn mìíràn láti gbé àwọn eré ọlọ́kan-ò-jọkan jáde. Ní ọdún 2012 ó kópa nínú eré Blink àti Knock Knock ní dédé agogo mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́. Ní ọdún 2013, ó dojú kọ eré sinimá nìkan, tí ó sì ti kópa nínú eré tí ó ti tó àádọ́ta lẹ́yìn èyí, tí ó sì tún ti ṣe ìpolongo fún ilé iṣẹ́ ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ Globacom àti OLX. Ó ti bá Waje àti Arámidé ṣe fọ́nrán fídíò orin wọn. Ó tún ti kópa nínú eré "Beyond Blood". Ó kòpa nínú eré "If Tomorrow Never Comes" tí Joseph Benjamin àti Kehinde Bamkole ti kópa. [2] Ishaya Bako's Road To Yesterday starring Genevieve Nnaji and Majid Michel and Pascal Amanfo's No Man’s Land starring Adjetey Anang. He was in NdaniTV's series Gidi Up with OC Ukeje, Titilope Sonuga, Somkele Iyamah and Joke Silva.[5] àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn amì-ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó gba amì-ẹ̀yẹ òṣérékùnrin tó peregedé jùlọ nínú eré kúkúrú nínú In-Short film festival fún ipa rẹ̀ tí ó kó gẹ́gẹ́ bí " Ọkọ alárùn ọpọlọ" nínú eré Blink.[6]

Ọ̀kánlàwọ́n ṣe ìgbéyàwó ní ọjọ́ kíní ọdún 2013, wọ́n sì bímọ ní ọjọ́ Kẹwàá oṣù keje ọdún 2016.[4][7]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Àkòrí eré Ipa tí ó kó Adarí eré náà Notes
2010 ZR-7 Alabi Udoka & Olufemi Principal (Feature Film)
2010 Grain of Wheat Saviour Daniel & Ruyi Lead Role/Short Film
2011 Dependence Dayo Brian Wilson Lead/Short Film
2012 6:30PM Ghost Tonye Faloughi Short Film/Supporting Role
2012 Journey To Self Ex lover Tope Oshin-Ogun Feature Film alongside Ashionye Raccah, Katherine Obiang, Dakore Akande, Tina Mba and more
2012 Blink Husband Tolu Ajayi Lead Role/Short Film
2012 Gidi Up Season 1 Tokunbo Jade Osiberu Lead/Series
2013 Kpians: The Feast of Souls Eric Stanlee Ohikhuare Sub-Lead/Feature Film alongside Kiki Omeili and Ashionye Ugboh-Raccah
2013 +Kpians Premonition Eric Stanlee Ohikhuare Sub-Lead/Web
2013 Gidi Up II Tokunbo Jade Osiberu Lead/Series
2013 Oblivious Charles Stanlee Ohikhuare Feature Film
2014 Dowry I Demola Victor Sanchez Lead Role/Series
2014 Lekki Wives III Hassan Blessing Egbe Supporting Role/Series
2014 A Place Called Happy Dele LowlaDee Feature Film
2014 Perfect Imperfection Kanmi Ehizojie Ojesebholo Lead Role/Feature Film
2014 Friends and Lovers Frank Yemi Morafa Feature Film
2014 A Few Good Men Wale Ejiro Onobrakpor Feature Film featuring Joseph Benjamin
2014 Vanity's Last Game Justin Ehizojie Ojesebholo Feature Film
2015 Dowry II Demola Victor Sanchez Feature Film featuring Iretiola Doyle
2015 If Tomorrow Never Comes Kay Pascal Amanfo Feature Film featuring Yvonne Nelson
2015 Road To Yesterday Michael Ishaya Bako Feature Film featuring Majid Michel and Genevieve Nnaji
2015 All Of Me Chris Okey Ifeanyi Feature Film
2015 Undercover Lover Mr Roberts Okey Ifeanyi Feature Film
2016 Desperate Housegirls 2 & 3 Femi Sukanmi Adebayo & Akin-Tijani Supporting Role/Series
2016 Tobi Ha.foo.sa Niyi Akinmolayan Animated Series
2016 It's About Your Husband Kay Bunmi Ajakaiye Feature Film
2016 Madam Caitlyn Dr Sam - Feature film
2016 Asawana Sere Diminas Dagogo Feature Film
2016 Dinner - Jay Franklin Jituboh Feature Film featuring Iretiola Doyle and Richard Mofe Damijo
2017 The Royal Hibiscus Hotel
2019 Pandora's Box

