Jump to content

Oúnjẹ Ugali

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ugali
Alternative namesPosho, nsima, akume, Ewokple, akple, amawe
Typestaple
Region or stateWest Africa, East Africa and parts of Southern Africa
Associated national cuisineKenya, Tanzania
Main ingredientsMaize meal (also known as mielie meal, or ground white maize)
Similar dishes
Àdàkọ:Wikibooks-inline 

Ugali, èyí tí a tún mọ̀ sí posho, nsima, papa, pap, sadza, isitshwala, akume, amawe, ewokple, akple, àti àwọn onírúurú oúnjẹ, ó jẹ́ oúnjẹ tí a ṣe láti ara àgbàdo tàbí ìyẹ̀fun àgbàdo ní àwọn ní àwọn onírúurú orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń bẹ ní ilẹ̀ Áfíríkà bíi: Kenya, Uganda, Tanzania, Zimbabwe, Zambia, Lesotho, Eswatini, Angola, Mozambique, Namibia, Democratic Republic of the Congo, Malawi, Botswana àti South Africa, àti ní ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà ní àárín ẹ̀yà Ewe tí wọ́n ń bẹ ní Togo, Ghana, Benin, Nàìjíríà àti Cote D'Ivoire. [1] A máa ń sè é nínú omi gbígbóná tàbí mílìkì títí tí ó fi máa dì léraléra.[2] Ní ọdún 2017, ní àjọ UNESCO to oúnjẹ yìí mọ́ ara àwọn oúnjẹ tí ó ń ṣojú àṣà tí ó sì tún ń gbé àṣà lárugẹ.[3]

Malawian children eating nsima, ndiwo, and masamba
Ugali with beef and sauce

Oúnjẹ yìí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ káàkiri àwọn ilẹ̀ Áfíríkà, níbi tí wọ́n ti fún un ní onírúurú orúkọ:

Bí orúkọ yìí ṣe wáyé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀rọ̀ ugali jẹ́ èdè ilẹ̀ Áfíríkà èyí tí yọ láti inú èdè Swahili; ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n mọ̀ ọ́n sí nsima nínú èdè àwọn ará Malawi bíi Chichewa àti Chitumbuka. Ní àwọn apá kan ní Kenya, wọ́n tún máa ń pe oúnjẹ yìí ní sembe tàbí ugali. Ní Zimbabwe wọ́n mọ oúnjẹ yìí sí sadzaChishona tàbí isitshwalaNdebele [13] Orúkọ àwọn Áfíríkà ẹ̀kọ́ (mielie) wá láti inú èdè Dutch, níbi tí ó ti túmọ̀ sí "(àgbàdo) àsáró".

Yawo women preparing ugali for a large gathering

Wọ́n mú Ugali wá sí ilẹ̀ Áfíríkà ní kété tí àwọn Portuguese mú àgbàdo wá. Wọ́n mú àgbàdo wá sí ilẹ̀ Áfíríkà láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà láàrin sẹ́ntúrì kẹrìn-dín-lógún sí ìkẹtà-dín-lógún. Ṣáájú àkókò yìí, sorghum àti jéró ni wọ́n gbajúmọ̀ káàkiri gbogbo Sub-Saharan Africa. Àwọn àgbẹ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà gba àgbàdo wọlé torí bí a ṣe ń gbìn ín papọ̀ mọ́ ti sorghum tí ó sì máa ń so púpọ̀. Ní nǹkan bíi ogún sẹ́ntúrì ni àgbàdo gba ipò mọ́ sorghum lọ́wọ́.[14]Malawi, wọ́n máa ń pe ìpèdè kan pé 'chimanga ndi moyo' èyí tí ó túmọ̀ sí pé 'àgbàdo layé'.[15] Nshima/nsima nígbà mìíràn jẹ́ ohun tí a le ṣe láti ara ìyẹ̀fun sorghum bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe gbogbo ìgbà. Ẹ̀gẹ́, èyí tí àwọn ará ilẹ̀ Amẹ́ríkà mú wá náà jẹ́ èyí tí a le fi ṣe nshima/nsima, nínú kí á ṣe é lásán tàbí kí á dà á mọ́ ìyẹ̀fun àgbàdo. Ní Malawi wọ́n máa ń ṣe nsima láti ara ẹ̀gẹ́ (chinangwa), bí ìkórè àgbàdo kò bá tó nǹkankan, nsima tí a fi ẹ̀gẹ́ ṣe ni ó má wà káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè náà. [16]

