Àtòjọ àwọn òrìṣà Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti List of Yoruba deities)
Jump to navigation Jump to search

Àwọn wọ̀nyí ni àwòn Òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá.

Òrìṣà tó ga jù[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọlọ́run Elédùmarè ní orúkọ mẹ́ta tí Yorùbá má ń pèé, àwọn ni:

 • Elédùmarè - Olùṣèdá ohun gbogbo.
 • Ọlọ́run - Olù kápá ọ̀run.
 • Ọlọ́fin - Olù sààmì láàrín ọ̀run àti  Ayé

[1]

Àwọn òrìṣà tó níiṣe pẹ̀lú ìpín[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 • Ọ̀rúnmìlà -  Ó jẹ́ òrìṣà ọlọ́gbọ́n, ìpín, àti arínú róde.
 • Orí - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó rọ̀ mọ́ ìṣèdá tàbí ìpín

 Àwọn Òrìṣà Imọlẹ̀ tí ó jẹ́ akọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]


 • Ọbalú Ayé - Ó jẹ́ òrìṣ̀à tí ó rọ̀ mọ́ àjàkálẹ̀ àrùn tí ó sì tún ma ń ṣe ìwòsan àjàkálẹ̀ àrùn.
 • Erinlẹ̀ - Ó jẹ́ òrìṣà ìwòsàn, ó sì tún ma ń ṣe ìwòsàn àrùn. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó ma ń mú ìtura bá ènìyàn
 • Èṣ̣ù - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ń gbé oríta, ó jẹ́ òrìṣà ẹlẹ̀tàn, tí ó sì ma ń ṣeni ní jàmbá
 • Ìbejì - Ó jẹ́ òrìṣà àwọn ọmọ méjì  tí a bí papọ̀, ó ma ń fúni lọ́mọ.
 • Kokou - Ó jẹ́ òrìṣà oní jàgídí-jàgan
 • Ọbàtálá - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó mọ orí àti gbogbo ara tó kù fún ọmó ènìyàn. Ó jẹ́ òrìṣà ìmọ́lẹ̀, ó sì tún jẹ́ òrìṣà tí ó mọ́ kangá tí ó sì ma ń ṣe déédé
 • Odùduwà - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ṣẹ àwọn ọmọ Yorùbá kalẹ̀ sí ilé Ifẹ̀
 • Ògún - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó rọ̀ mọ́ irin tàbí àgbẹ̀dẹ. Ó sì tún jẹ́ jagun jagun nígbà ayé rẹ̀
 • Òrìṣà Oko - Ó jẹ́ òrìṣà tí Yorùbá ma ń lò láti fi ṣètò ohun ọ̀gbìn
 • Ọ̀sanyìn - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ma ń ṣòfófó fúni. ó lè gbé inú ilé tàbí inú oko
 • Òṣùmàrè - Ó jẹ́ òrìṣà tó dàbí ejò tí ó ma ń ta àwọn àwọ̀ oríṣi méje sí ojú ọ̀run
 • Ọ̀ṣọ́ọ̀sì - Ó jẹ́ òrìṣà tí  wọ́n fi ń dẹ ọdẹ tàbí ro oko
 • Ṣàngó, Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ma ń sán àrá látojú ọ̀run

 Àwọn Òrìṣà Yorùbá tí ó jẹ́ abo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 • ́Àjà - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ń gbé inú igbó tàbí aginjù, kò yàtọ̀ sí iwin, ó sì ma ń ṣe ìwòsàn.
 • Ajé Olókun - Ó jẹ́ òrìṣà omi tí ó ma ń ṣ̀àánú ènìyàn pẹ̀lú ọrọ̀.
 • Ẹ̀fúùfù - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó níkàpá lórí ìjì tàbí atẹ́gùn.
 • Mawu - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó níkàpá lórí Òòrùn àti Òṣup̀á.
 • Ọ̀bà - Òrìṣà yí jẹ́ ìyàwó Ṣ̀àngó àkọ́kọ́ tí ó di omi
 • Olókun - Ó jẹ́ òrìṣà omi.
 • Ọ̀ṣun - Òrìṣà  yí jẹ́ òrìṣà omi, tí o ́ní ṣe pẹ̀lú ìfé, ẹwà, àti owó.
 • Ọya - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ní agbára láti dá ìjì, mọ̀nàmọ́ná, fífúni lówó, àti idán fún ọmọ́ ènìyàn
 • Yemọja - Ó jẹ́ òrìṣà olú-odò tí ó ní agbára púpọ̀.

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "Awon asa ati orisa ile Yoruba in SearchWorks catalog". SearchWorks catalog. 2019-06-15. Retrieved 2019-07-02.