Jump to content

Joaquin Phoenix

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Joaquin Phoenix
Ọjọ́ìbíJoaquin Rafael Bottom
28 Oṣù Kẹ̀wá 1974 (1974-10-28) (ọmọ ọdún 49)
San Juan, Puerto Rico
IbùgbéLos Angeles, California, U.S.
Orílẹ̀-èdèAmerican
Orúkọ mírànLeaf Phoenix
Iṣẹ́
  • Actor
  • producer
Ìgbà iṣẹ́1982–present
WorksFull list
Alábàálòpọ̀Rooney Mara (2016–present)
Parent(s)
Àwọn olùbátanRiver Phoenix (brother)
Rain Phoenix (sister)
Liberty Phoenix (sister)
Summer Phoenix (sister)
AwardsFull list

Joaquin Rafael Phoenix[lower-alpha 1] ( /hwɑːˈkn/; né Bottom; tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1984 (October 28, 1974) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò àti olóòtú ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà Ó ti gba ẹgbẹlẹmùkú àmìn ẹ̀yẹ nínú iṣẹ́ rẹ̀, pàápàá jùlọ àmìn ẹ̀yẹ BAFTA Award, a Grammy Award, Golden Globe Awards méjì, Screen Actors Guild Award, wọ́n sìn yàn án fún àmìn ẹ̀yẹ Academy Awards nígbà mẹ́rin.

Phoenix bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré sinimá àgbéléwò lórí ẹ̀rọ tẹlifíṣàn pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, River àti Summer. Ipa gbòógì àkọ́kọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré sinimá ni nínú sinimá SpaceCamp lọ́dún (1986). Ní àkókò náà, ó sọ ara rẹ̀ ní Leaf Phoenix. Nígbà tí ó ṣe fẹ̀ẹ̀rẹ̀, ó tún lọ ṣe ìyípadà sí orúkọ àbísọ rẹ̀. Ó sìn gba lámèyítọ́ tó dára nínú sinimá aláwàdà rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ To Die For lọ́dún (1995) àti sinimá mìíràn tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Quills lọ́dún (2000). Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbajúmọ̀ si nígbà tí ó kópa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ìtàn tí wọ́n pè ní Commodus nínú sinimá tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Gladiator lọ́dún (2000), ó gba àmìn ẹ̀yẹ Academy Award for Best Supporting Actor fún sinimá yìí. Bẹ́ẹ̀ náà wọ́n yàn án fún àmìn ẹ̀yẹ Best Actor fún ipa tó kó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ìtàn olórin Johnny Cash nínú Walk the Line lọ́dún (2005), ọ̀mùtí ajagun fẹ̀hìntì nínú sinimá The Master lọ́dún (2012), nínú èyí tí ó ti gba àmìn ẹ̀yẹ ti Volpi Cup for Best Actor, àti the title characterJoker lọ́dún (2019). Àwọn fíìmù rẹ̀ mìíràn ni; Signs (2002) àti The Village (2004), gbajúmọ̀ sinimá nì Hotel Rwanda lọ́dún (2004), sinimá olólùfẹ́ Her lọ́dún (2013), Inherent Vice lọ́dún (2014), àti You Were Never Really Here lọ́dún (2017), èyí tí ó fi gba àmìn ẹ̀yẹ Cannes Film Festival Award for Best Actor.

Phoenix máa ń ṣiṣẹ́ olóòtú, olùdarí sinimá àgbéléwò àti tẹlifíṣàn. Ó sìn gba àmìn ẹ̀yẹ Grammy Award for Best Compilation Soundtrack for Visual Media lórí Walk the Line.[3][4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "PREMIERE April 1988". Aleka.org. Retrieved August 24, 2010. 
  2. "Joaquin Phoenix". Hello!. http://www.hellomagazine.com/profiles/joaquin-phoenix/. Retrieved June 17, 2017. 
  3. "Joaquin Phoenix's Charity Work". Look to the Stars. Archived from the original on June 14, 2012. Retrieved August 22, 2007. 
  4. "Fake leather please!". Daily News and Analysis. November 14, 2006. http://www.dnaindia.com/entertainment/report_fake-leather-please_1064075. Retrieved December 1, 2012. 


Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tags exist for a group named "lower-alpha", but no corresponding <references group="lower-alpha"/> tag was found