Àwọn amì-ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Ayẹyẹ Amì-ẹ̀yẹ Ẹni tí ó gbàá Èsì
2013 In-Short Film Festival Best Actor in a Short Film - Supporting Role in an English language film (Married but Living Single) Deyemi Okanlawon (Blink) Gbàá
In-Short Film Festival Best Short Film Blink Wọ́n pèé
Africa Magic Viewer's Choice Awards (AMVCA) Best New Media Online Video Kpians Premonition Gbàá
AFRINOLLY Best Animation In Iredu Gbàá
2015 Best of Nollywood (BON) Awards Revelation of the Year Deyemi Okanlawon (If Tomorrow Never Comes) Gbàá
GMA Awards Best Actor, African Collaboration Deyemi Okanlawon (If Tomorrow Never Comes) Gbàá
2016 GMA Awards Best Actor, African Collaboration Deyemi Okanlawon (No Man's Land) Gbàá
GMA Awards Best Actor in a Drama Series Deyemi Okanlawon (An African City) Wọ́n pèé

Àwọn Ìtọ́ksí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Dimorkorkus, Stella (16 May 2016). "Actor, Deyemi Okanlawon Shows Versatility In Falz’s Short Film Musical, ‘Soldier’". SDK (Lagos, Nigeria). http://www.stelladimokokorkus.com/2016/05/actor-deyemi-okanlawon-shows.html. Retrieved 27 June 2016. 
  2. 2.0 2.1 2.2 Vitae, Style (19 February 2015). "DEYEMI OKANLAWON’S FIVE THINGS THIS WEEK". Style Vitae (Lagos, Nigeria). Archived from the original on 21 June 2016. https://web.archive.org/web/20160621150837/http://www.stylevitae.com/deyemi-okanlawons-five-things-this-week/. Retrieved 27 June 2016. 
  3. Izuzu, Chidumga (19 March 2016). "9 things you should know about talented actor". PulseNG (Lagos, Nigeria). Archived from the original on 25 October 2016. https://web.archive.org/web/20161025044950/http://pulse.ng/movies/deyemi-okanlawon-9-things-you-should-know-about-talented-actor-id4934890.html. Retrieved 24 October 2016. 
  4. 4.0 4.1 4.2 4.3 Izuzu, Chidumga (11 November 2014). ""My Wife is My Woman Crush Forever" - Deyemi Okanlawon". PulseNG (Lagos, Nigeria). Archived from the original on 16 August 2016. https://web.archive.org/web/20160816170405/http://pulse.ng/movies/pulse-exclusive-interview-my-wife-is-my-woman-crush-forever-deyemi-okanlawon-id3263934.html. Retrieved 27 June 2016. 
  5. Gidi cast on The Juice, Ndanitv, Retrieved 6 October 2016.
  6. Ibaka, TV (16 May 2016). "Adeyemi Okanlawon". IbakaTV.com. Lagos, Nigeria. Archived from the original on 2 January 2017. Retrieved 27 June 2016. 
  7. Showemimo, Adedayo (12 July 2016). "Nollywood actor, Deyemi Okanlawon welcomes first child". TheNetNG (Lagos, Nigeria). http://thenet.ng/2016/07/nollywood-actor-deyemi-okanlawon-welcomes-first-child/. Retrieved 26 July 2016. 

Àdàkọ:Authority control