Ugali (nígbà tí a bá sè é gẹ́gẹ́ bíi àsáró, a máa ń pè é ní uji) wọ́n máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú ànàmọ́, ọ̀gẹ̀dẹ̀ pípọ́n, ànàmọ́ Irish àti búrẹ́dì. Òkèlè ugali jẹ́ èyí tí a sáábà máa ń jẹ pẹ̀lú ẹ̀fọ́, ọbẹ̀ tàbí sukuma-wiki (èyí tí a mọ̀ sí collard greens).[17] Bí a bá ṣe Ugali láti ara ohun èlò mìíràn, wọ́n sáábà máa ń fún un ní orúkọ irúfẹ́ agbègbè bẹ́ẹ̀.[18]

Àṣà bí a ṣe ń jẹ ugali gẹ́gẹ́ bíi èyí tí ó gbajúmọ̀ jù ni láti fi ọwọ́ ọ̀tún wa bu òkèlè oúnjẹ yìí kí a sì fi ọbẹ̀ ẹ̀fọ́, tàbí ata tí a fi ẹran sè jẹ́. A le fi tíì jẹ ugali tí ó bá ṣẹ́kù ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì.[19]

Ugali jẹ́ oúnjẹ kan tí kò wọ́n rárá, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn ni ó ní àǹfààní láti lè ra oúnjẹ yìí, wọ́n sáábà máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú ẹran tàbí ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ (fún àpẹẹrẹ, sukuma wikiKenya) láti se oúnjẹ tó máa yó ni. Ugali jẹ́ oúnjẹ tí ó rọrùn láti sè, àti pé ìyẹ̀fun rẹ̀ le lo ọjọ́ pípẹ́.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Ugali - a Kenyan cornmeal" (in en-US). Taste Of The Place. 2017-10-16. https://www.tasteoftheplace.com/ugali-kenyan-cornmeal/. 
  2. "How to prepare ugali/posho" (in en-US). Yummy. 2015-05-04. https://maureenmumasi.wordpress.com/2015/05/04/how-to-prepare-ugaliposho/. 
  3. "UNESCO - Nsima, culinary tradition of Malawi". ich.unesco.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-06-26. 
  4. 4.00 4.01 4.02 4.03 4.04 4.05 4.06 4.07 4.08 4.09 4.10 4.11 4.12 4.13 4.14 4.15 4.16 4.17 McCann 2009, p. 137.
  5. 5.0 5.1 5.2 Tembo, Mwizenge S. "Nshima and Ndiwo: Zambian Staple Food". Hunger For Culture (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 24 February 2017. Retrieved 2018-02-18. 
  6. "Mealiepap, n." Dictionary of South African English. Dictionary Unit for South African English, 2018.[1] 25 February 2019
  7. "Kenya Information Guide Home page". Retrieved 24 June 2013. 
  8. "Pap, n." Dictionary of South African English. Dictionary Unit for South African English, 2018. [2] 25 February 2019.
  9. "Putu, n." Dictionary of South African English. Dictionary Unit for South African English, 2018.[3] 25 February 2019.
  10. "Ugandan food recipes - POSHO (UGALI) – Wattpad". www.wattpad.com. Retrieved 2018-08-23. 
  11. "Sadza, n." Dictionary of South African English. Dictionary Unit for South African English, 2018. [4] 25 February 2019
  12. Gough, Amy (2004). "The Chewa". The Peoples of The World Foundation. Retrieved 18 February 2018. 
  13. "Tanzanian Ugali / Nguna Recipe" (in en-US). Gayathri's Cook Spot. 2015-09-01. https://gayathriscookspot.com/2015/09/tanzanian-ugali-nguna-recipe/. 
  14. McCann 2009, p. 139.
  15. "Food & Daily life". Our Africa. Retrieved 7 May 2015. 
  16. Emma Kambewa (November 2010). "Cassava Commercialization in Malawi" (PDF) (MSU International Development Working Paper). Archived from the original (PDF) on 2016-03-04. 
  17. "Ugali & Sukuma Wiki". Rehema Home (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-06. 
  18. "HOW TO COOK THE PERFECT UGALI / Nairobi Kitchen". HOW TO COOK THE PERFECT UGALI / Nairobi Kitchen. 2017-07-15. Retrieved 2020-05-19. 
  19. App, Daily Nation. "Fancy a piece of ugali cake with your tea?". mobile.nation.co.ke (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-29.