Kofoworola Ademola
Kòfowórọlá Adémọ́lá | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Kòfowórọlá Àìná Moore ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù karùn-ún, ọdún 1913 Èkó, Nàìjíríà |
Aláìsí | 15 May 2002 | (ọmọ ọdún 88)
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà àti Bìrìtìkó |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Ilé-ìwé CMS Girl's School, Èkó Vassar College Oxford University |
Iṣẹ́ | Olùkọ́, Oǹkọ̀wẹ́ |
Gbajúmọ̀ fún | obìnrin adúláwọ̀ àkọ́kọ́ tí ó kàwé gboyè dìgírì ní Oxford University, ìkàwé ọmọbìnrin lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. |
Olólùfẹ́ |
|
Àwọn ọmọ | 5 [1] |
Àwọn olùbátan | Oyinkansola Abayomi,
Lady Abayomi (cousin) Oloori Charlotte Obasa (aunt) |
Olorì Kòfowórọlá Adémọ́lá tí a tún mọ̀ sí Kòfowórọlá Aina Adémọ́lá àti Arábìnrin Adémọ́lá tí ó gboyè Order of the British Empire, (MBE), MFR, OFR ni wọ́n bí lọ́jọ́ kọkànlélógún oṣù karùn-ún ọdún 1913, tí ó sìn kú lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù karùn-ún ọdún 2002 jẹ́ olùkọ́ ọmọ Nàìjíríà [2] òun ni Ààrẹ àkókò ti àjọ ẹgbẹ́ obìnrin, National Council of Women Societies lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òun náà sìn ni adarí ẹgbẹ́ obìnrin náà láti ọdún 1958 sí 1964.[3] Òun ni obìnrin adúláwọ̀ àkọ́kọ́ tí ó kàwé gboyè dìgírì ní Oxford University[4][2] bákan náà, ó jẹ́ oǹkọ̀wẹ́ àwọn ọmọdé.[5]
Ìgbé-ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí kòfó sí ẹbí amọ̀fin àti ọmọba Eric Ọláwọ̀lú Moore ti ìlú Ẹ̀gbá,[6] pẹ̀lú aya rẹ̀, Aida Arabella, tí ó jẹ́ ọmọ Scipio Vaughan àti ìran Cherokee.[7][8] Ó jẹ́ ìbátan Oyinkánsọ́lá Àbáyọ̀mí àti Olorì Charlotte Ọbasá.[9] Ó lo ìdajì ìgbé-ayé rẹ̀ ní Èkó àti ìlàjì tó kù ní United Kingdom.[10] Adémọ́lá kàwé ní ilé-ìwé àwọn obìnrin C.M.S. Girls School, ní ìlú Èkó; Vassar College, ní New York;[11] Portway College, ní ìlú Reading, àti St. Hugh's College, ní Oxford láti ọdún 1931 sí 1935. Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí dìgírì nínú ìmọ̀ olùkọ́ni àti èdè Gèésì ní Yunifásítì Oxford, nígbà tí ó wà ní Oxford, ó kọ̀wé ìtàn olójú-ewé mọ́kànlélógún nípa ìgbé-ayé Margery Perham láti ṣe àtakò àṣìkọ ìwé ìtàn àwọn òyìnbó nípa Áfíríkà, ó kọ nípa ìtàn ìgbà èwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí í àmúlùmálà àṣà ìbílẹ̀ àti òkèèrè.[10]
Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé kò sọ nípa ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà tí wọ́n hù sí í nígbà tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Gèésì, ṣùgbọ́n, ó fi ìbínú àwọn ìwà yìí hàn nígbà tí wọ́n bú u ní oríṣiríṣi èébú ẹlẹ́yàmẹ̀yà.[12] Kòfowórọlá padà sí Nàìjíríà lọ́dún 1935 tí ó sìn gba iṣẹ́ olùkọ́ ní ilé-ìwé Queens College ní ìlú Èkó. Nígbà tó wà ní Èkó, ó kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ́ obìnrin pàápàá jùlọ YWCA.
