Kizz Daniel
Kizz Daniel | |
---|---|
A portrait of Kizz Daniel | |
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Oluwatobiloba Daniel Anidugbe |
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | Vado |
Ọjọ́ìbí | Ogun State, Nigeria |
Irú orin |
|
Occupation(s) |
|
Years active | 2014-Present |
Labels |
|
Associated acts |
Oluwatobiloba Daniel Anidugbe, tí àwọn ènìyàn tún mọ̀ sí orúkọ ìtàgé rẹ̀ Kizz Daniel, jẹ́ olórin àti a-kọ-orin ti ile nijiria Ó gbajúgbajà fún àwọn orin rẹ̀ "Woju" ati "Yeba". Orúkọ ìtàgé Kiss Daniel ni ó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ kí ó tó yí i dà ní oṣù karùn-ún, ọdún 2018. Ó bọwọ́lùwe àdéhùn iṣẹ́ pẹ̀lú G-Worldwide Entertainment ní ọdún 2013, ṣùgbọ́n ó fi ilé-iṣẹ́ orin náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìjà lórí àdéhùn tí kì í ṣe gbòńkẹ́lẹ́ àti ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́. Ó dá ilé-iṣẹ́ orin Fly Boy Inc record label sílẹ̀ ní oṣù kọkànlá, ọdún 2017.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbésí-ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Kizz Daniel gẹ́gẹ́ bí i Olúwatóbilọ́ba Daniel Anidugbe ní Abẹ́òkúta , Ìpínlẹ̀ Ògùn , Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ ìjọba ìbílẹ̀ Abeokuta North.
Ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama Abeokuta Grammar School, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Federal University of Agriculture, Abeokuta, ní ọdún 2013, pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí ní Water Resources Management and Agrometeorology.[1] Ní ìgbà tí ó ṣì wà ní Yunifásítì, ó pinnu láti máa lé iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ rẹ̀ papọ̀. [2]
Ìgbé ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kìíní, oṣù karùn-ún, ọdún 2021, ó bí àwọn ìbẹẹ̀ta , Jamal, Jalil àti Jelani, pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ .[3] Kizz sọ lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ bí ó ṣe pàdánù ọ̀kan nínú àwọn ìbẹẹ̀ta rẹ̀, Jamal, ní ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn ọjọ́ tí ó bí wọn bí ó ṣe ra ilé oníyàrá méjì kọ̀ọ̀kan fún Jalil àti Jelani.[4][5]
Iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní oṣù karùn-ún, ọdún 2015, Kizz Daniel láfarabara fi orin kẹta léde tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní, “Laye,” ní ọjọ́ tí ó jẹ́ ọjọ́ ìbí rẹ̀, pẹ̀lú fọ́nrán tí AJE FILMS darí, tí wọ́n yà ní oríṣìíríṣìí ibi ní ìlà-oòrùn Áfíríkà lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí orin náà jáde.
Daniel fi àwo orin rẹ̀ kìíní tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní New Era léde ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù karùn-ún, ọdún, 2016. Lẹ́yìn tí ó fi ilé iṣẹ́ orin tí ó ń bá ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, G-WorldWide, ó lọ dá tirẹ̀ sílẹ̀ FLYBOY I.N.C. tí ó sì gba àwọn olórin tuntun méjì wọlé láìpẹ́ yìí, Demmie Vee àti Philkeyz. Lẹ́yìn èyí ni Kizz Daniel kọ nínú orin Demmie Vee single tí wọ́n pè ní "You Go Wait?".[6] 2018 jẹ́ ọdún tí ó da fún olórin tí ó kọ WOJU, ó pe Wizkid sí orin tí ó gbalégbako "FOR YOU"[7] àti Davido sí orin mìíràn "One Ticket" tí ó gún òkè lorí àtẹ láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún tí wọ́n fi léde. Ní ọjọ́ ọgbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2018, Kizz Daniel fi àwo-orin rẹ̀ kejì léde, èyí tí ó jẹ́ èkíní rẹ̀ lábẹ́ ilé-iṣẹ́ orin FlyBoy Inc tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní "No Bad Songz". Àwo-orin náà ní orin ogún nínú pẹ̀lú èyí tí ó fi fi léde tẹ́lẹ̀, One Ticket, tí ó kọ pẹ̀lú Davido. Àwọn olórin mìíràn tí ó kọrin pẹ̀lú nínú Àwo-orin náà ni Nasty C, Diamond Platiumz, Philkeyz, Demmie Vee, Dj Xclusive, Wretch 32, Diplo àti Sarkodie. Àwo-orin yìí gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ì-gbóríyìn-fún lọ́dọ̀ àwọn olólùfẹ́ orin, ó gba ipò 55 ní orí US iTunes Chart ó sì gba ipò kìíní lórí àtẹ̀ àwo-orin lágbàáyé láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún tí wọ́n fi léde. Ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹfà, ọdún, ó fi àwo-orin rẹ̀ kẹta 'King of Love'[8][9]léde
Ní 2017, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ni wọ́n rò pé ó máa pàrọ̀ iṣẹ́ sí iṣẹ́ adẹ́rìn-ín-pòṣónú nítorí pé ó ń fi àwọn fọ́nrán apanilẹ́rìn-ín léde. Ṣùgbọ́n ṣá, ó sọ pé òun ò ní èrò láti pàrọ̀ iṣẹ́ sí iṣẹ́ adẹ́rìn-ín-pòṣónú nítorí iṣẹ́ orin gan-an ni ẹ̀bùn òun. [10]
Ìjà ilé-iṣẹ́ orin àti orúkọ yíyídà.
