Olikoye Ransome-Kuti

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Olikoye Ransome-Kuti
Ọjọ́ìbí(1927-12-30)Oṣù Kejìlá 30, 1927
AláìsíJune 1, 2003(2003-06-01) (ọmọ ọdún 75)
Ẹ̀kọ́Ransome-Kuti attended Abeokuta Grammar School, University of Ibadan and Trinity College Dublin (1948–54).
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Ibadan.
Iṣẹ́paediatrician, activist and health minister of Nigeria.
Àwọn ọmọ3
AwardsLeon Bernard Foundation Prize
Maurice Pate Award

A bí Olíkóyè Ransome-Kútì sí Ìjẹ̀bú-Òde ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1927, ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Reverend Israel and Chief Funmilayo ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀; Dolu wà lẹ́yìn pẹ̀lú Fela níwájú wọn lórí ìdúró; Beko ni ọmọ ọwọ́; Olikoye ló wà ní apá ọ̀tún.

Wọ́n bí Olikoye Ransome-Kuti ní Ijebu Ode ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1927, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà. Ìyá rẹ̀, Olóyè Funmilayo Ransome-Kuti, jẹ́ gbajúgbajà olùpolongo òṣèlú àti ajàfitafita fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin. Bàbá rẹ̀, Rẹ́fẹ̀nì Israel Olúdọ̀tun Ransome-Kútì, mínísítà Protestant àti ọ̀gá ilé-ìwé, ni Ààrẹ àkọ́kó ti Nigeria Union of Teachers.[2] Arákùnrin rẹ̀ Fẹlá jẹ́ olórin olókìkí àti olùdásílè Afrobeat, nígbà tí arákùnrin rẹ̀ mìíran, Beko, jẹ́ dókítà tí ó mọ̀ye lágbàáyé àti ajàfitafita olósèlú. Olíkóyè Ransome-Kuti lọ sí ilé-ìwé Girama Abéòkúta, Yunifásitì ti ìlú Ìbàdàn àti Trinity College Dublin (1948-54).[3]

Iṣẹ́-ṣíṣe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olíkóyè Ransome-Kútì jẹ́ oníwòsàn ilé ní Ilé-ìwòsàn Gbogbogbò, Èkó. Ó jẹ́ olùkọ́ni àgbà ni Yunifásitì ìlú Èkó láti ọdún 1967 sí 1970; ó sì di olórí Ẹka ti Àwọn ìtọ́jú ọmọdé láti 1968 sí 1976. Ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìtọ́jú ọmọdé ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì ti Ìṣègùn, Yunifásítì ti Èkó títí di ìgbà tí ó fẹ̀yìntì ní ọdún 1988. [4] [5] Ó ṣiṣẹ́ bí i òṣìṣẹ́ ilé àgbà ní Ilé-ìwòsàn Great Ormond Street, Lọ́ńdọ̀nù, àti bí i dókítà adeleIlé-ìwòsàn Hammersmith ní àwọn ọdún 1960.[6]

Ní àwọn ọdún 1980, ó darapọ̀ mọ́ ìṣèjọba Ọ̀gágun Ibrahim Bàbáńgídá gẹ́gẹ́ bí i mínísítà fún ètò ìlera. Ní ọdún 1983, pẹ̀lú àwọn ọmọ orílèdè Nàìjíríà méjì mìíràn, ṣe ìdásílẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn àjọ aláìwojúèrè-aládàání tó ń rí sí ìlera, èyí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Society for Family Health Nigeria, léyìí tó ń rí sí ìfètò-sọ́mọ-bíbí àti ètò ìlera àwọn ọmọ. Ó jẹ́ mínísítà di ọdún 1992, nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ World Health Organization gẹ́gẹ́ bí i amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ adarí pátápátá. [7] Ó di ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipò ìkọ́ni mú, pẹ̀lú olùkọ́-àbẹ̀wò-sí ní ilé-ẹ̀kọ́ onímọ̀ọ́tótó àti ìlera gbogbogbò Baltimore's Johns Hopkins University. Ó kọ̀wé lọ́pọ̀lọpọ̀ fún àwọn ìwe-ìròyìn ìṣoògùn àti àwọn àtẹ̀jáde.[8] Ó jẹ ẹ̀bùn Leon Bernard Prize Foundation ní ni 1986 [9] àti àmì ẹ̀yẹ Maurice Pate ní 1990.

Ikú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olíkóyè Ransome-Kuti kú ní ọjọ́ kìíní Oṣù Kẹfà ọdún 2003, tí ó sì fi ìyàwó rẹ̀ Sonia ẹni àádọ́ta ọdún àti àwọn ọmọ mẹ́ta sẹ́yìn. [10]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Adenekan, Shola (1 June 2003). "Olikoye Ransome-Kuti". The Guardian (United Kingdom). https://www.theguardian.com/news/2003/jun/10/guardianobituaries.aids. Retrieved 1 March 2015. 
  2. Empty citation (help) 
  3. Empty citation (help) 
  4. Olukoye Ransome-Kuti. 
  5. Empty citation (help) 
  6. Empty citation (help) 
  7. F. Adewole, Isaac (21 June 2023). "African Journal of Reproductive Health". Mason Publishing, Part of the George Mason University Libraries. 27 (5). https://www.ajrh.info/index.php/ajrh/article/view/3823. 
  8. Empty citation (help) 
  9. Empty citation (help) 
  10. Empty citation (help)