Lọ́dún 1939, ó fẹ́ ọmọba Adétòkunbọ̀ Adémọ́lá, òṣìṣẹ́ ìjọba lọ́kọ, wọ́n sìn bímọ márùn-ún [1] Gẹ́gẹ́ bí ìyàwó ọmọba nílẹ̀ Yorùbá, ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìgbé-ayé Olorì, àti pàṣẹ, òun fún ara rẹ̀ jẹ́ ọmọba, ṣùgbọ́n nítorí pé ọkọ rẹ̀ jẹ́ alàgbà ìjọ, ló fà á tí wọ́n fi ń pè é ní Ìyáàfin Adémọ́lá, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ ọ́ sí.
Nígbà tó yá, iṣẹ́ gbé ọkọ rẹ̀ lọ sí ìlú Warri àti Ìbàdàn, gbogbo àwọn ìlú wọ̀nyí ni Kòfowórọlá tí jọ ní àjọṣe pọ̀ tó lóòrì pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ obìnrin. [13]
Wọ́n ṣe àtẹ̀jáde ìwé-ìtàn ìgbésí-ayé Kòfowórọlá Adémọ́lá àti àwòrán Gbemi Rosiji tí wọ́n pè ní Portrait of a Pioneer lọ́dún 1996.[14]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 Kayode Soyinka (February 12, 1993). "Sir Adetokunbo Ademola". United Kingdom: The Independent. https://www.independent.co.uk/news/people/obituary-sir-adetokunbo-ademola-1472554.html.
- ↑ 2.0 2.1 Lisa A. Lindsay; John Wood Sweet (2013). Biography and the Black Atlantic (The Early Modern Americas). University of Pennsylvania Press. p. 198. ISBN 978-0-8122-454-62. https://books.google.com/books?id=XVf7AAAAQBAJ&pg=PA198&dq=.
- ↑ Jubril Olabode Aka (2012). Nigerian Women of Distinction, Honour and Exemplary Presidential Qualities: Equal Opportunities for All Genders (White, Black Or Coloured People). Trafford Publishing. p. 50. ISBN 978-1-46-6915-5-41.
- ↑ "Lady Ademola". Bookcraft. Retrieved August 3, 2016.
- ↑ Pamela Roberts (2014). Black Oxford: The Untold Stories of Oxford University's Black Scholars. Andrews UK Limited. ISBN 978-1-909-9301-48. https://books.google.com/books?id=KrvABQAAQBAJ&pg=PT37&dq=.
- ↑ "Meet Kofoworola Ademola, First African Woman To Graduate From Oxford University". Hope for Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-10-31. Retrieved 2020-05-30.
- ↑ Horace Mann Bond (1972). Black American scholars: a study of their beginnings. University of Minnesota (Balamp Pub). p. 46. https://books.google.com/books?id=DlOuImoHAggC&q=.
- ↑ Lindsay; Sweet (2013). Biography and the Black Atlantic. p. 203. https://books.google.com/books?id=FdJAAQAAQBAJ&pg=PA201&lpg=PA201&dq=.
- ↑ George 2014, p. 1898.
- ↑ 10.0 10.1 George 2014, p. 1899.
- ↑ Ann Short Chirhart; Kathleen Ann Clark (2014). Georgia Women: Their Lives and Times, (Volume 2 Book collections on Project MUSE. 2. University of Georgia Press. p. 306. ISBN 978-0-820-3378-45. https://books.google.com/books?id=cTGlAwAAQBAJ&pg=PA306&dq=.
- ↑ Umoren, Imaobong (2 October 2015). "Kofoworola Moore at the University of Oxford". www.torch.ox.ac.uk (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). University of Oxford. Retrieved 24 December 2017.
- ↑ Ojewusi 1996, p. 276.
- ↑ Gbemi Rosiji, Portrait of a Pioneer: The Authorized Biography of Lady Kofoworola Aina Ademola, MBE, OFR (2nd edn Macmillan Nigeria, 2000). ISBN 9789783212855.