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní oṣù kọkànlá 2017, Kizz Daniel kéde ìpínyà rẹ̀ kúrò lábẹ́ ilé-iṣẹ́ orin, G-Worldwide, ó sì dá ilé-iṣẹ́ orin tirẹ̀ sílẹ̀ tí ó pe ní FLYBOY I.N.C.[11] Àwọn ilé-iṣẹ́ orin ti tẹ́lẹ̀ gbé e lọ ilé-ẹjọ́ ṣùgbọ́n kò jẹ̀bi ọ̀kankan nínú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.[12] [13]
Ní oṣù karùn-ún 2018, Kizz Daniel kéde pé òun ti yí orúkọ ìtàgé òun kúrò láti Kiss Daniel sí Kizz Daniel, orúkọ èyí tí ó farahàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní orí àwọn ẹ̀rọ ìbánidọ̀ọ̀rẹ́ rẹ̀. Spotify tuntun àti Apple Music accounts di ṣíṣí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pẹ̀lú orúkọ Kizz Daniel, àti àwọn orin rẹ̀ tuntun.[14][15]
Ní oṣù kẹfà 2018, ilé-iṣẹ́ orin ti tẹ́lẹ̀ tí Kizz Daniel wà lábẹ́ wọn, G-Worldwide gbìyànjú láti ní àṣẹ sí orúkọ “Kizz Daniel”, wọ́n sì tún gba olórin yìí níyànjú láti dẹ́kun lílo orúkọ yìí Àbí kí ó fojú winá òfin nínú àtẹ̀jáde ìròyìn tí wọ́n fi ṣọwọ́ sí àwọn ilé ìròyìn. Ní oṣù kẹwàá 2018, Daniel fèsì sí ìwé ìpẹ̀jọ́ àti ọ̀rọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ G-Worldwide láti ẹnu agbẹjẹ́rò tirẹ̀.[16]
Discography
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àtòjọ orin rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwo-orin/EP
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Altòjọ àwọn amì-èyẹ tó ti gbà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Event | Prize | Result | Ref |
---|---|---|---|---|
2015 | The Headies | Yàán | [20] | |
Nigeria Entertainment Award | Gbàá | [21] | ||
City People Entertainment | Yàán | [22] | ||
Yàán | ||||
2016 | MTV Africa Music Award | Yàán | [23] | |
Nigeria Entertainment Award | Gbàá | [24] | ||
Gbàá | ||||
City People Music Award | Gbàá | [25] | ||
Yàán | [26] | |||
The Headies | Gbàá | [27][28] | ||
Gbàá | ||||
Yàán | ||||
Gbàá | ||||
2017 | The Future Awards Africa | Yàán | [29] | |
Nigeria Entertainment Award | Yàán | |||
2018 | The Headies | style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé | [30] | |
style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé | ||||
style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé | ||||
style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé |
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "5 interesting facts about the singer". www.pulse.ng. 2017-12-06. Retrieved 2019-05-07.
- ↑ Akan, Joey. "Kiss Daniel: 10 things you don"t know about "Woju" singer". http://www.pulse.ng/entertainment/music/kiss-daniel-10-things-you-dont-know-about-woju-singer-id3507573.html.
- ↑ Omotayo (2021-05-01). "Nigerian singer, Kizz Daniel welcomes a set of twins on his birthday". FreshPopMusic (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-07-24. Retrieved 2021-07-24.
- ↑ Omotayo (2021-07-15). "Kizz Daniel reveals how he lost one of his triplets, buys penthouses for Jalil & Jelani". FreshPopMusic (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-07-24. Retrieved 2021-07-24.
- ↑ Emmanuel (2021-07-16). "One Of The Triplets Of Kizz Daniel Is Dead, He Confirms" (in en). Archived from the original on 2021-07-27. https://web.archive.org/web/20210727074950/https://candytv.ng/one-of-the-triplets-of-kizz-daniel-is-died-he-confirms/.
- ↑ "Demmie Vee ft. Kizz Daniel – You Go Wait?". https://www.mp3bullet.ng/demmie-vee-ft-kizz-daniel-you-go-wait-mp3.
- ↑ "Kizz Daniel ft Wizkid - For You". https://www.mp3bullet.ng/kizz-daniel-x-wizkid-for-you-prod-philkeyz-music.
