Olú Abọ́dẹrìn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Olú Abọ́dẹrìn
Ọjọ́ìbíJames Olúbùnmi Abọ́dẹrìn
3 September 1934
Ìbàdàn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèỌmọ Nàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèỌmọ Nàìjíríà
Iṣẹ́Oníṣẹ́ ìròyìn
Ìgbà iṣẹ́1961 - àkókò yìí
Gbajúmọ̀ fúnThe Punch

Olú Abọ́dẹrìn (tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹta oṣù kẹsàn-án ọdún 1934,ti oó sìn kú lọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 1984) jẹ́ gbajúmọ̀ olóòtú ìwé-ìròyìn ọmọ Nàìjíríà tí ó wà lára àwọn tí wọ́n dá ìwé-ìròyìn The Punch sílẹ̀. Ó fìgbà kan jẹ́ Ààrẹ àwọn olùdásílẹ̀ ìwé-ìròyìn kí ó tó kú lọ́dún 1984. Bẹ́ẹ̀ náà ó jẹ́ ògnóǹtarìgì onímọ̀ ìṣirò-owó tí ó ti fìgbà kan ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Oníṣirò-owó àgbà nílé ìfowópamọ́ National Bank of Nigeria. Ìwé-ìròyìn The Punch tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ni Nàìjíríà.[1] Ó dá ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn The Punch sílẹ̀ pẹ̀lú olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn Vanguard Newspaper, Sam Amuka-Pemu, lọ́jọ́ kìíní oṣù kọkànlá ọdún 1976.[2][3]

Ó jẹ́ olólùfẹ́ iṣẹ́-ọ̀nà, bẹ́ẹ̀ náà lọ jẹ́ bàbá-ìsàlẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ olórin ní Nàìjíríà kí ó tó di olóògbé.

Ìgbésí-ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Abọ́dẹrìn sí ìdílé Ọ̀gbẹ́ni Jame Oyèbọ̀dé àti aya rẹ̀, Janet Abọ́dẹrìn ní ìlú Ìbàdàn, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Lọ́dún 1941 sí 1944, ó kàwé ní Native Authority Primary School ní Ọ̀rányàn, ní Ìbàdàn, kí ó tó tẹ̀ ṣíwájú ni Ìbàdàn Grammar School. Ní ilé-ìwé yìí, ó gbádùn eré-ìdárayá bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá. Ó kàwé gboyè A-level kí ó tó dèró òkè-òkun láàárín àwọn ọdún 1950 níbi tí ó ti kàwé gboyè ìmọ̀ ìtàn ní Northwest Polytechnic ní London. Nígbà tí ó wà ní London, ó kópa nínú ìdánwò Institute of Chartered Accountants, èyí sìn fún ní àǹfààní láti di akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ìwé gíga náà lọ́dún 1964. Ní àkókò yìí, ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé-ìṣe Brighton, Sussex, bẹ́ẹ̀ náà, lọ́dún 1963 sí 1964, ó bá ilé-ìṣe ìṣirò-owó tí Bradley, Lytton & Co, ṣiṣẹ́ ní Moorgate, ní London.

Lọ́dún 1964,ó padà sí Nàìjíríà, ó sìn ríṣẹ́ sí ilé-ìṣe Pannell Fitzpatrick & Co, chartered accountants. Ó dára pọ̀ mọ́ ilé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ National Bank of Nigeria lọ́dún 1967, òun sìn ní òní ṣírò-owó fún wọn nígbà Ogun Abẹ́lé Nàìjíríà. Bẹ́ẹ̀ náà, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ ilé-iṣé West African Pictures, Nigeria Spinning Company, àti General Insurance. Ọdún 1971,ni ó kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ ní National Bank of Nigeria, tí ó sìn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àdání ara rẹ̀. Ó dá ilé-iṣẹ́ Feedwell Nigeria Ltd sílẹ̀ kí ó tó dá The Punch sílẹ̀ lọ́dún 1976.

Ó kú ní ilé-ìwòsàn The Princess Grace Hospital, London. Kí ó tó kú, ó ṣe àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ ìròyìn láti láti jà fún ẹ̀tọ́ akọròyìn ẹgbẹ́ rẹ̀ kan, Haroun Adamu, tí ó jẹ́ olórí àwọn olùdásílẹ̀ ìwé-ìròyìn ní Nàìjíríà, tí ìjọba fi sẹ́wọ̀n. Ó jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn abẹnuàtẹ́ lu ìsèjọba Ààrẹ Shehu Shagari.

Ó joyè Aṣípa Pàràkòyí ni ilu Ìbàdàn kí ó tó kú.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "The unforgettable Olu Aboderin, 1934-1984". The Sun News. Retrieved 14 June 2015. 
  2. "Buhari pays tribute to amuka pemu at 80". The Nation News. Retrieved 14 June 2015. 
  3. "Remembering James Olubunmi Aboderin (1934-1984)". The Punch News. Archived from the original on 15 June 2015. Retrieved 14 June 2015.