Wikipedia:Àyọkà ọṣẹ̀ 11 ọdún 2011

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Àwòrán Júpítérì

Júpítérì ni plánẹ̀tì karùún láti ọ̀dọ̀ Òrùn àti plánẹ̀tì tótóbijùlọ nínú Sístẹ̀mù Òrùn. Ó jẹ́ òmìrán ẹ̀fúùfù tó ní ìsúpọ̀ tó fi díẹ̀ dín ju ìkan-nínú-ìdálẹ́gbẹ́rùún ìsúpọ̀ Òrùn lọ sùgbọ́n ìsúpọ̀ lọ́nà méjì àti àbọ̀ ti ìsúpò gbogbo àwọn plánẹ̀tì yìókù nínú Sítẹ̀mù Òrùn lápapọ̀. Júpítérì jẹ́ kìkósọ́tọ̀ bíi òmìrán ẹ̀fúùfù lápapọ̀ mọ́ Sátúrnù, Úránù àti Nẹ́ptúnù. Lápapọ̀, àwọn plánẹ̀tì mẹ́rẹ̀rin yìí jẹ́ pípè nígbà míràn bíi plánẹ̀tì Jofia.

Àwọn atòràwọ̀ ayéijọ́un mọ Júpítérì, bẹ́ ẹ̀ sìni ó jẹ́ gbígbà nínú ẹ̀sìn àti àṣà àwọn ènìyàn ìgbà náà. Àwọn ará Rómù sọ orúkọ rẹ̀ fún òsa Rómù tó únjẹ́ Júpítérì. Láti Ayé, Júpítérì le ní ìhàn ìtóbi −2.94, èyí só di ohun tómọ́lẹ̀jùlọ kẹta ní ojúsànmọ̀ àṣálẹ lẹ́yìn Òsùpá àti Àgùàlà. (Mársì áà le mọ́lẹ̀ bíi Júpítérì fún ìgbà díẹ̀ tó bá wà ní ààyè kan pàtó lórí ojúọ̀nàìyípo rẹ̀.)

Júpítérì jẹ́ ṣíṣàjọsínú pẹ̀lú háídrójìn tí ìkan-nínú-ìdámẹ́rin ìsúpọ̀ sì jẹ́ hélíọ̀m; bákannáà ó tún ṣe é ṣe kó ní inúàrin oníàpáta apilẹ̀sè wíwúwo. Nítorípé ó ún yírapo kíákíá, àwòrán Júpítérì jẹ́ bíi òbìrìkìtì afẹ̀lẹ́ẹ̀gbẹ́ (ó wú díẹ̀ síta ní agedeméjì rẹ̀). Afẹ́fẹ́ojúọ̀run òde rẹ̀ jẹ́ yíyàsọ́tọ̀ sí orísirísi ẹ̀gbẹ́ ní ojúibigbọọrọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tó ún fa ìjì àti ìṣe rudurudu lẹ́ẹ̀gbẹ́ àwọn bodè tó únkanra wọn. Esi eyi ni Great Red Spot, iji omiran kan to ti je mimo lati orundun 17k nigbati o koko je riri pelu teleskopu. To yika planeti yi ni sistemu oruka planeti ati igberinojuorun alagbara. Be si tun ni o ni awon osupa 63, ninu won ni awon osupa gbangba merin ti won unje awon osupa Galilei ti won koko je wiwari latowo Galileo Galilei ni 1610. Ganymede, eyi totobijulo ninu awon osupa yi ni diamita totobiju planet Mercury lo.

Júpítérì ti je wiwakiri ninu lopolopo igba pelu oko-ofurufu roboti, agaga nigba awon iranlose ifokoja Pioneer ati Voyager ati leyin won pelu Galileo orbiter. Oko iwadi to pese lo si Júpítérì ni oko-ofurufu to unlo si en:Pluto, en:New Horizons ni opin February 2007. Oko iwadi yi lo iwolura lati odo Júpítérì lati fun ni isare pupo. Awon iwakiri ojowaju ninu sistemu Jofia ni wiwa omi ti tinyin bo mole ninu osupa Europa. (ìyókù...)