- ↑ Alake, Motolani (June 26, 2020). "Kizz Daniel releases new album, 'King of Love'". Pulse Ng. Retrieved July 4, 2020.
- ↑ Omotayo (2020-06-04). "Kizz Daniel's King of Love album is dropping June 25 - See Tracklist". FreshPopMusic (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-07-24. Retrieved 2021-07-24.
- ↑ "My comedy skits are strategic –Kiss Daniel". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 15 October 2017. Retrieved 2021-02-26.
- ↑ "Kiss Daniel Leaves G-Worldwide Label - PM NEWS Nigeria". PM NEWS Nigeria. 2017-11-13. https://www.pmnewsnigeria.com/2017/11/13/kiss-daniel-leaves-g-worldwide-label/.
- ↑ "Breaking News & Top Stories | Pulse Nigeria". /entertainment/music/kiss-daniel-g-worldwide-full-story-id7707718.html
- ↑ "G-Worldwide drags Kiss Daniel to court". Punch Newspapers. http://www.punchng.com/g-worldwide-drags-kiss-daniel-to-court/.
- ↑ "Nigerian musician, Kiss Daniel changes stage name - Daily Post Nigeria". Daily Post Nigeria. 2018-05-22. http://dailypost.ng/2018/05/22/nigerian-musician-kiss-daniel-changes-stage-name/.
- ↑ "Kiss Daniel changes name to Kizz Daniel - BellaNaija". www.bellanaija.com. 22 May 2018. Retrieved 2018-07-03.
- ↑ Uche, Prinx (October 27, 2019). "Kizz Daniel Fires Back At G-Worldwide Record Label". Luvmp. Archived from the original on September 24, 2021. Retrieved April 30, 2022.
- ↑ "Kizz Daniel - No Bad Songz Album - TrendyBeatz.com". Trendybeatz.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì).
- ↑ "DOWNLOAD Kizz Daniel set to drop new album, 'King of Love' tomorrow, releases tracklist". Yahiphop.com. 2020-06-24. Archived from the original on 2020-06-25. Retrieved 2020-06-25.
- ↑ "Kizz Daniel drops new EP "Barnabas" - P.M. News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-21.
- ↑ "Breaking: Wizkid, Olamide, Praiz, others nominated for #TheHeadies2015!". Vanguard News. 2015-09-30. https://www.vanguardngr.com/2015/09/breaking-wizkid-olamide-praiz-others-nominated-for-theheadies2015/.
- ↑ "The Nigeria Entertainment Awards Announce 2015 Nominees". OkayAfrica. 2015-06-15. http://www.okayafrica.com/nigeria-entertainment-awards-nominees-2015/.
- ↑ "City People Awards 2015 Nominees List". TooXclusive. 2015-07-13. Archived from the original on 2018-07-03. https://web.archive.org/web/20180703220212/http://tooxclusive.com/news/city-people-awards-2015-nominees-list/90246.html.
- ↑ "Here's the Full List of Nominees at the 2016 MTV Africa Music Awards in Johannesburg". OkayAfrica. 2016-10-22. http://www.okayafrica.com/mtv-africa-music-awards-2016-nominees-mtvmama2016/.
- ↑ Solanke, Abiola. "NEA 2016: Adekunle Gold, Olamide, Kiss Daniel, others win big". http://www.pulse.ng/buzz/nea-2016-adekunle-gold-olamide-kiss-daniel-others-win-big-id5460429.html.
- ↑ "Full List Of Winners at 2016 City People Entertainment Awards - Nigerian Entertainment Today". Nigerian Entertainment Today. 2016-07-26. http://thenet.ng/full-list-of-winners-at-2016-city-people-entertainment-awards/.
- ↑ Solanke, Abiola. "City People Entertainment Awards 2016: Olamide, Falz, Phyno, Tiwa Savage lead nomination pack". Archived from the original on 2018-07-03. https://web.archive.org/web/20180703220338/http://www.pulse.ng/buzz/city-people-entertainment-awards-2016-olamide-falz-phyno-tiwa-savage-lead-nomination-pack-id5233745.html.
- ↑ "Full list of Headies 2016 winners - Vanguard News". Vanguard News. 2016-12-23. https://www.vanguardngr.com/2016/12/full-list-headies-2016-winners/.
- ↑ "The Headies Awards 2016: Complete list of Nominees - INFORMATION NIGERIA". INFORMATION NIGERIA. 2016-11-09. http://www.informationng.com/2016/11/headies-awards-2016-complete-list-nominees.html.
- ↑ "The Future Awards Africa 2017 Nominees Profiles - The Future Awards Africa". The Future Awards Africa. 2017-11-24. http://thefutureafrica.com/awards/future-awards-africa-2017-nominees-profiles/.
- ↑ Ohunyon, Ehis. "The nominees list for the 2018 Headies is out!". Archived from the original on 2018-07-11. https://web.archive.org/web/20180711225320/https://www.pulse.ng/entertainment/music/headies-2018-nominees-list-id8247089.html.